UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Saba - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Àti pé tiRẹ̀ ni gbogbo ọpẹ́ ní ọ̀run. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán
Surah Saba, Verse 1


يَعۡلَمُ مَا يَلِجُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا يَخۡرُجُ مِنۡهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا يَعۡرُجُ فِيهَاۚ وَهُوَ ٱلرَّحِيمُ ٱلۡغَفُورُ

Ó mọ ohunkóhun t’ó ń wọnú ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń jáde látinú rẹ̀. (Ó mọ) ohunkóhun t’ó ń sọ̀kalẹ̀ látinú sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó ń gùnkè lọ sínú rẹ̀. Òun sì ni Àṣàkẹ́-ọ̀run, Aláforíjìn
Surah Saba, Verse 2


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَأۡتِينَا ٱلسَّاعَةُۖ قُلۡ بَلَىٰ وَرَبِّي لَتَأۡتِيَنَّكُمۡ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِۖ لَا يَعۡزُبُ عَنۡهُ مِثۡقَالُ ذَرَّةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَآ أَصۡغَرُ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرُ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ

Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Àkókò náà kò níí dé bá wa.” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́. Èmi fi Olúwa mi búra. Dájúdájú ó máa dé ba yín (láti ọ̀dọ̀) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (Ẹni tí) òdiwọ̀n ọmọ iná-igún kò pamọ́ fún nínú sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. (Kò sí n̄ǹkan tí ó) kéré sí ìyẹn tàbí tí ó tóbi (jù ú lọ) àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.”
Surah Saba, Verse 3


لِّيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ

(Ó máa ṣẹlẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún
Surah Saba, Verse 4


وَٱلَّذِينَ سَعَوۡ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مِّن رِّجۡزٍ أَلِيمٞ

Àti pé àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ burúkú nípa àwọn āyah Wa, (tí wọ́n lérò pé) àwọn mórí bọ́ nínú ìyà; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléró t’ó burú ń bẹ fún
Surah Saba, Verse 5


وَيَرَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَ هُوَ ٱلۡحَقَّ وَيَهۡدِيٓ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ

Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ rí i pé èyí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, òhun ni òdodo, àti pé ó ń ṣe ìtọ́sọ́nà sí ọ̀nà Alágbára, Ẹlẹ́yìn
Surah Saba, Verse 6


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ هَلۡ نَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ رَجُلٖ يُنَبِّئُكُمۡ إِذَا مُزِّقۡتُمۡ كُلَّ مُمَزَّقٍ إِنَّكُمۡ لَفِي خَلۡقٖ جَدِيدٍ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé kí á tọ́ka yín sí ọkùnrin kan tí ó máa fun yín ní ìró pé nígbà tí wọ́n bá fọn yín ká tán pátápátá (sínú erùpẹ̀), pé dájúdájú ẹ máa padà wà ní ẹ̀dá titun
Surah Saba, Verse 7


أَفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَم بِهِۦ جِنَّةُۢۗ بَلِ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ فِي ٱلۡعَذَابِ وَٱلضَّلَٰلِ ٱلۡبَعِيدِ

Ṣé ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni tàbí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀ ni?” Rárá o! Àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ti wà nínú ìyà àti ìṣìnà t’ó jìnnà
Surah Saba, Verse 8


أَفَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِن نَّشَأۡ نَخۡسِفۡ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ نُسۡقِطۡ عَلَيۡهِمۡ كِسَفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّكُلِّ عَبۡدٖ مُّنِيبٖ

Ṣé wọn kò rí ohun t’ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t’ó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà
Surah Saba, Verse 9


۞وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ مِنَّا فَضۡلٗاۖ يَٰجِبَالُ أَوِّبِي مَعَهُۥ وَٱلطَّيۡرَۖ وَأَلَنَّا لَهُ ٱلۡحَدِيدَ

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un
Surah Saba, Verse 10


أَنِ ٱعۡمَلۡ سَٰبِغَٰتٖ وَقَدِّرۡ فِي ٱلسَّرۡدِۖ وَٱعۡمَلُواْ صَٰلِحًاۖ إِنِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

(A sọ fún un) pé ṣe àwọn ẹ̀wù irin t’ó máa bo ara, ṣe òrùka-ọrùn fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Saba, Verse 11


وَلِسُلَيۡمَٰنَ ٱلرِّيحَ غُدُوُّهَا شَهۡرٞ وَرَوَاحُهَا شَهۡرٞۖ وَأَسَلۡنَا لَهُۥ عَيۡنَ ٱلۡقِطۡرِۖ وَمِنَ ٱلۡجِنِّ مَن يَعۡمَلُ بَيۡنَ يَدَيۡهِ بِإِذۡنِ رَبِّهِۦۖ وَمَن يَزِغۡ مِنۡهُمۡ عَنۡ أَمۡرِنَا نُذِقۡهُ مِنۡ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ

Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀ . A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí t’ó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná t’ó ń jò fòfò tọ́ wò
Surah Saba, Verse 12


يَعۡمَلُونَ لَهُۥ مَا يَشَآءُ مِن مَّحَٰرِيبَ وَتَمَٰثِيلَ وَجِفَانٖ كَٱلۡجَوَابِ وَقُدُورٖ رَّاسِيَٰتٍۚ ٱعۡمَلُوٓاْ ءَالَ دَاوُۥدَ شُكۡرٗاۚ وَقَلِيلٞ مِّنۡ عِبَادِيَ ٱلشَّكُورُ

Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé t’ó dára, àwọn ère, àwo kòtò fífẹ̀ bí àbàtà àti àwọn ìkòkò t’ó rídìí múlẹ̀. Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́
Surah Saba, Verse 13


فَلَمَّا قَضَيۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَوۡتَ مَا دَلَّهُمۡ عَلَىٰ مَوۡتِهِۦٓ إِلَّا دَآبَّةُ ٱلۡأَرۡضِ تَأۡكُلُ مِنسَأَتَهُۥۖ فَلَمَّا خَرَّ تَبَيَّنَتِ ٱلۡجِنُّ أَن لَّوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ٱلۡغَيۡبَ مَا لَبِثُواْ فِي ٱلۡعَذَابِ ٱلۡمُهِينِ

Nígbà tí A pàṣẹ pé kí ikú pa (Ànábì) Sulaemọ̄n, kò sí ohun tí ó mú àwọn àlùjànnú mọ̀ pé ó ti kú bí kò ṣe kòkòrò inú ilẹ̀ kan tí ó jẹ ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó wó lulẹ̀, ó hàn kedere sí àwọn àlùjànnú pé tí ó bá jẹ́ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, àwọn ìbá tí wà nínú (iṣẹ́) ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá
Surah Saba, Verse 14


لَقَدۡ كَانَ لِسَبَإٖ فِي مَسۡكَنِهِمۡ ءَايَةٞۖ جَنَّتَانِ عَن يَمِينٖ وَشِمَالٖۖ كُلُواْ مِن رِّزۡقِ رَبِّكُمۡ وَٱشۡكُرُواْ لَهُۥۚ بَلۡدَةٞ طَيِّبَةٞ وَرَبٌّ غَفُورٞ

Dájúdájú àmì kan wà fún àwọn Saba’ nínú ibùgbé wọn; (òhun ni) ọgbà oko méjì t’ó wà ní ọ̀tún àti ní òsì. “Ẹ jẹ nínú arísìkí Olúwa yín. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un.” Ìlú t’ó dára ni (ilẹ̀ Saba’. Allāhu sì ni) Olúwa Aláforíjìn
Surah Saba, Verse 15


فَأَعۡرَضُواْ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ سَيۡلَ ٱلۡعَرِمِ وَبَدَّلۡنَٰهُم بِجَنَّتَيۡهِمۡ جَنَّتَيۡنِ ذَوَاتَيۡ أُكُلٍ خَمۡطٖ وَأَثۡلٖ وَشَيۡءٖ مِّن سِدۡرٖ قَلِيلٖ

Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko eléso kíkorò, oko igi ẹlẹ́gùn-ún àti kiní kan díẹ̀ nínú igi sidir
Surah Saba, Verse 16


ذَٰلِكَ جَزَيۡنَٰهُم بِمَا كَفَرُواْۖ وَهَلۡ نُجَٰزِيٓ إِلَّا ٱلۡكَفُورَ

Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé wọ́n ṣàì moore. Ǹjẹ́ A máa san ẹnì kan lẹ́san ìyà bí kò ṣe aláìmoore
Surah Saba, Verse 17


وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ ٱلۡقُرَى ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَا قُرٗى ظَٰهِرَةٗ وَقَدَّرۡنَا فِيهَا ٱلسَّيۡرَۖ سِيرُواْ فِيهَا لَيَالِيَ وَأَيَّامًا ءَامِنِينَ

A sì fi àwọn ìlú kan t’ó hàn sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà. Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀
Surah Saba, Verse 18


فَقَالُواْ رَبَّنَا بَٰعِدۡ بَيۡنَ أَسۡفَارِنَا وَظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَحَادِيثَ وَمَزَّقۡنَٰهُمۡ كُلَّ مُمَزَّقٍۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ

(Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. A sì sọ wọ́n di ìtàn. A sì fọ́n wọn ká pátápátá. Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́
Surah Saba, Verse 19


وَلَقَدۡ صَدَّقَ عَلَيۡهِمۡ إِبۡلِيسُ ظَنَّهُۥ فَٱتَّبَعُوهُ إِلَّا فَرِيقٗا مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú ’Iblīs ti sọ àbá rẹ̀ di òdodo lé wọn lórí. Wọ́n sì tẹ̀lé e àfi igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Saba, Verse 20


وَمَا كَانَ لَهُۥ عَلَيۡهِم مِّن سُلۡطَٰنٍ إِلَّا لِنَعۡلَمَ مَن يُؤۡمِنُ بِٱلۡأٓخِرَةِ مِمَّنۡ هُوَ مِنۡهَا فِي شَكّٖۗ وَرَبُّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ

(’Iblīs) kò sì ní agbára kan lórí wọn bí kò ṣe pé kí A lè ṣàfi hàn ẹni t’ó gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ kúrò lára ẹni t’ó wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀. Olùṣọ́ sì ni Olúwa rẹ lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Saba, Verse 21


قُلِ ٱدۡعُواْ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا لَهُمۡ فِيهِمَا مِن شِرۡكٖ وَمَا لَهُۥ مِنۡهُم مِّن ظَهِيرٖ

Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ olúwa) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn
Surah Saba, Verse 22


وَلَا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ عِندَهُۥٓ إِلَّا لِمَنۡ أَذِنَ لَهُۥۚ حَتَّىٰٓ إِذَا فُزِّعَ عَن قُلُوبِهِمۡ قَالُواْ مَاذَا قَالَ رَبُّكُمۡۖ قَالُواْ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ

Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi
Surah Saba, Verse 23


۞قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قُلِ ٱللَّهُۖ وَإِنَّآ أَوۡ إِيَّاكُمۡ لَعَلَىٰ هُدًى أَوۡ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ

Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Dájúdájú àwa tàbí ẹ̀yin wà nínú ìmọ̀nà tàbí nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
Surah Saba, Verse 24


قُل لَّا تُسۡـَٔلُونَ عَمَّآ أَجۡرَمۡنَا وَلَا نُسۡـَٔلُ عَمَّا تَعۡمَلُونَ

Sọ pé: “Wọn kò níí bi yín léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá; wọn kò sì níí bi àwa náà nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Surah Saba, Verse 25


قُلۡ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَا رَبُّنَا ثُمَّ يَفۡتَحُ بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَهُوَ ٱلۡفَتَّاحُ ٱلۡعَلِيمُ

Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.”
Surah Saba, Verse 26


قُلۡ أَرُونِيَ ٱلَّذِينَ أَلۡحَقۡتُم بِهِۦ شُرَكَآءَۖ كَلَّاۚ بَلۡ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Sọ pé: “Ẹ fi hàn mí ná àwọn òrìṣà tí ẹ dàpọ̀ mọ́ Allāhu.” Rárá (kò ní akẹgbẹ́). Rárá sẹ́, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Saba, Verse 27


وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ

A ò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀
Surah Saba, Verse 28


وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Surah Saba, Verse 29


قُل لَّكُم مِّيعَادُ يَوۡمٖ لَّا تَسۡتَـٔۡخِرُونَ عَنۡهُ سَاعَةٗ وَلَا تَسۡتَقۡدِمُونَ

Sọ pé: “Àdéhùn ọjọ́ kan ń bẹ fun yín, tí ẹ̀yin kò lè sún síwájú di ìgbà kan, ẹ ò sì lè fà á sẹ́yìn.”
Surah Saba, Verse 30


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن نُّؤۡمِنَ بِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَلَا بِٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّـٰلِمُونَ مَوۡقُوفُونَ عِندَ رَبِّهِمۡ يَرۡجِعُ بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٍ ٱلۡقَوۡلَ يَقُولُ ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُواْ لَوۡلَآ أَنتُمۡ لَكُنَّا مُؤۡمِنِينَ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “A ò níí ní ìgbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān yìí àti èyí t’ó wá ṣíwájú rẹ̀.” Tí ó bá jẹ́ pé o bá rí wọn ni nígbà tí wọ́n bá dá àwọn alábòsí dúró níwájú Olúwa wọn, (o máa rí wọn tí) apá kan wọn yóò dá ọ̀rọ̀ náà padà sí apá kan; àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ (nínú wọn) yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga (nínú wọn) pé: “Tí kì í bá ṣe ẹ̀yin ni, àwa ìbá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Surah Saba, Verse 31


قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُواْ لِلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُوٓاْ أَنَحۡنُ صَدَدۡنَٰكُمۡ عَنِ ٱلۡهُدَىٰ بَعۡدَ إِذۡ جَآءَكُمۖ بَلۡ كُنتُم مُّجۡرِمِينَ

Àwọn t’ó ṣègbéraga yó sì wí fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ pé: “Ṣé àwa l’a ṣẹ yín lórí kúrò nínú ìmọ̀nà lẹ́yìn tí ó dé ba yín? Rárá o! Ọ̀daràn ni yín ni.”
Surah Saba, Verse 32


وَقَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُواْ بَلۡ مَكۡرُ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ إِذۡ تَأۡمُرُونَنَآ أَن نَّكۡفُرَ بِٱللَّهِ وَنَجۡعَلَ لَهُۥٓ أَندَادٗاۚ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۚ وَجَعَلۡنَا ٱلۡأَغۡلَٰلَ فِيٓ أَعۡنَاقِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ هَلۡ يُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ yó sì wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Rárá! Ète òru àti ọ̀sán (láti ọ̀dọ̀ yín lókó bá wa) nígbà tí ẹ̀ ń pa wá ní àṣẹ pé kí á ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí á sì sọ (àwọn kan) di ẹgbẹ́ Rẹ̀.” Wọ́n fi àbámọ̀ wọn pamọ́ nígbà tí wọ́n rí ìyà. A sì kó ẹ̀wọ̀n sí ọrùn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Saba, Verse 33


وَمَآ أَرۡسَلۡنَا فِي قَرۡيَةٖ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتۡرَفُوهَآ إِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ

Àti pé A ò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
Surah Saba, Verse 34


وَقَالُواْ نَحۡنُ أَكۡثَرُ أَمۡوَٰلٗا وَأَوۡلَٰدٗا وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ

Wọ́n tún wí pé: “Àwa ní dúkìá àti ọmọ jù (yín lọ); wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
Surah Saba, Verse 35


قُلۡ إِنَّ رَبِّي يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ

Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀
Surah Saba, Verse 36


وَمَآ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُم بِٱلَّتِي تُقَرِّبُكُمۡ عِندَنَا زُلۡفَىٰٓ إِلَّا مَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَأُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ جَزَآءُ ٱلضِّعۡفِ بِمَا عَمِلُواْ وَهُمۡ فِي ٱلۡغُرُفَٰتِ ءَامِنُونَ

Kì í ṣe àwọn dúkìá yín, kì í sì ṣe àwọn ọmọ yín ni n̄ǹkan tí ó máa mu yín súnmọ́ Wa pẹ́kípẹ́kí àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san ìlọ́po wà fún nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Wọn yó sì wà nínú àwọn ipò gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀
Surah Saba, Verse 37


وَٱلَّذِينَ يَسۡعَوۡنَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَـٰٓئِكَ فِي ٱلۡعَذَابِ مُحۡضَرُونَ

Àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú nípa àwọn āyah Wa, (tí wọ́n lérò pé) àwọn mórí bọ́ nínú ìyà; àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa mú wá sínú Iná.”
Surah Saba, Verse 38


قُلۡ إِنَّ رَبِّي يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُ لَهُۥۚ وَمَآ أَنفَقۡتُم مِّن شَيۡءٖ فَهُوَ يُخۡلِفُهُۥۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلرَّـٰزِقِينَ

Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, Òun l’Ó máa fi (òmíràn) rọ́pò rẹ̀. Ó sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”
Surah Saba, Verse 39


وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا ثُمَّ يَقُولُ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ أَهَـٰٓؤُلَآءِ إِيَّاكُمۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ

Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ṣé ẹ̀yin ni wọ́n ń jọ́sìn fún?”
Surah Saba, Verse 40


قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ أَنتَ وَلِيُّنَا مِن دُونِهِمۖ بَلۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ ٱلۡجِنَّۖ أَكۡثَرُهُم بِهِم مُّؤۡمِنُونَ

Wọ́n á sọ pé: “Mímọ́ fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gba àlùjànnú gbọ́
Surah Saba, Verse 41


فَٱلۡيَوۡمَ لَا يَمۡلِكُ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٖ نَّفۡعٗا وَلَا ضَرّٗا وَنَقُولُ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّتِي كُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ

Nítorí náà, ní òní apá kan yín kò ní ìkápá àǹfààní, kò sì ní ìkápá ìnira fún apá kan. A sì máa sọ fún àwọn t’ó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.”
Surah Saba, Verse 42


وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّا رَجُلٞ يُرِيدُ أَن يَصُدَّكُمۡ عَمَّا كَانَ يَعۡبُدُ ءَابَآؤُكُمۡ وَقَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّآ إِفۡكٞ مُّفۡتَرٗىۚ وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, wọ́n á wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá yín ń jọ́sìn fún.” Wọ́n tún wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́.” Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí nípa òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
Surah Saba, Verse 43


وَمَآ ءَاتَيۡنَٰهُم مِّن كُتُبٖ يَدۡرُسُونَهَاۖ وَمَآ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمۡ قَبۡلَكَ مِن نَّذِيرٖ

A ò fún wọn ní àwọn tírà kan kan tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀, A ò sì rán olùkìlọ̀ kan kan sí wọn ṣíwájú rẹ
Surah Saba, Verse 44


وَكَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَمَا بَلَغُواْ مِعۡشَارَ مَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ فَكَذَّبُواْ رُسُلِيۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ

Àwọn t’ó ṣíwájú wọn náà pe òdodo nírọ́. (Ọwọ́ àwọn wọ̀nyí) kò sì tí ì tẹ ìdá kan ìdá mẹ́wàá nínú ohun tí A fún (àwọn t’ó ṣíwájú). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ Mi ní òpùrọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí
Surah Saba, Verse 45


۞قُلۡ إِنَّمَآ أَعِظُكُم بِوَٰحِدَةٍۖ أَن تَقُومُواْ لِلَّهِ مَثۡنَىٰ وَفُرَٰدَىٰ ثُمَّ تَتَفَكَّرُواْۚ مَا بِصَاحِبِكُم مِّن جِنَّةٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا نَذِيرٞ لَّكُم بَيۡنَ يَدَيۡ عَذَابٖ شَدِيدٖ

Sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo ni mò ń ṣe wáàsí rẹ̀ fun yín pé, ẹ dúró nítorí ti Allāhu ní méjì àti ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú jinlẹ̀. Kò sí àlùjànnú kan lára ẹni yín. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ fun yín ṣíwájú ìyà líle kan.”
Surah Saba, Verse 46


قُلۡ مَا سَأَلۡتُكُم مِّنۡ أَجۡرٖ فَهُوَ لَكُمۡۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٞ

Sọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan, ẹ̀yin lẹ kúkú lowó yín. Kò sí owó ọ̀yà mi (lọ́dọ̀ ẹnì kan) àfi lọ́dọ̀ Allāhu. Òun sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.”
Surah Saba, Verse 47


قُلۡ إِنَّ رَبِّي يَقۡذِفُ بِٱلۡحَقِّ عَلَّـٰمُ ٱلۡغُيُوبِ

Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ l’Ó ń mú òdodo wá.”
Surah Saba, Verse 48


قُلۡ جَآءَ ٱلۡحَقُّ وَمَا يُبۡدِئُ ٱلۡبَٰطِلُ وَمَا يُعِيدُ

Sọ pé: “Òdodo ti dé. Irọ́ (èṣù) kò lè mú n̄ǹkan bẹ, kò sì lè dá n̄ǹkan padà (lẹ́yìn tó ti kú).”
Surah Saba, Verse 49


قُلۡ إِن ضَلَلۡتُ فَإِنَّمَآ أَضِلُّ عَلَىٰ نَفۡسِيۖ وَإِنِ ٱهۡتَدَيۡتُ فَبِمَا يُوحِيٓ إِلَيَّ رَبِّيٓۚ إِنَّهُۥ سَمِيعٞ قَرِيبٞ

Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”
Surah Saba, Verse 50


وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ فَزِعُواْ فَلَا فَوۡتَ وَأُخِذُواْ مِن مَّكَانٖ قَرِيبٖ

Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè t’ó súnmọ́
Surah Saba, Verse 51


وَقَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦ وَأَنَّىٰ لَهُمُ ٱلتَّنَاوُشُ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ

Wọn yóò wí pé: “A gbàgbọ́ nínú (al-Ƙur’ān báyìí).” Báwo ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìgbàgbọ́ òdodo láti àyè t’ó jìnnà (ìyẹn, ọ̀run).”
Surah Saba, Verse 52


وَقَدۡ كَفَرُواْ بِهِۦ مِن قَبۡلُۖ وَيَقۡذِفُونَ بِٱلۡغَيۡبِ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ

Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣíwájú (nílé ayé). Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀kọ̀ láti àyè t’ó jìnnà (ìyẹn, ilé ayé)
Surah Saba, Verse 53


وَحِيلَ بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ مَا يَشۡتَهُونَ كَمَا فُعِلَ بِأَشۡيَاعِهِم مِّن قَبۡلُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ فِي شَكّٖ مُّرِيبِۭ

A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde)
Surah Saba, Verse 54


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 33
>> Surah 35

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai