Surah Al-Baqara Verse 83 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ لَا تَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَانٗا وَذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَقُولُواْ لِلنَّاسِ حُسۡنٗا وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ ثُمَّ تَوَلَّيۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنكُمۡ وَأَنتُم مُّعۡرِضُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ‘Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù. Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn)