UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Fatir - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ جَاعِلِ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ رُسُلًا أُوْلِيٓ أَجۡنِحَةٖ مَّثۡنَىٰ وَثُلَٰثَ وَرُبَٰعَۚ يَزِيدُ فِي ٱلۡخَلۡقِ مَا يَشَآءُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Fatir, Verse 1


مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dá a dúró. Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Fatir, Verse 2


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ هَلۡ مِنۡ خَٰلِقٍ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ

Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo
Surah Fatir, Verse 3


وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ

Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí
Surah Fatir, Verse 4


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ

Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ
Surah Fatir, Verse 5


إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لَكُمۡ عَدُوّٞ فَٱتَّخِذُوهُ عَدُوًّاۚ إِنَّمَا يَدۡعُواْ حِزۡبَهُۥ لِيَكُونُواْ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ

Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fun yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná t’ó ń jò fòfò
Surah Fatir, Verse 6


ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٌ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi ń bẹ fún wọn
Surah Fatir, Verse 7


أَفَمَن زُيِّنَ لَهُۥ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ فَرَءَاهُ حَسَنٗاۖ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُضِلُّ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۖ فَلَا تَذۡهَبۡ نَفۡسُكَ عَلَيۡهِمۡ حَسَرَٰتٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا يَصۡنَعُونَ

Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l’o fẹ́ banújẹ́ lé lórí?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe
Surah Fatir, Verse 8


وَٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ ٱلرِّيَٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابٗا فَسُقۡنَٰهُ إِلَىٰ بَلَدٖ مَّيِّتٖ فَأَحۡيَيۡنَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ كَذَٰلِكَ ٱلنُّشُورُ

Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí)
Surah Fatir, Verse 9


مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعِزَّةَ فَلِلَّهِ ٱلۡعِزَّةُ جَمِيعًاۚ إِلَيۡهِ يَصۡعَدُ ٱلۡكَلِمُ ٱلطَّيِّبُ وَٱلۡعَمَلُ ٱلصَّـٰلِحُ يَرۡفَعُهُۥۚ وَٱلَّذِينَ يَمۡكُرُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۖ وَمَكۡرُ أُوْلَـٰٓئِكَ هُوَ يَبُورُ

Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun
Surah Fatir, Verse 10


وَٱللَّهُ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ جَعَلَكُمۡ أَزۡوَٰجٗاۚ وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَمَا يُعَمَّرُ مِن مُّعَمَّرٖ وَلَا يُنقَصُ مِنۡ عُمُرِهِۦٓ إِلَّا فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ

Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A ò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A ò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu
Surah Fatir, Verse 11


وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡبَحۡرَانِ هَٰذَا عَذۡبٞ فُرَاتٞ سَآئِغٞ شَرَابُهُۥ وَهَٰذَا مِلۡحٌ أُجَاجٞۖ وَمِن كُلّٖ تَأۡكُلُونَ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُونَ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ فِيهِ مَوَاخِرَ لِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín lọ́fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ t’ó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l’ẹ ti ń jẹ ẹran (ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí ki ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)
Surah Fatir, Verse 12


يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۚ وَٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ مَا يَمۡلِكُونَ مِن قِطۡمِيرٍ

(Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù
Surah Fatir, Verse 13


إِن تَدۡعُوهُمۡ لَا يَسۡمَعُواْ دُعَآءَكُمۡ وَلَوۡ سَمِعُواْ مَا ٱسۡتَجَابُواْ لَكُمۡۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكۡفُرُونَ بِشِرۡكِكُمۡۚ وَلَا يُنَبِّئُكَ مِثۡلُ خَبِيرٖ

Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn)
Surah Fatir, Verse 14


۞يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ أَنتُمُ ٱلۡفُقَرَآءُ إِلَى ٱللَّهِۖ وَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ

Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́
Surah Fatir, Verse 15


إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ وَيَأۡتِ بِخَلۡقٖ جَدِيدٖ

Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò nílẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá
Surah Fatir, Verse 16


وَمَا ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ بِعَزِيزٖ

Ìyẹn kò sì kágara kan bá Allāhu
Surah Fatir, Verse 17


وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ وَإِن تَدۡعُ مُثۡقَلَةٌ إِلَىٰ حِمۡلِهَا لَا يُحۡمَلۡ مِنۡهُ شَيۡءٞ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰٓۗ إِنَّمَا تُنذِرُ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُم بِٱلۡغَيۡبِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَۚ وَمَن تَزَكَّىٰ فَإِنَّمَا يَتَزَكَّىٰ لِنَفۡسِهِۦۚ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ

Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan. Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá
Surah Fatir, Verse 18


وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ

Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba
Surah Fatir, Verse 19


وَلَا ٱلظُّلُمَٰتُ وَلَا ٱلنُّورُ

Àwọn òòkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba)
Surah Fatir, Verse 20


وَلَا ٱلظِّلُّ وَلَا ٱلۡحَرُورُ

Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba)
Surah Fatir, Verse 21


وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَحۡيَآءُ وَلَا ٱلۡأَمۡوَٰتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُسۡمِعُ مَن يَشَآءُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُسۡمِعٖ مَّن فِي ٱلۡقُبُورِ

Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́
Surah Fatir, Verse 22


إِنۡ أَنتَ إِلَّا نَذِيرٌ

Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀
Surah Fatir, Verse 23


إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗاۚ وَإِن مِّنۡ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٞ

Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn
Surah Fatir, Verse 24


وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَبِٱلزُّبُرِ وَبِٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ

Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn t’ó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
Surah Fatir, Verse 25


ثُمَّ أَخَذۡتُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ

Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí
Surah Fatir, Verse 26


أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦ ثَمَرَٰتٖ مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهَاۚ وَمِنَ ٱلۡجِبَالِ جُدَدُۢ بِيضٞ وَحُمۡرٞ مُّخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٞ

Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn pẹ̀lú aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta
Surah Fatir, Verse 27


وَمِنَ ٱلنَّاسِ وَٱلدَّوَآبِّ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مُخۡتَلِفٌ أَلۡوَٰنُهُۥ كَذَٰلِكَۗ إِنَّمَا يَخۡشَى ٱللَّهَ مِنۡ عِبَادِهِ ٱلۡعُلَمَـٰٓؤُاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ

Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn t’ó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn
Surah Fatir, Verse 28


إِنَّ ٱلَّذِينَ يَتۡلُونَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَنفَقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ يَرۡجُونَ تِجَٰرَةٗ لَّن تَبُورَ

Dájúdájú àwọn t’ó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun
Surah Fatir, Verse 29


لِيُوَفِّيَهُمۡ أُجُورَهُمۡ وَيَزِيدَهُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ غَفُورٞ شَكُورٞ

(Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́
Surah Fatir, Verse 30


وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ هُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِعِبَادِهِۦ لَخَبِيرُۢ بَصِيرٞ

Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀
Surah Fatir, Verse 31


ثُمَّ أَوۡرَثۡنَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِينَ ٱصۡطَفَيۡنَا مِنۡ عِبَادِنَاۖ فَمِنۡهُمۡ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ وَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞ وَمِنۡهُمۡ سَابِقُۢ بِٱلۡخَيۡرَٰتِ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَضۡلُ ٱلۡكَبِيرُ

Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur’ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí t’ó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ t’ó tóbi
Surah Fatir, Verse 32


جَنَّـٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ

Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀
Surah Fatir, Verse 33


وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَذۡهَبَ عَنَّا ٱلۡحَزَنَۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٞ شَكُورٌ

Wọ́n yóò sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́
Surah Fatir, Verse 34


ٱلَّذِيٓ أَحَلَّنَا دَارَ ٱلۡمُقَامَةِ مِن فَضۡلِهِۦ لَا يَمَسُّنَا فِيهَا نَصَبٞ وَلَا يَمَسُّنَا فِيهَا لُغُوبٞ

Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀
Surah Fatir, Verse 35


وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ نَارُ جَهَنَّمَ لَا يُقۡضَىٰ عَلَيۡهِمۡ فَيَمُوتُواْ وَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُم مِّنۡ عَذَابِهَاۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي كُلَّ كَفُورٖ

Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahnamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò sì níí gbé ìyà rẹ̀ fúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san
Surah Fatir, Verse 36


وَهُمۡ يَصۡطَرِخُونَ فِيهَا رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا نَعۡمَلۡ صَٰلِحًا غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ أَوَلَمۡ نُعَمِّرۡكُم مَّا يَتَذَكَّرُ فِيهِ مَن تَذَكَّرَ وَجَآءَكُمُ ٱلنَّذِيرُۖ فَذُوقُواْ فَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٍ

Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe.” Ṣé A ò fun yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí
Surah Fatir, Verse 37


إِنَّ ٱللَّهَ عَٰلِمُ غَيۡبِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá
Surah Fatir, Verse 38


هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَكُمۡ خَلَـٰٓئِفَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ فَمَن كَفَرَ فَعَلَيۡهِ كُفۡرُهُۥۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ إِلَّا مَقۡتٗاۖ وَلَا يَزِيدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ كُفۡرُهُمۡ إِلَّا خَسَارٗا

Òun ní Ẹni t’Ó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò
Surah Fatir, Verse 39


قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ شُرَكَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا فَهُمۡ عَلَىٰ بَيِّنَتٖ مِّنۡهُۚ بَلۡ إِن يَعِدُ ٱلظَّـٰلِمُونَ بَعۡضُهُم بَعۡضًا إِلَّا غُرُورًا

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí t’ó yanjú nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.”
Surah Fatir, Verse 40


۞إِنَّ ٱللَّهَ يُمۡسِكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ أَن تَزُولَاۚ وَلَئِن زَالَتَآ إِنۡ أَمۡسَكَهُمَا مِنۡ أَحَدٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ حَلِيمًا غَفُورٗا

Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn
Surah Fatir, Verse 41


وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَئِن جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ لَّيَكُونُنَّ أَهۡدَىٰ مِنۡ إِحۡدَى ٱلۡأُمَمِۖ فَلَمَّا جَآءَهُمۡ نَذِيرٞ مَّا زَادَهُمۡ إِلَّا نُفُورًا

Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: "Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (t’ó ti ṣíwájú) lọ." Nígbà tí olùkìlọ̀ sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)
Surah Fatir, Verse 42


ٱسۡتِكۡبَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَكۡرَ ٱلسَّيِّيِٕۚ وَلَا يَحِيقُ ٱلۡمَكۡرُ ٱلسَّيِّئُ إِلَّا بِأَهۡلِهِۦۚ فَهَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا سُنَّتَ ٱلۡأَوَّلِينَۚ فَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗاۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّتِ ٱللَّهِ تَحۡوِيلًا

ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ìpète aburú. Ìyà ìpète aburú kò sì níí kò lé ẹnì kan lórí àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́? Nítorí náà, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu
Surah Fatir, Verse 43


أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ وَكَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعۡجِزَهُۥ مِن شَيۡءٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَلِيمٗا قَدِيرٗا

Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára
Surah Fatir, Verse 44


وَلَوۡ يُؤَاخِذُ ٱللَّهُ ٱلنَّاسَ بِمَا كَسَبُواْ مَا تَرَكَ عَلَىٰ ظَهۡرِهَا مِن دَآبَّةٖ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمۡ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗىۖ فَإِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِعِبَادِهِۦ بَصِيرَۢا

Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀
Surah Fatir, Verse 45


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 34
>> Surah 36

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai