Surah Al-Baqara Verse 231 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ سَرِّحُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖۚ وَلَا تُمۡسِكُوهُنَّ ضِرَارٗا لِّتَعۡتَدُواْۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗاۚ وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَمَآ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡحِكۡمَةِ يَعِظُكُم بِهِۦۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí àsìkò (opó) wọn súnmọ́ kó parí, ẹ lè mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ (ní ìparí opó wọn) pẹ̀lú dáadáa. Ẹ má ṣe mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà ìnira láti lè tayọ ẹnu-àlà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, ó kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín àti ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah Ànábì s.a.w.), tí Ó ń fi ṣe ìṣítí fun yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdáju Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan