Surah Al-Baqara Verse 282 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا تَدَايَنتُم بِدَيۡنٍ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى فَٱكۡتُبُوهُۚ وَلۡيَكۡتُب بَّيۡنَكُمۡ كَاتِبُۢ بِٱلۡعَدۡلِۚ وَلَا يَأۡبَ كَاتِبٌ أَن يَكۡتُبَ كَمَا عَلَّمَهُ ٱللَّهُۚ فَلۡيَكۡتُبۡ وَلۡيُمۡلِلِ ٱلَّذِي عَلَيۡهِ ٱلۡحَقُّ وَلۡيَتَّقِ ٱللَّهَ رَبَّهُۥ وَلَا يَبۡخَسۡ مِنۡهُ شَيۡـٔٗاۚ فَإِن كَانَ ٱلَّذِي عَلَيۡهِ ٱلۡحَقُّ سَفِيهًا أَوۡ ضَعِيفًا أَوۡ لَا يَسۡتَطِيعُ أَن يُمِلَّ هُوَ فَلۡيُمۡلِلۡ وَلِيُّهُۥ بِٱلۡعَدۡلِۚ وَٱسۡتَشۡهِدُواْ شَهِيدَيۡنِ مِن رِّجَالِكُمۡۖ فَإِن لَّمۡ يَكُونَا رَجُلَيۡنِ فَرَجُلٞ وَٱمۡرَأَتَانِ مِمَّن تَرۡضَوۡنَ مِنَ ٱلشُّهَدَآءِ أَن تَضِلَّ إِحۡدَىٰهُمَا فَتُذَكِّرَ إِحۡدَىٰهُمَا ٱلۡأُخۡرَىٰۚ وَلَا يَأۡبَ ٱلشُّهَدَآءُ إِذَا مَا دُعُواْۚ وَلَا تَسۡـَٔمُوٓاْ أَن تَكۡتُبُوهُ صَغِيرًا أَوۡ كَبِيرًا إِلَىٰٓ أَجَلِهِۦۚ ذَٰلِكُمۡ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِ وَأَقۡوَمُ لِلشَّهَٰدَةِ وَأَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَرۡتَابُوٓاْ إِلَّآ أَن تَكُونَ تِجَٰرَةً حَاضِرَةٗ تُدِيرُونَهَا بَيۡنَكُمۡ فَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَلَّا تَكۡتُبُوهَاۗ وَأَشۡهِدُوٓاْ إِذَا تَبَايَعۡتُمۡۚ وَلَا يُضَآرَّ كَاتِبٞ وَلَا شَهِيدٞۚ وَإِن تَفۡعَلُواْ فَإِنَّهُۥ فُسُوقُۢ بِكُمۡۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ وَيُعَلِّمُكُمُ ٱللَّهُۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n se kata-kara ni awin fun gbedeke akoko kan, e se akosile re. Ki akowe se akosile re laaarin yin ni ona eto. Ki akowe ma se ko lati se akosile gege bi Allahu se fi mo on. Nitori naa. ki o se akosile. Ki eni ti eto wa lorun re pe e fun un. Ki o beru Allahu, Oluwa re. Ko ma se din kini kan ku ninu re. Ti eni ti eto wa lorun re ba je alailoye tabi alaisan, tabi ko le pe e (funra re), ki alamojuuto re ba a pe e ni ona eto. Ki e pe elerii meji ninu awon okunrin yin lati jerii si i. Ti ko ba si okunrin meji, ki e wa okunrin kan ati obinrin meji ninu awon elerii ti e yonu si; nitori pe ti okan ninu awon obinrin mejeeji ba gbagbe, okan yo si ran ikeji leti. Ki awon elerii ma se ko ti won ba pe won (lati jerii). E ma se kaaare lati se akosile re, o kere ni tabi o tobi, titi di asiko isangbese re. Iyen ni deede julo lodo Allahu. O si gbe ijerii duro julo. O tun fi sunmo julo pe eyin ko fi nii seyemeji. Afi ti o ba je kata-kara oju ese ti e n se ni atowodowo laaarin ara yin, ko si ese fun yin ti e o ba se akosile re. E wa elerii se nigba ti e ba n se kata-kara (oja awin). Won ko si nii ko inira ba akowe ati elerii. Ti e ba si se bee, dajudaju ibaje l’e se. E beru Allahu. Allahu yo si maa fi imo mo yin. Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan