Surah Al-Baqara Verse 286 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraلَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَعَلَيۡهَا مَا ٱكۡتَسَبَتۡۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذۡنَآ إِن نَّسِينَآ أَوۡ أَخۡطَأۡنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تَحۡمِلۡ عَلَيۡنَآ إِصۡرٗا كَمَا حَمَلۡتَهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلۡنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِۦۖ وَٱعۡفُ عَنَّا وَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَآۚ أَنتَ مَوۡلَىٰنَا فَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Allahu ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. (Esan) ohun ti o se nise (rere) n be fun un. (Iya) ohun ti o se ni’se (ibi) n be fun un pelu. Oluwa wa, ma se mu wa ti a ba gbagbera tabi (ti) a ba sasise. Oluwa wa, ma se di eru t’o wuwo le wa lori, gege bi O se di i ru awon t’o siwaju wa. Oluwa wa, ma se diru wa ohun ti ko si agbara re fun wa. Samoju kuro fun wa, forijin wa, ki O si saanu wa. Iwo ni Alafeyinti wa. Nitori naa, ran wa lowo lori ijo alaigbagbo