UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Al-Ahzab - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ ٱتَّقِ ٱللَّهَ وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n
Surah Al-Ahzab, Verse 1


وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا

Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Ahzab, Verse 2


وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا

Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́
Surah Al-Ahzab, Verse 3


مَّا جَعَلَ ٱللَّهُ لِرَجُلٖ مِّن قَلۡبَيۡنِ فِي جَوۡفِهِۦۚ وَمَا جَعَلَ أَزۡوَٰجَكُمُ ٱلَّـٰٓـِٔي تُظَٰهِرُونَ مِنۡهُنَّ أُمَّهَٰتِكُمۡۚ وَمَا جَعَلَ أَدۡعِيَآءَكُمۡ أَبۡنَآءَكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ قَوۡلُكُم بِأَفۡوَٰهِكُمۡۖ وَٱللَّهُ يَقُولُ ٱلۡحَقَّ وَهُوَ يَهۡدِي ٱلسَّبِيلَ

Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà
Surah Al-Ahzab, Verse 4


ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٞ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا

Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ ò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ bá ṣàṣìṣe rẹ̀, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Ahzab, Verse 5


ٱلنَّبِيُّ أَوۡلَىٰ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَأَزۡوَٰجُهُۥٓ أُمَّهَٰتُهُمۡۗ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ إِلَّآ أَن تَفۡعَلُوٓاْ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِكُم مَّعۡرُوفٗاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورٗا

Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn t’ó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀). Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 6


وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِيثَٰقَهُمۡ وَمِنكَ وَمِن نُّوحٖ وَإِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۖ وَأَخَذۡنَا مِنۡهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا

(Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn t’ó nípọn
Surah Al-Ahzab, Verse 7


لِّيَسۡـَٔلَ ٱلصَّـٰدِقِينَ عَن صِدۡقِهِمۡۚ وَأَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابًا أَلِيمٗا

nítorí kí (Allāhu) lè bèèrè (òdodo) àwọn olódodo nípa òdodo wọn. Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Al-Ahzab, Verse 8


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَآءَتۡكُمۡ جُنُودٞ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا وَجُنُودٗا لَّمۡ تَرَوۡهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ ò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe
Surah Al-Ahzab, Verse 9


إِذۡ جَآءُوكُم مِّن فَوۡقِكُمۡ وَمِنۡ أَسۡفَلَ مِنكُمۡ وَإِذۡ زَاغَتِ ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَبَلَغَتِ ٱلۡقُلُوبُ ٱلۡحَنَاجِرَ وَتَظُنُّونَ بِٱللَّهِ ٱلظُّنُونَا۠

(Ẹ rántí) nígbà tí wọ́n dé ba yín láti òkè yín àti ìsàlẹ̀ yín, àti nígbà tí àwọn ojú yẹ̀ (sọ́tùn-ún sósì), tí àwọn ọkàn sí dé ọ̀nà-ọ̀fun (ní ti ìpáyà). Ẹ sì ń ro àwọn èrò kan nípa Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 10


هُنَالِكَ ٱبۡتُلِيَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَزُلۡزِلُواْ زِلۡزَالٗا شَدِيدٗا

Níbẹ̀ yẹn ni wọ́n ti fi àdánwò kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n sì milẹ̀ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ní ìmìtìtì líle
Surah Al-Ahzab, Verse 11


وَإِذۡ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ مَّا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ إِلَّا غُرُورٗا

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àìsàn wà nínú ọkàn wọn ń wí pé: “Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kò ṣe àdéhùn kan fún wa bí kò ṣe ẹ̀tàn.”
Surah Al-Ahzab, Verse 12


وَإِذۡ قَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ يَـٰٓأَهۡلَ يَثۡرِبَ لَا مُقَامَ لَكُمۡ فَٱرۡجِعُواْۚ وَيَسۡتَـٔۡذِنُ فَرِيقٞ مِّنۡهُمُ ٱلنَّبِيَّ يَقُولُونَ إِنَّ بُيُوتَنَا عَوۡرَةٞ وَمَا هِيَ بِعَوۡرَةٍۖ إِن يُرِيدُونَ إِلَّا فِرَارٗا

(Ẹ rántí) nígbà tí igun kan nínú wọn wí pé: “Ẹ̀yin ará Yẹthrib, kò sí àyè (ìṣẹ́gun) fun yín, nítorí náà, ẹ ṣẹ́rí padà (lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́).” Apá kan nínú wọn sì ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ Ànábì, wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú ilé wa dá páropáro ni.” (Ilé wọn) kò sì dá páropáro. Wọn kò sì gbèrò ohun kan tayọ síságun
Surah Al-Ahzab, Verse 13


وَلَوۡ دُخِلَتۡ عَلَيۡهِم مِّنۡ أَقۡطَارِهَا ثُمَّ سُئِلُواْ ٱلۡفِتۡنَةَ لَأٓتَوۡهَا وَمَا تَلَبَّثُواْ بِهَآ إِلَّا يَسِيرٗا

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé (ọmọ ogun oníjọ) wọlé tọ̀ wọ́n wá láti àwọn ìloro ìlú (Mọdīnah), lẹ́yìn náà, kí wọ́n pe (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) sínú ẹbọ ṣíṣe, wọn ìbá ṣẹbọ. Wọn kò sì níí gbé nínú ìlú mọ́ tayọ ìgbà díẹ̀ (tí wọn yóò fi parẹ́)
Surah Al-Ahzab, Verse 14


وَلَقَدۡ كَانُواْ عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ مِن قَبۡلُ لَا يُوَلُّونَ ٱلۡأَدۡبَٰرَۚ وَكَانَ عَهۡدُ ٱللَّهِ مَسۡـُٔولٗا

Dájúdájú wọ́n ti bá Allāhu ṣe àdéhùn ṣíwájú pé àwọn kò níí pẹ̀yìndà (láti ságun). Àdéhùn Allāhu sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa bèèrè (lọ́wọ́ wọn)
Surah Al-Ahzab, Verse 15


قُل لَّن يَنفَعَكُمُ ٱلۡفِرَارُ إِن فَرَرۡتُم مِّنَ ٱلۡمَوۡتِ أَوِ ٱلۡقَتۡلِ وَإِذٗا لَّا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلٗا

Sọ pé: “Síságun yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí ẹ bá sá fún ikú tàbí pípa (sí ojú ogun ẹ̀sìn. Tí ẹ bá sì ságun) nígbà náà, A ò níí fun yín ní ìgbádùn ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 16


قُلۡ مَن ذَا ٱلَّذِي يَعۡصِمُكُم مِّنَ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَ بِكُمۡ سُوٓءًا أَوۡ أَرَادَ بِكُمۡ رَحۡمَةٗۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا

Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó lè dá ààbò bò yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá fẹ́ fi aburú kàn yín tàbí tí Ó bá fẹ́ kẹ yín?” Wọn kò sì lè rí aláàbò tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 17


۞قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلۡمُعَوِّقِينَ مِنكُمۡ وَٱلۡقَآئِلِينَ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ هَلُمَّ إِلَيۡنَاۖ وَلَا يَأۡتُونَ ٱلۡبَأۡسَ إِلَّا قَلِيلًا

Dájúdájú Allāhu ti mọ àwọn t’ó ń fa ènìyàn sẹ́yìn nínú yín àti àwọn t’ó ń wí fún àwọn arakùnrin wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Wọn kò sì níí lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn àfi (ogun) díẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 18


أَشِحَّةً عَلَيۡكُمۡۖ فَإِذَا جَآءَ ٱلۡخَوۡفُ رَأَيۡتَهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ تَدُورُ أَعۡيُنُهُمۡ كَٱلَّذِي يُغۡشَىٰ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَإِذَا ذَهَبَ ٱلۡخَوۡفُ سَلَقُوكُم بِأَلۡسِنَةٍ حِدَادٍ أَشِحَّةً عَلَى ٱلۡخَيۡرِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَمۡ يُؤۡمِنُواْ فَأَحۡبَطَ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا

Wọ́n ní ahun si yín (láti ṣe ìrànlọ́wọ́). Nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá dé, o máa rí wọn tí wọn yóò máa wò ọ́. Ojú wọn yó sì máa yí kiri ràkọ̀ràkọ̀ (ní ti ìbẹ̀rù) bí ẹni tí ó fẹ́ dákú, ṣùgbọ́n nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá lọ, (tí ìkógun bá dé), wọn yóò máa fi àwọn ahọ́n kan t’ó mú bérébéré ba yín sọ̀rọ̀ ní ti ṣíṣe ọ̀kánjúà sí oore náà. Àwọn wọ̀nyẹn kò gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 19


يَحۡسَبُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ لَمۡ يَذۡهَبُواْۖ وَإِن يَأۡتِ ٱلۡأَحۡزَابُ يَوَدُّواْ لَوۡ أَنَّهُم بَادُونَ فِي ٱلۡأَعۡرَابِ يَسۡـَٔلُونَ عَنۡ أَنۢبَآئِكُمۡۖ وَلَوۡ كَانُواْ فِيكُم مَّا قَٰتَلُوٓاْ إِلَّا قَلِيلٗا

Wọ́n ń lérò pé àwọn ọmọ ogun oníjọ kò tí ì lọ, (wọ́n sì ti túká). Tí àwọn ọmọ ogun oníjọ bá (sì padà) dé, dájúdájú (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò fẹ́ kí àwọn ti wà ní oko láààrin àwọn Lárúbáwá oko, kí wọ́n máa bèèrè nípa àwọn ìró yín (pé ṣé ẹ ti kú tán tàbí ẹ sì wà láyé). Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n wà láààrin yín, wọn kò níí jagun bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 20


لَّقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِي رَسُولِ ٱللَّهِ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَذَكَرَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا

Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fun yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà)
Surah Al-Ahzab, Verse 21


وَلَمَّا رَءَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ قَالُواْ هَٰذَا مَا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَصَدَقَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥۚ وَمَا زَادَهُمۡ إِلَّآ إِيمَٰنٗا وَتَسۡلِيمٗا

Nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu)
Surah Al-Ahzab, Verse 22


مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ رِجَالٞ صَدَقُواْ مَا عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ عَلَيۡهِۖ فَمِنۡهُم مَّن قَضَىٰ نَحۡبَهُۥ وَمِنۡهُم مَّن يَنتَظِرُۖ وَمَا بَدَّلُواْ تَبۡدِيلٗا

Ó wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ olódodo nípa àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe; ó wà nínú wọn ẹni tí ó pé àdéhùn rẹ̀ (t’ó sì kú sójú ogun ẹ̀sìn), ó sì wà nínú wọn ẹni t’ó ń retí (ikú tirẹ̀). Wọn kò sì yí (àdéhùn) padà rárá
Surah Al-Ahzab, Verse 23


لِّيَجۡزِيَ ٱللَّهُ ٱلصَّـٰدِقِينَ بِصِدۡقِهِمۡ وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ إِن شَآءَ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا

(Ìwọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi (òdodo) àwọn olódodo san wọ́n ní ẹ̀san òdodo wọn, àti nítorí kí Ó lè jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìyà tí Ó bá fẹ́ tàbí nítorí kí Ó lè gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Ahzab, Verse 24


وَرَدَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِغَيۡظِهِمۡ لَمۡ يَنَالُواْ خَيۡرٗاۚ وَكَفَى ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلۡقِتَالَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزٗا

Allāhu sì dá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ padà tòhun ti ìbínú wọn; ọwọ́ wọn kò sì tẹ oore kan. Allāhu sì tó àwọn onígbàgbọ́ òdodo níbi ogun náà. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Olùborí
Surah Al-Ahzab, Verse 25


وَأَنزَلَ ٱلَّذِينَ ظَٰهَرُوهُم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن صَيَاصِيهِمۡ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَ فَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ وَتَأۡسِرُونَ فَرِيقٗا

(Allāhu) sì mú àwọn t’ó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn ahlul-kitāb sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú
Surah Al-Ahzab, Verse 26


وَأَوۡرَثَكُمۡ أَرۡضَهُمۡ وَدِيَٰرَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُمۡ وَأَرۡضٗا لَّمۡ تَطَـُٔوهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٗا

(Allāhu) sì jogún ilẹ̀ wọn, ilé wọn, dúkìá wọn àti ilẹ̀ tí ẹ ò tẹ̀ rí fun yín. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Al-Ahzab, Verse 27


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ إِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا فَتَعَالَيۡنَ أُمَتِّعۡكُنَّ وَأُسَرِّحۡكُنَّ سَرَاحٗا جَمِيلٗا

Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn ìyàwó rẹ pé: “Tí ẹ bá fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ẹ wá níbí kí n̄g fun yín ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀, kí n̄g sì fi yín sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà
Surah Al-Ahzab, Verse 28


وَإِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ فَإِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡمُحۡسِنَٰتِ مِنكُنَّ أَجۡرًا عَظِيمٗا

Tí ẹ bá sì fẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ilé Ìkẹ́yìn, dájúdájú Allāhu ti pèsè ẹ̀san ńlá sílẹ̀ de àwọn olùṣe-rere lóbìnrin nínú yín.”
Surah Al-Ahzab, Verse 29


يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ مَن يَأۡتِ مِنكُنَّ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖ يُضَٰعَفۡ لَهَا ٱلۡعَذَابُ ضِعۡفَيۡنِۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ìbàjẹ́ t’ó fojú hàn, A máa di àdìpèlé ìyà ìlọ́po méjì fún un. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 30


۞وَمَن يَقۡنُتۡ مِنكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا نُّؤۡتِهَآ أَجۡرَهَا مَرَّتَيۡنِ وَأَعۡتَدۡنَا لَهَا رِزۡقٗا كَرِيمٗا

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú yín, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, A máa fún un ní ẹ̀san ìlọ́po méjì. A sì ti pèsè ìjẹ-ìmu alápọ̀n-ọ́nlé sílẹ̀ dè é.”
Surah Al-Ahzab, Verse 31


يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ لَسۡتُنَّ كَأَحَدٖ مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِنِ ٱتَّقَيۡتُنَّۚ فَلَا تَخۡضَعۡنَ بِٱلۡقَوۡلِ فَيَطۡمَعَ ٱلَّذِي فِي قَلۡبِهِۦ مَرَضٞ وَقُلۡنَ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹ ò dà bí ẹnì kan kan nínú àwọn obìnrin, tí ẹ bá ti bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ má ṣe dínhùn (sí àwọn ọkùnrin létí) nítorí kí ẹni tí àrùn wà nínú ọkàn rẹ̀ má baá jẹ̀rankàn. Kí ẹ sì máa sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára
Surah Al-Ahzab, Verse 32


وَقَرۡنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجۡنَ تَبَرُّجَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ ٱلۡأُولَىٰۖ وَأَقِمۡنَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتِينَ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِعۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُذۡهِبَ عَنكُمُ ٱلرِّجۡسَ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِ وَيُطَهِّرَكُمۡ تَطۡهِيرٗا

Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ t’ó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni
Surah Al-Ahzab, Verse 33


وَٱذۡكُرۡنَ مَا يُتۡلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱلۡحِكۡمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا

Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀. tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ èdè Lárúbáwá ti ní ìhun akọ fún akọ. Bákan náà
Surah Al-Ahzab, Verse 34


إِنَّ ٱلۡمُسۡلِمِينَ وَٱلۡمُسۡلِمَٰتِ وَٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡقَٰنِتَٰتِ وَٱلصَّـٰدِقِينَ وَٱلصَّـٰدِقَٰتِ وَٱلصَّـٰبِرِينَ وَٱلصَّـٰبِرَٰتِ وَٱلۡخَٰشِعِينَ وَٱلۡخَٰشِعَٰتِ وَٱلۡمُتَصَدِّقِينَ وَٱلۡمُتَصَدِّقَٰتِ وَٱلصَّـٰٓئِمِينَ وَٱلصَّـٰٓئِمَٰتِ وَٱلۡحَٰفِظِينَ فُرُوجَهُمۡ وَٱلۡحَٰفِظَٰتِ وَٱلذَّـٰكِرِينَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱلذَّـٰكِرَٰتِ أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمٗا

Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùpáyà Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùpáyà Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n
Surah Al-Ahzab, Verse 35


وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٖ وَلَا مُؤۡمِنَةٍ إِذَا قَضَى ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ أَمۡرًا أَن يَكُونَ لَهُمُ ٱلۡخِيَرَةُ مِنۡ أَمۡرِهِمۡۗ وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلٗا مُّبِينٗا

Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé
Surah Al-Ahzab, Verse 36


وَإِذۡ تَقُولُ لِلَّذِيٓ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَأَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِ أَمۡسِكۡ عَلَيۡكَ زَوۡجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخۡفِي فِي نَفۡسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبۡدِيهِ وَتَخۡشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَىٰهُۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيۡدٞ مِّنۡهَا وَطَرٗا زَوَّجۡنَٰكَهَا لِكَيۡ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ حَرَجٞ فِيٓ أَزۡوَٰجِ أَدۡعِيَآئِهِمۡ إِذَا قَضَوۡاْ مِنۡهُنَّ وَطَرٗاۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولٗا

(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún1 pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ
Surah Al-Ahzab, Verse 37


مَّا كَانَ عَلَى ٱلنَّبِيِّ مِنۡ حَرَجٖ فِيمَا فَرَضَ ٱللَّهُ لَهُۥۖ سُنَّةَ ٱللَّهِ فِي ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلُۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قَدَرٗا مَّقۡدُورًا

Kò sí láìfí fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nípa ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un. (Ó jẹ́) ìlànà Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. Àti pé àṣẹ Allāhu jẹ́ àkọọ́lẹ̀ kan t’ó gbọ́dọ̀ ṣẹ
Surah Al-Ahzab, Verse 38


ٱلَّذِينَ يُبَلِّغُونَ رِسَٰلَٰتِ ٱللَّهِ وَيَخۡشَوۡنَهُۥ وَلَا يَخۡشَوۡنَ أَحَدًا إِلَّا ٱللَّهَۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا

(Kọ́ṣe àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́) àwọn t’ó ń jẹ́ iṣẹ́ Allāhu, tí wọ́n ń páyà Rẹ̀, tí wọn kò sì páyà ẹnì kan àyàfi Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣírò
Surah Al-Ahzab, Verse 39


مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا

(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn wulẹ̀ ni òun. Irọ́ ẹnu rẹ̀ ti pọ̀ jù. Alágbárí pọ́nńbélé sì ni pẹ̀lú. Irú iṣẹ́ aburú tí ṣeeu Ahmada Tijāni ṣe fún ’Islām gẹ́lẹ́ náà ni mirza ghulam Ahmad ṣe. Àwọn méjèèjì ni Pọ́ọ̀lù láààrin àwa mùsùlùmí. Ẹ wo díẹ̀ nínú irọ́ ńlá rẹ̀. Mirza ghulam Ahmad sọ pé: ""Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé bí ọmọ Mi ló ṣe wà sí Mi."" (Tadhkirah “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun kò yẹ fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti padà wá sáyé mọ́ lópin ayé.” Wọ́n tún sọ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun àmọ́ ìṣòro tiwọn ni pé
Surah Al-Ahzab, Verse 40


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ ذِكۡرٗا كَثِيرٗا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí Allāhu ní ìrántí púpọ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 41


وَسَبِّحُوهُ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلًا

Ẹ ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́
Surah Al-Ahzab, Verse 42


هُوَ ٱلَّذِي يُصَلِّي عَلَيۡكُمۡ وَمَلَـٰٓئِكَتُهُۥ لِيُخۡرِجَكُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۚ وَكَانَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ رَحِيمٗا

(Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó ń kẹ yín, àwọn mọlāika Rẹ̀ (sì ń tọrọ àforíjìn fun yín), nítorí kí Allāhu lè mu yín kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àti pé Ó ń jẹ́ Àṣàkẹ́-ọ̀run fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Al-Ahzab, Verse 43


تَحِيَّتُهُمۡ يَوۡمَ يَلۡقَوۡنَهُۥ سَلَٰمٞۚ وَأَعَدَّ لَهُمۡ أَجۡرٗا كَرِيمٗا

Ìkíni wọn ní ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Rẹ̀ ni "àlàáfíà." Ó sì ti pèsè ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlẹ́ sílẹ̀ dè wọ́n
Surah Al-Ahzab, Verse 44


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ شَٰهِدٗا وَمُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú, olùkìlọ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 45


وَدَاعِيًا إِلَى ٱللَّهِ بِإِذۡنِهِۦ وَسِرَاجٗا مُّنِيرٗا

olùpèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ àti àtùpà ìmọ́lẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 46


وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ بِأَنَّ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَضۡلٗا كَبِيرٗا

Fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú oore àjùlọ ńlá wà fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 47


وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَدَعۡ أَذَىٰهُمۡ وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا

Má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Fi bí wọ́n ṣe ń kó ìnira bá ọ sílẹ̀. Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì ń tó ní Alámòjúútó
Surah Al-Ahzab, Verse 48


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نَكَحۡتُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمۡ عَلَيۡهِنَّ مِنۡ عِدَّةٖ تَعۡتَدُّونَهَاۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحٗا جَمِيلٗا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fun yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà
Surah Al-Ahzab, Verse 49


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَحۡلَلۡنَا لَكَ أَزۡوَٰجَكَ ٱلَّـٰتِيٓ ءَاتَيۡتَ أُجُورَهُنَّ وَمَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَ مِمَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ وَبَنَاتِ عَمِّكَ وَبَنَاتِ عَمَّـٰتِكَ وَبَنَاتِ خَالِكَ وَبَنَاتِ خَٰلَٰتِكَ ٱلَّـٰتِي هَاجَرۡنَ مَعَكَ وَٱمۡرَأَةٗ مُّؤۡمِنَةً إِن وَهَبَتۡ نَفۡسَهَا لِلنَّبِيِّ إِنۡ أَرَادَ ٱلنَّبِيُّ أَن يَسۡتَنكِحَهَا خَالِصَةٗ لَّكَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۗ قَدۡ عَلِمۡنَا مَا فَرَضۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ لِكَيۡلَا يَكُونَ عَلَيۡكَ حَرَجٞۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún ọ àwọn ìyàwó rẹ̀, tí o fún ní owó-orí wọn, àti àwọn ẹrú nínú àwọn tí Allāhu fí ṣe ìkógun fún ọ àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin bàbá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin ìyá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin ìyá rẹ, àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ìlú Mọdīnah pẹ̀lú rẹ, àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ó bá fi ara rẹ̀ tọrẹ fún Ànábì, tí Ànábì náà sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Ìwọ nìkan ni (èyí) wà fún, kò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin. A ti mọ ohun tí A ṣe ní ọ̀ran-anyàn fún wọn nípa àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ẹrú wọn. (Èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ó má baà sí láìfí fún ọ. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Ahzab, Verse 50


۞تُرۡجِي مَن تَشَآءُ مِنۡهُنَّ وَتُـٔۡوِيٓ إِلَيۡكَ مَن تَشَآءُۖ وَمَنِ ٱبۡتَغَيۡتَ مِمَّنۡ عَزَلۡتَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكَۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن تَقَرَّ أَعۡيُنُهُنَّ وَلَا يَحۡزَنَّ وَيَرۡضَيۡنَ بِمَآ ءَاتَيۡتَهُنَّ كُلُّهُنَّۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَلِيمٗا

Lọ́ra láti súnmọ́ ẹni tí o bá fẹ́ nínú wọn. Fa ẹni tí o bá fẹ́ mọ́ra. Àti pé ẹni kẹ́ni tí o bá tún wá (láti súnmọ́) nínú àwọn tí o ò pín oorun fún, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ (láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ojú wọn tutù ìdùnnú. Wọn kò sì níí banújẹ́. Gbogbo wọn yó sì yọ́nú sí ohunkóhun tí o bá fún wọn. Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Aláfaradà
Surah Al-Ahzab, Verse 51


لَّا يَحِلُّ لَكَ ٱلنِّسَآءُ مِنۢ بَعۡدُ وَلَآ أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ حُسۡنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ رَّقِيبٗا

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ (nìkan l’o lè kọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn ìyàwó rẹ). Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Al-Ahzab, Verse 52


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَدۡخُلُواْ بُيُوتَ ٱلنَّبِيِّ إِلَّآ أَن يُؤۡذَنَ لَكُمۡ إِلَىٰ طَعَامٍ غَيۡرَ نَٰظِرِينَ إِنَىٰهُ وَلَٰكِنۡ إِذَا دُعِيتُمۡ فَٱدۡخُلُواْ فَإِذَا طَعِمۡتُمۡ فَٱنتَشِرُواْ وَلَا مُسۡتَـٔۡنِسِينَ لِحَدِيثٍۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ يُؤۡذِي ٱلنَّبِيَّ فَيَسۡتَحۡيِۦ مِنكُمۡۖ وَٱللَّهُ لَا يَسۡتَحۡيِۦ مِنَ ٱلۡحَقِّۚ وَإِذَا سَأَلۡتُمُوهُنَّ مَتَٰعٗا فَسۡـَٔلُوهُنَّ مِن وَرَآءِ حِجَابٖۚ ذَٰلِكُمۡ أَطۡهَرُ لِقُلُوبِكُمۡ وَقُلُوبِهِنَّۚ وَمَا كَانَ لَكُمۡ أَن تُؤۡذُواْ رَسُولَ ٱللَّهِ وَلَآ أَن تَنكِحُوٓاْ أَزۡوَٰجَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦٓ أَبَدًاۚ إِنَّ ذَٰلِكُمۡ كَانَ عِندَ ٱللَّهِ عَظِيمًا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn inú ilé Ànábì àfi tí wọ́n bá yọ̀ǹda fun yín láti wọlé jẹun láì níí jẹ́ ẹni tí yóò máa retí kí oúnjẹ jinná, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pè yín (fún oúnjẹ) ẹ wọ inú ilé nígbà náà. Nígbà tí ẹ bá sì jẹun tán, ẹ túká, ẹ má ṣe jókòó kalẹ̀ tira yin fún ọ̀rọ̀ kan mọ́ (nínú ilé rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn ń kó ìnira bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì ń tijú yín. Allāhu kò sì níí tijú níbi òdodo. Nígbà tí ẹ bá sì fẹ́ bèèrè n̄ǹkan ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀, ẹ bèèrè rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn ní ẹ̀yìn gàgá. Ìyẹn jẹ́ àfọ̀mọ́ jùlọ fún ọkàn yín àti ọkàn wọn. Kò tọ́ fun yín láti kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu. (Kò sì tọ́ fun yín) láti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ láéláé. Dájúdájú ìyẹn jẹ́ n̄ǹkan ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 53


إِن تُبۡدُواْ شَيۡـًٔا أَوۡ تُخۡفُوهُ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا

Tí ẹ bá ṣàfi hàn kiní kan tàbí ẹ fi pamọ́, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan
Surah Al-Ahzab, Verse 54


لَّا جُنَاحَ عَلَيۡهِنَّ فِيٓ ءَابَآئِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآئِهِنَّ وَلَآ إِخۡوَٰنِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآءِ إِخۡوَٰنِهِنَّ وَلَآ أَبۡنَآءِ أَخَوَٰتِهِنَّ وَلَا نِسَآئِهِنَّ وَلَا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُنَّۗ وَٱتَّقِينَ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدًا

Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ìyàwó Ànábì nípa àwọn bàbá wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn àti àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn àti àwọn ẹrúkùnrin wọn (láti wọlé tì wọ́n.) Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan
Surah Al-Ahzab, Verse 55


إِنَّ ٱللَّهَ وَمَلَـٰٓئِكَتَهُۥ يُصَلُّونَ عَلَى ٱلنَّبِيِّۚ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ صَلُّواْ عَلَيۡهِ وَسَلِّمُواْ تَسۡلِيمًا

Dájúdájú Allāhu àti àwọn mọlāika Rẹ̀ ń kẹ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tọrọ ìkẹ́ fún un, kí ẹ sì kí i ní kíkí àlàáfíà. àwọn Sọhābah náa (r.ahm) máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn àáfà sunnah ṣe ń ṣe asọlātu fún Ànábì nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú nínú àwọn tírà wọn. Kò sí aburú nínú èyí rárá. Ṣùgbọ́n mùsùlùmí yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìhun asọlātu dáràn tí ó bá fi lè kó sínú ọ̀kan nínú àwọn n̄ǹkan mẹ́fà kan. Ìkíní: Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí òfin àti àdìsọ́kàn ’Islām nínú àwọn gbólóhùn asọlātu náà. Ìkejì: Sísọ gbólóhùn asọlātu yẹn gan-angan di ìlànà tí wọn yóò máa pèpè sí tí irúfẹ́ gbólóhùn náà yóò fi wá dà bí ẹni pé hadīth kan l’ó gbà á wá
Surah Al-Ahzab, Verse 56


إِنَّ ٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمۡ عَذَابٗا مُّهِينٗا

Dájúdájú àwọn t’ó ń fi ìnira kan Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn nílé ayé àti ní ọ̀run. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ dè wọ́n
Surah Al-Ahzab, Verse 57


وَٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ بِغَيۡرِ مَا ٱكۡتَسَبُواْ فَقَدِ ٱحۡتَمَلُواْ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا

Àwọn t’ó ń fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin nípa n̄ǹkan tí wọn kò ṣe, dájúdájú wọ́n ti ru ẹrù (ọ̀ràn) ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé
Surah Al-Ahzab, Verse 58


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَآءِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ يُدۡنِينَ عَلَيۡهِنَّ مِن جَلَٰبِيبِهِنَّۚ ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن يُعۡرَفۡنَ فَلَا يُؤۡذَيۡنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا

Ìwọ Ànábì sọ fún àwọn ìyàwó rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ òdodo pé kí wọ́n máa gbé àwọn aṣọ jilbāb wọn wọ̀ sí ara wọn bámúbámú. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti fi mọ̀ wọ́n (ní olùbẹ̀rù Allāhu). Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò níí fi ìnira kàn wọ́n. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Ahzab, Verse 59


۞لَّئِن لَّمۡ يَنتَهِ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ وَٱلۡمُرۡجِفُونَ فِي ٱلۡمَدِينَةِ لَنُغۡرِيَنَّكَ بِهِمۡ ثُمَّ لَا يُجَاوِرُونَكَ فِيهَآ إِلَّا قَلِيلٗا

Tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí, àti àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn túlétúlé nínú ìlú Mọdīnah kò bá jáwọ́ (níbi aburú), dájúdájú A máa dẹ ọ́ sí wọn, (o sì máa borí wọn). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí bá ọ gbé àdúgbò pọ̀ mọ́ àfi fún ìgbà díẹ̀
Surah Al-Ahzab, Verse 60


مَّلۡعُونِينَۖ أَيۡنَمَا ثُقِفُوٓاْ أُخِذُواْ وَقُتِّلُواْ تَقۡتِيلٗا

Wọ́n di ẹni-ìṣẹ́bilé níbikíbi tí ọwọ́ bá ti bà wọ́n; wọ́n máa mú wọn, wọ́n sì máa pa wọ́n tààrà
Surah Al-Ahzab, Verse 61


سُنَّةَ ٱللَّهِ فِي ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلُۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗا

(Ó jẹ́) ìṣe Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 62


يَسۡـَٔلُكَ ٱلنَّاسُ عَنِ ٱلسَّاعَةِۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ ٱللَّهِۚ وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّ ٱلسَّاعَةَ تَكُونُ قَرِيبًا

Àwọn ènìyàn ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo ni ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!”
Surah Al-Ahzab, Verse 63


إِنَّ ٱللَّهَ لَعَنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَأَعَدَّ لَهُمۡ سَعِيرًا

Dájúdájú Allāhu ṣẹ́bi le àwọn aláìgbàgbọ́. Ó sì pèsè Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n
Surah Al-Ahzab, Verse 64


خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ لَّا يَجِدُونَ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé; wọn kò níí rí olùṣọ́ tàbí alárànṣe kan
Surah Al-Ahzab, Verse 65


يَوۡمَ تُقَلَّبُ وُجُوهُهُمۡ فِي ٱلنَّارِ يَقُولُونَ يَٰلَيۡتَنَآ أَطَعۡنَا ٱللَّهَ وَأَطَعۡنَا ٱلرَّسُولَا۠

Ní ọjọ́ tí A óò yí ojú wọn padà nínú Iná, wọn yó sì wí pé: “Yéè! Àwa ìbá tẹ̀lé ti Allāhu, àwa ìbá sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́.”
Surah Al-Ahzab, Verse 66


وَقَالُواْ رَبَّنَآ إِنَّآ أَطَعۡنَا سَادَتَنَا وَكُبَرَآءَنَا فَأَضَلُّونَا ٱلسَّبِيلَا۠

Wọ́n wí pé: “Olúwa wa! Dájúdájú àwa tẹ̀lé àwọn aṣíwájú wa àti àwọn àgbààgbà wa. Wọ́n sì ṣì wá lọ́nà
Surah Al-Ahzab, Verse 67


رَبَّنَآ ءَاتِهِمۡ ضِعۡفَيۡنِ مِنَ ٱلۡعَذَابِ وَٱلۡعَنۡهُمۡ لَعۡنٗا كَبِيرٗا

Olúwa wa! Fún wọn ní ìlọ́po méjì nínú ìyà. Kí O sì ṣẹ́bi lé wọn ní ìṣẹ́bi t’ó tóbi.”
Surah Al-Ahzab, Verse 68


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ ءَاذَوۡاْ مُوسَىٰ فَبَرَّأَهُ ٱللَّهُ مِمَّا قَالُواْۚ وَكَانَ عِندَ ٱللَّهِ وَجِيهٗا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó fi ìnira kan (Ànábì) Mūsā. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ rẹ̀ nínú ohun tí wọ́n wí. Ó sì jẹ́ ẹni abiyì lọ́dọ̀ Allāhu
Surah Al-Ahzab, Verse 69


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَقُولُواْ قَوۡلٗا سَدِيدٗا

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì sọ ọ̀rọ̀ òdodo
Surah Al-Ahzab, Verse 70


يُصۡلِحۡ لَكُمۡ أَعۡمَٰلَكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡۗ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَقَدۡ فَازَ فَوۡزًا عَظِيمًا

(Allāhu) máa ṣàtúnṣe àwọn iṣẹ́ yín fun yín, Ó sì máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Àti pé ẹni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ó kúkú ti jèrè ní èrèǹjẹ ńlá
Surah Al-Ahzab, Verse 71


إِنَّا عَرَضۡنَا ٱلۡأَمَانَةَ عَلَى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡجِبَالِ فَأَبَيۡنَ أَن يَحۡمِلۡنَهَا وَأَشۡفَقۡنَ مِنۡهَا وَحَمَلَهَا ٱلۡإِنسَٰنُۖ إِنَّهُۥ كَانَ ظَلُومٗا جَهُولٗا

Dájúdájú Àwa fi iṣẹ́ láádá lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan
Surah Al-Ahzab, Verse 72


لِّيُعَذِّبَ ٱللَّهُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ وَٱلۡمُشۡرِكَٰتِ وَيَتُوبَ ٱللَّهُ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمَۢا

(Ènìyàn tẹ́rí gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá) nítorí kí Allāhu lè fi ìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn ọ̀sẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin àti nítorí kí Allāhu lè gba ìronúpìwàdà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Ahzab, Verse 73


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 32
>> Surah 34

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai