Surah Al-Baqara Verse 84 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ لَا تَسۡفِكُونَ دِمَآءَكُمۡ وَلَا تُخۡرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ ثُمَّ أَقۡرَرۡتُمۡ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín pé ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i