Surah Al-Baqara Verse 231 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ سَرِّحُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖۚ وَلَا تُمۡسِكُوهُنَّ ضِرَارٗا لِّتَعۡتَدُواْۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗاۚ وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَمَآ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡحِكۡمَةِ يَعِظُكُم بِهِۦۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti asiko (opo) won sunmo ko pari, e le mu won mora pelu daadaa tabi ki e tu won sile (ni ipari opo won) pelu daadaa. E ma se mu won mora ni ona inira lati le tayo enu-ala. Enikeni ti o ba se iyen, o kuku ti sabosi si emi ara re. E ma se so awon ayah Allahu di nnkan yeye. E ranti idera Allahu lori yin ati ohun ti O sokale fun yin ninu Tira ati oye ijinle (iyen, sunnah Anabi s.a.w.), ti O n fi se isiti fun yin. E beru Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan