UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah As-Saaffat - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


وَٱلصَّـٰٓفَّـٰتِ صَفّٗا

(Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà
Surah As-Saaffat, Verse 1


فَٱلزَّـٰجِرَٰتِ زَجۡرٗا

àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà
Surah As-Saaffat, Verse 2


فَٱلتَّـٰلِيَٰتِ ذِكۡرًا

àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí
Surah As-Saaffat, Verse 3


إِنَّ إِلَٰهَكُمۡ لَوَٰحِدٞ

Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni
Surah As-Saaffat, Verse 4


رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَرَبُّ ٱلۡمَشَٰرِقِ

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn
Surah As-Saaffat, Verse 5


إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ

Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
Surah As-Saaffat, Verse 6


وَحِفۡظٗا مِّن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ مَّارِدٖ

àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun
Surah As-Saaffat, Verse 7


لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰ وَيُقۡذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٖ

(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀)
Surah As-Saaffat, Verse 8


دُحُورٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ وَاصِبٌ

Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn
Surah As-Saaffat, Verse 9


إِلَّا مَنۡ خَطِفَ ٱلۡخَطۡفَةَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ ثَاقِبٞ

(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e
Surah As-Saaffat, Verse 10


فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَهُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَم مَّنۡ خَلَقۡنَآۚ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّن طِينٖ لَّازِبِۭ

Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn
Surah As-Saaffat, Verse 11


بَلۡ عَجِبۡتَ وَيَسۡخَرُونَ

Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 12


وَإِذَا ذُكِّرُواْ لَا يَذۡكُرُونَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí
Surah As-Saaffat, Verse 13


وَإِذَا رَأَوۡاْ ءَايَةٗ يَسۡتَسۡخِرُونَ

Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 14


وَقَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٌ

Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé
Surah As-Saaffat, Verse 15


أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni
Surah As-Saaffat, Verse 16


أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ

Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́
Surah As-Saaffat, Verse 17


قُلۡ نَعَمۡ وَأَنتُمۡ دَٰخِرُونَ

Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ
Surah As-Saaffat, Verse 18


فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ فَإِذَا هُمۡ يَنظُرُونَ

Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn
Surah As-Saaffat, Verse 19


وَقَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا هَٰذَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ

Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san
Surah As-Saaffat, Verse 20


هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ

Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́
Surah As-Saaffat, Verse 21


۞ٱحۡشُرُواْ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَأَزۡوَٰجَهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَعۡبُدُونَ

Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
Surah As-Saaffat, Verse 22


مِن دُونِ ٱللَّهِ فَٱهۡدُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡجَحِيمِ

lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm
Surah As-Saaffat, Verse 23


وَقِفُوهُمۡۖ إِنَّهُم مَّسۡـُٔولُونَ

Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè
Surah As-Saaffat, Verse 24


مَا لَكُمۡ لَا تَنَاصَرُونَ

Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́
Surah As-Saaffat, Verse 25


بَلۡ هُمُ ٱلۡيَوۡمَ مُسۡتَسۡلِمُونَ

Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni
Surah As-Saaffat, Verse 26


وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè
Surah As-Saaffat, Verse 27


قَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَأۡتُونَنَا عَنِ ٱلۡيَمِينِ

(Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)
Surah As-Saaffat, Verse 28


قَالُواْ بَل لَّمۡ تَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ

(Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
Surah As-Saaffat, Verse 29


وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭۖ بَلۡ كُنتُمۡ قَوۡمٗا طَٰغِينَ

Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà
Surah As-Saaffat, Verse 30


فَحَقَّ عَلَيۡنَا قَوۡلُ رَبِّنَآۖ إِنَّا لَذَآئِقُونَ

Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò
Surah As-Saaffat, Verse 31


فَأَغۡوَيۡنَٰكُمۡ إِنَّا كُنَّا غَٰوِينَ

Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà
Surah As-Saaffat, Verse 32


فَإِنَّهُمۡ يَوۡمَئِذٖ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ

Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà
Surah As-Saaffat, Verse 33


إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 34


إِنَّهُمۡ كَانُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ يَسۡتَكۡبِرُونَ

Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga
Surah As-Saaffat, Verse 35


وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُوٓاْ ءَالِهَتِنَا لِشَاعِرٖ مَّجۡنُونِۭ

Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan
Surah As-Saaffat, Verse 36


بَلۡ جَآءَ بِٱلۡحَقِّ وَصَدَّقَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà
Surah As-Saaffat, Verse 37


إِنَّكُمۡ لَذَآئِقُواْ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَلِيمِ

Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò
Surah As-Saaffat, Verse 38


وَمَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ

A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 39


إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
Surah As-Saaffat, Verse 40


أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ رِزۡقٞ مَّعۡلُومٞ

Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀
Surah As-Saaffat, Verse 41


فَوَٰكِهُ وَهُم مُّكۡرَمُونَ

àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
Surah As-Saaffat, Verse 42


فِي جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ

nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
Surah As-Saaffat, Verse 43


عَلَىٰ سُرُرٖ مُّتَقَٰبِلِينَ

Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn
Surah As-Saaffat, Verse 44


يُطَافُ عَلَيۡهِم بِكَأۡسٖ مِّن مَّعِينِۭ

Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn
Surah As-Saaffat, Verse 45


بَيۡضَآءَ لَذَّةٖ لِّلشَّـٰرِبِينَ

Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún
Surah As-Saaffat, Verse 46


لَا فِيهَا غَوۡلٞ وَلَا هُمۡ عَنۡهَا يُنزَفُونَ

Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 47


وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ عِينٞ

Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn
Surah As-Saaffat, Verse 48


كَأَنَّهُنَّ بَيۡضٞ مَّكۡنُونٞ

Wọ́n dà bí tinú ẹyin. ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run
Surah As-Saaffat, Verse 49


فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè
Surah As-Saaffat, Verse 50


قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٞ

Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
Surah As-Saaffat, Verse 51


يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ

tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde
Surah As-Saaffat, Verse 52


أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
Surah As-Saaffat, Verse 53


قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)
Surah As-Saaffat, Verse 54


فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ

Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm
Surah As-Saaffat, Verse 55


قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ

Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán
Surah As-Saaffat, Verse 56


وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ

Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná
Surah As-Saaffat, Verse 57


أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ

Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí
Surah As-Saaffat, Verse 58


إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ

Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà
Surah As-Saaffat, Verse 59


إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ

Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá
Surah As-Saaffat, Verse 60


لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ

Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ
Surah As-Saaffat, Verse 61


أَذَٰلِكَ خَيۡرٞ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ

Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)
Surah As-Saaffat, Verse 62


إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةٗ لِّلظَّـٰلِمِينَ

Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí
Surah As-Saaffat, Verse 63


إِنَّهَا شَجَرَةٞ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ

Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm
Surah As-Saaffat, Verse 64


طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ

Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù
Surah As-Saaffat, Verse 65


فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ

Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú
Surah As-Saaffat, Verse 66


ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبٗا مِّنۡ حَمِيمٖ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí
Surah As-Saaffat, Verse 67


ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm
Surah As-Saaffat, Verse 68


إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ

Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà
Surah As-Saaffat, Verse 69


فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ

Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn
Surah As-Saaffat, Verse 70


وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ

Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn
Surah As-Saaffat, Verse 71


وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ

Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn
Surah As-Saaffat, Verse 72


فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ

Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí
Surah As-Saaffat, Verse 73


إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
Surah As-Saaffat, Verse 74


وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٞ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ

Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè
Surah As-Saaffat, Verse 75


وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ

A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá
Surah As-Saaffat, Verse 76


وَجَعَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُۥ هُمُ ٱلۡبَاقِينَ

A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 77


وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
Surah As-Saaffat, Verse 78


سَلَٰمٌ عَلَىٰ نُوحٖ فِي ٱلۡعَٰلَمِينَ

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá
Surah As-Saaffat, Verse 79


إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
Surah As-Saaffat, Verse 80


إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah As-Saaffat, Verse 81


ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ

Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami
Surah As-Saaffat, Verse 82


۞وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِۦ لَإِبۡرَٰهِيمَ

Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 83


إِذۡ جَآءَ رَبَّهُۥ بِقَلۡبٖ سَلِيمٍ

(Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́
Surah As-Saaffat, Verse 84


إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَاذَا تَعۡبُدُونَ

(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún
Surah As-Saaffat, Verse 85


أَئِفۡكًا ءَالِهَةٗ دُونَ ٱللَّهِ تُرِيدُونَ

Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu
Surah As-Saaffat, Verse 86


فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
Surah As-Saaffat, Verse 87


فَنَظَرَ نَظۡرَةٗ فِي ٱلنُّجُومِ

Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an
Surah As-Saaffat, Verse 88


فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٞ

Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí
Surah As-Saaffat, Verse 89


فَتَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ مُدۡبِرِينَ

Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ
Surah As-Saaffat, Verse 90


فَرَاغَ إِلَىٰٓ ءَالِهَتِهِمۡ فَقَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ

Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni
Surah As-Saaffat, Verse 91


مَا لَكُمۡ لَا تَنطِقُونَ

Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀
Surah As-Saaffat, Verse 92


فَرَاغَ عَلَيۡهِمۡ ضَرۡبَۢا بِٱلۡيَمِينِ

Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú)
Surah As-Saaffat, Verse 93


فَأَقۡبَلُوٓاْ إِلَيۡهِ يَزِفُّونَ

(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́
Surah As-Saaffat, Verse 94


قَالَ أَتَعۡبُدُونَ مَا تَنۡحِتُونَ

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni
Surah As-Saaffat, Verse 95


وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ

Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 96


قَالُواْ ٱبۡنُواْ لَهُۥ بُنۡيَٰنٗا فَأَلۡقُوهُ فِي ٱلۡجَحِيمِ

Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná
Surah As-Saaffat, Verse 97


فَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدٗا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَسۡفَلِينَ

Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ
Surah As-Saaffat, Verse 98


وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهۡدِينِ

Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀)
Surah As-Saaffat, Verse 99


رَبِّ هَبۡ لِي مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere
Surah As-Saaffat, Verse 100


فَبَشَّرۡنَٰهُ بِغُلَٰمٍ حَلِيمٖ

A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà
Surah As-Saaffat, Verse 101


فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ ٱلسَّعۡيَ قَالَ يَٰبُنَيَّ إِنِّيٓ أَرَىٰ فِي ٱلۡمَنَامِ أَنِّيٓ أَذۡبَحُكَ فَٱنظُرۡ مَاذَا تَرَىٰۚ قَالَ يَـٰٓأَبَتِ ٱفۡعَلۡ مَا تُؤۡمَرُۖ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّـٰبِرِينَ

Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 102


فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ

Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 103


وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَـٰٓإِبۡرَٰهِيمُ

A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm
Surah As-Saaffat, Verse 104


قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
Surah As-Saaffat, Verse 105


إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَـٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ

Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé
Surah As-Saaffat, Verse 106


وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٖ

A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 107


وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
Surah As-Saaffat, Verse 108


سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm
Surah As-Saaffat, Verse 109


كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
Surah As-Saaffat, Verse 110


إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah As-Saaffat, Verse 111


وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere
Surah As-Saaffat, Verse 112


وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ

Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì
Surah As-Saaffat, Verse 113


وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ

Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn
Surah As-Saaffat, Verse 114


وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ

A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá
Surah As-Saaffat, Verse 115


وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ

A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn)
Surah As-Saaffat, Verse 116


وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ

A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú
Surah As-Saaffat, Verse 117


وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ

A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà
Surah As-Saaffat, Verse 118


وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
Surah As-Saaffat, Verse 119


سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn
Surah As-Saaffat, Verse 120


إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
Surah As-Saaffat, Verse 121


إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah As-Saaffat, Verse 122


وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 123


إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ

(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni
Surah As-Saaffat, Verse 124


أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ

Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām 6:62) olùdájọ́ aláàánú ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́ owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú
Surah As-Saaffat, Verse 125


ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ

(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́
Surah As-Saaffat, Verse 126


فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná
Surah As-Saaffat, Verse 127


إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
Surah As-Saaffat, Verse 128


وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn
Surah As-Saaffat, Verse 129


سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās
Surah As-Saaffat, Verse 130


إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)
Surah As-Saaffat, Verse 131


إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah As-Saaffat, Verse 132


وَإِنَّ لُوطٗا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 133


إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là
Surah As-Saaffat, Verse 134


إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ

Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́)
Surah As-Saaffat, Verse 135


ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run
Surah As-Saaffat, Verse 136


وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ

Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
Surah As-Saaffat, Verse 137


وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni
Surah As-Saaffat, Verse 138


وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 139


إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ

(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 140


فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ

Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí
Surah As-Saaffat, Verse 141


فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٞ

Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi
Surah As-Saaffat, Verse 142


فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ

Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu
Surah As-Saaffat, Verse 143


لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ

dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde
Surah As-Saaffat, Verse 144


۞فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٞ

Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera
Surah As-Saaffat, Verse 145


وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةٗ مِّن يَقۡطِينٖ

A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó
Surah As-Saaffat, Verse 146


وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ

A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i
Surah As-Saaffat, Verse 147


فَـَٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ

Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 148


فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ

Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin
Surah As-Saaffat, Verse 149


أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ إِنَٰثٗا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ

Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí
Surah As-Saaffat, Verse 150


أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ

Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé
Surah As-Saaffat, Verse 151


وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ

Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n
Surah As-Saaffat, Verse 152


أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ

Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni
Surah As-Saaffat, Verse 153


مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ

Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí
Surah As-Saaffat, Verse 154


أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
Surah As-Saaffat, Verse 155


أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٞ مُّبِينٞ

Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni
Surah As-Saaffat, Verse 156


فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo
Surah As-Saaffat, Verse 157


وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبٗاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ

Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni
Surah As-Saaffat, Verse 158


سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ

Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)
Surah As-Saaffat, Verse 159


إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
Surah As-Saaffat, Verse 160


فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ

Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu)
Surah As-Saaffat, Verse 161


مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ

ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
Surah As-Saaffat, Verse 162


إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ

àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm
Surah As-Saaffat, Verse 163


وَمَامِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٞ مَّعۡلُومٞ

Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀
Surah As-Saaffat, Verse 164


وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ

Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
Surah As-Saaffat, Verse 165


وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ

Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu)
Surah As-Saaffat, Verse 166


وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ

Wọ́n kúkú ń wí pé
Surah As-Saaffat, Verse 167


لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرٗا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́
Surah As-Saaffat, Verse 168


لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà
Surah As-Saaffat, Verse 169


فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ

Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀
Surah As-Saaffat, Verse 170


وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 171


إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ

Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún
Surah As-Saaffat, Verse 172


وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ

Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí
Surah As-Saaffat, Verse 173


فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀
Surah As-Saaffat, Verse 174


وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò
Surah As-Saaffat, Verse 175


أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú
Surah As-Saaffat, Verse 176


فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ

Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún
Surah As-Saaffat, Verse 177


وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ

Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná
Surah As-Saaffat, Verse 178


وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò
Surah As-Saaffat, Verse 179


سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ

Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)
Surah As-Saaffat, Verse 180


وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
Surah As-Saaffat, Verse 181


وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Surah As-Saaffat, Verse 182


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 36
>> Surah 38

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai