UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Sad - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


صٓۚ وَٱلۡقُرۡءَانِ ذِي ٱلذِّكۡرِ

Sọ̄d. (Allāhu búra pẹ̀lú) al-Ƙur’ān, tírà ìrántí
Surah Sad, Verse 1


بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي عِزَّةٖ وَشِقَاقٖ

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo)
Surah Sad, Verse 2


كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّن قَرۡنٖ فَنَادَواْ وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٖ

Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe tòò nígbà tí kò sí ibùsásí kan
Surah Sad, Verse 3


وَعَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٞ مِّنۡهُمۡۖ وَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا سَٰحِرٞ كَذَّابٌ

Wọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni òpìdán, òpùrọ́
Surah Sad, Verse 4


أَجَعَلَ ٱلۡأٓلِهَةَ إِلَٰهٗا وَٰحِدًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عُجَابٞ

Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí A óò máa jọ́sìn fún ni? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu
Surah Sad, Verse 5


وَٱنطَلَقَ ٱلۡمَلَأُ مِنۡهُمۡ أَنِ ٱمۡشُواْ وَٱصۡبِرُواْ عَلَىٰٓ ءَالِهَتِكُمۡۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٞ يُرَادُ

Àwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káàkiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: "Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbà lérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run)
Surah Sad, Verse 6


مَا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِي ٱلۡمِلَّةِ ٱلۡأٓخِرَةِ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا ٱخۡتِلَٰقٌ

Àwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn kristiẹniti) . Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́
Surah Sad, Verse 7


أَءُنزِلَ عَلَيۡهِ ٱلذِّكۡرُ مِنۢ بَيۡنِنَاۚ بَلۡ هُمۡ فِي شَكّٖ مِّن ذِكۡرِيۚ بَل لَّمَّا يَذُوقُواْ عَذَابِ

Ṣé Wọ́n sọ Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?" Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni
Surah Sad, Verse 8


أَمۡ عِندَهُمۡ خَزَآئِنُ رَحۡمَةِ رَبِّكَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡوَهَّابِ

Tàbí (ṣé) àwọn ni wọ́n ni àwọn àpótí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ
Surah Sad, Verse 9


أَمۡ لَهُم مُّلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۖ فَلۡيَرۡتَقُواْ فِي ٱلۡأَسۡبَٰبِ

Tàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa)
Surah Sad, Verse 10


جُندٞ مَّا هُنَالِكَ مَهۡزُومٞ مِّنَ ٱلۡأَحۡزَابِ

A máa ṣẹ́gun ọmọ ogun t’ó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ
Surah Sad, Verse 11


كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَعَادٞ وَفِرۡعَوۡنُ ذُو ٱلۡأَوۡتَادِ

Àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn
Surah Sad, Verse 12


وَثَمُودُ وَقَوۡمُ لُوطٖ وَأَصۡحَٰبُ لۡـَٔيۡكَةِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلۡأَحۡزَابُ

Ìjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará ’Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (t’ó pe òdodo nírọ́)
Surah Sad, Verse 13


إِن كُلٌّ إِلَّا كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ عِقَابِ

Kò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí
Surah Sad, Verse 14


وَمَا يَنظُرُ هَـٰٓؤُلَآءِ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ مَّا لَهَا مِن فَوَاقٖ

Àwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan, tí kò níí sí ìdápadà (tàbí ìdádúró) kan fún un (t’ó bá dé)
Surah Sad, Verse 15


وَقَالُواْ رَبَّنَا عَجِّل لَّنَا قِطَّنَا قَبۡلَ يَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ

Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
Surah Sad, Verse 16


ٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱذۡكُرۡ عَبۡدَنَا دَاوُۥدَ ذَا ٱلۡأَيۡدِۖ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ

Ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà
Surah Sad, Verse 17


إِنَّا سَخَّرۡنَا ٱلۡجِبَالَ مَعَهُۥ يُسَبِّحۡنَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِشۡرَاقِ

Dájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní àṣálẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ
Surah Sad, Verse 18


وَٱلطَّيۡرَ مَحۡشُورَةٗۖ كُلّٞ لَّهُۥٓ أَوَّابٞ

Àti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu)
Surah Sad, Verse 19


وَشَدَدۡنَا مُلۡكَهُۥ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحِكۡمَةَ وَفَصۡلَ ٱلۡخِطَابِ

Àti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́
Surah Sad, Verse 20


۞وَهَلۡ أَتَىٰكَ نَبَؤُاْ ٱلۡخَصۡمِ إِذۡ تَسَوَّرُواْ ٱلۡمِحۡرَابَ

Ǹjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn
Surah Sad, Verse 21


إِذۡ دَخَلُواْ عَلَىٰ دَاوُۥدَ فَفَزِعَ مِنۡهُمۡۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ خَصۡمَانِ بَغَىٰ بَعۡضُنَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فَٱحۡكُم بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَلَا تُشۡطِطۡ وَٱهۡدِنَآ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلصِّرَٰطِ

Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù bà á láti ara wọn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-àlà sí apá kan. Nítorí náà, dájọ́ láààrin wa pẹ̀lú òdodo. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà
Surah Sad, Verse 22


إِنَّ هَٰذَآ أَخِي لَهُۥ تِسۡعٞ وَتِسۡعُونَ نَعۡجَةٗ وَلِيَ نَعۡجَةٞ وَٰحِدَةٞ فَقَالَ أَكۡفِلۡنِيهَا وَعَزَّنِي فِي ٱلۡخِطَابِ

Dájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: "Fà á lé mi lọ́wọ́. Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀
Surah Sad, Verse 23


قَالَ لَقَدۡ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعۡجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦۖ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٞ مَّا هُمۡۗ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّـٰهُ فَٱسۡتَغۡفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّۤ رَاكِعٗاۤ وَأَنَابَ۩

(Ànábì Dāwūd) sọ pé: "Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-àlà lórí apá kan àfi àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n. (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni- afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu). òǹkà ìyàwó wọn lè pọ̀ ní òǹkà kì í ṣe ní ti ìgbádùn adùn-ara bí kò ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹ̀kọ́ ìgbẹ́jọ́ nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ fi ṣe adájọ́ láààrin àwọn ìjọ rẹ̀. Àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn ni àṣíṣe t’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí náà sì ni ohun tí ó tọrọ àforíjìn Ọlọ́hun fún
Surah Sad, Verse 24


فَغَفَرۡنَا لَهُۥ ذَٰلِكَۖ وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلۡفَىٰ وَحُسۡنَ مَـَٔابٖ

Nítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa
Surah Sad, Verse 25


يَٰدَاوُۥدُ إِنَّا جَعَلۡنَٰكَ خَلِيفَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱحۡكُم بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّ وَلَا تَتَّبِعِ ٱلۡهَوَىٰ فَيُضِلَّكَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَضِلُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدُۢ بِمَا نَسُواْ يَوۡمَ ٱلۡحِسَابِ

(Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, dájọ́ láààrin àwọn ènìyà́n pẹ̀lú òdodo. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
Surah Sad, Verse 26


وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَآءَ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا بَٰطِلٗاۚ ذَٰلِكَ ظَنُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنَ ٱلنَّارِ

A kò ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì pẹ̀lú irọ́. (Irọ́), ìyẹn ni èrò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná
Surah Sad, Verse 27


أَمۡ نَجۡعَلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ كَٱلۡمُفۡسِدِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ نَجۡعَلُ ٱلۡمُتَّقِينَ كَٱلۡفُجَّارِ

Ṣé kí Á ṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi
Surah Sad, Verse 28


كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ إِلَيۡكَ مُبَٰرَكٞ لِّيَدَّبَّرُوٓاْ ءَايَٰتِهِۦ وَلِيَتَذَكَّرَ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ

(Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀ kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí
Surah Sad, Verse 29


وَوَهَبۡنَا لِدَاوُۥدَ سُلَيۡمَٰنَۚ نِعۡمَ ٱلۡعَبۡدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ

A fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà)
Surah Sad, Verse 30


إِذۡ عُرِضَ عَلَيۡهِ بِٱلۡعَشِيِّ ٱلصَّـٰفِنَٰتُ ٱلۡجِيَادُ

(Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́
Surah Sad, Verse 31


فَقَالَ إِنِّيٓ أَحۡبَبۡتُ حُبَّ ٱلۡخَيۡرِ عَن ذِكۡرِ رَبِّي حَتَّىٰ تَوَارَتۡ بِٱلۡحِجَابِ

ó sọ pé: "Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀
Surah Sad, Verse 32


رُدُّوهَا عَلَيَّۖ فَطَفِقَ مَسۡحَۢا بِٱلسُّوقِ وَٱلۡأَعۡنَاقِ

Ẹ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi. "Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn
Surah Sad, Verse 33


وَلَقَدۡ فَتَنَّا سُلَيۡمَٰنَ وَأَلۡقَيۡنَا عَلَىٰ كُرۡسِيِّهِۦ جَسَدٗا ثُمَّ أَنَابَ

Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ìyàwó t’ó tó ọgọ́rùn-ún lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ (ìyẹn ni pé Allāhu s.w.t. l’Ó ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún un). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì fi Allāhu búra ní ọjọ́ kan pé kì í ṣe ara òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àwọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n wà. Báwo wá ni ó ṣe máa jẹ́ pé nípasẹ̀ òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ni àwọ̀ rẹ̀ fi máa kúrò lára rẹ̀ sí ara èṣù àlùjànnú nígbà tí Ànábì Sulaemọ̄n kì í ṣe òpìdán? Ànábì Sulaemọ̄n kò sì fi òrùka jọba áḿbọ̀sìbọ́sí pé nígbà tí kò bá sí òrùka rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ l’ó máa fún ẹlòmíìràn ní àyè láti di ọba! Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:102. W-Allāhu ’a‘lam
Surah Sad, Verse 34


قَالَ رَبِّ ٱغۡفِرۡ لِي وَهَبۡ لِي مُلۡكٗا لَّا يَنۢبَغِي لِأَحَدٖ مِّنۢ بَعۡدِيٓۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡوَهَّابُ

Ó sọ pé: "Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ
Surah Sad, Verse 35


فَسَخَّرۡنَا لَهُ ٱلرِّيحَ تَجۡرِي بِأَمۡرِهِۦ رُخَآءً حَيۡثُ أَصَابَ

Nítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́
Surah Sad, Verse 36


وَٱلشَّيَٰطِينَ كُلَّ بَنَّآءٖ وَغَوَّاصٖ

Àti àwọn èṣù àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un)
Surah Sad, Verse 37


وَءَاخَرِينَ مُقَرَّنِينَ فِي ٱلۡأَصۡفَادِ

Àti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un)
Surah Sad, Verse 38


هَٰذَا عَطَآؤُنَا فَٱمۡنُنۡ أَوۡ أَمۡسِكۡ بِغَيۡرِ حِسَابٖ

Èyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání láì la ìṣírò lọ (lọ́run)
Surah Sad, Verse 39


وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلۡفَىٰ وَحُسۡنَ مَـَٔابٖ

Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa
Surah Sad, Verse 40


وَٱذۡكُرۡ عَبۡدَنَآ أَيُّوبَ إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَسَّنِيَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بِنُصۡبٖ وَعَذَابٍ

Ṣèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): "Dájúdájú Èṣù ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi
Surah Sad, Verse 41


ٱرۡكُضۡ بِرِجۡلِكَۖ هَٰذَا مُغۡتَسَلُۢ بَارِدٞ وَشَرَابٞ

(Mọlāika sọ fún un pé): "Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ)
Surah Sad, Verse 42


وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ أَهۡلَهُۥ وَمِثۡلَهُم مَّعَهُمۡ رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ

A sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè
Surah Sad, Verse 43


وَخُذۡ بِيَدِكَ ضِغۡثٗا فَٱضۡرِب بِّهِۦ وَلَا تَحۡنَثۡۗ إِنَّا وَجَدۡنَٰهُ صَابِرٗاۚ نِّعۡمَ ٱلۡعَبۡدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٞ

Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ. Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà)
Surah Sad, Verse 44


وَٱذۡكُرۡ عِبَٰدَنَآ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ أُوْلِي ٱلۡأَيۡدِي وَٱلۡأَبۡصَٰرِ

Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára, olùríran (nípa ẹ̀sìn)
Surah Sad, Verse 45


إِنَّآ أَخۡلَصۡنَٰهُم بِخَالِصَةٖ ذِكۡرَى ٱلدَّارِ

Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan; ìrántí Ilé Ìkẹ́yìn
Surah Sad, Verse 46


وَإِنَّهُمۡ عِندَنَا لَمِنَ ٱلۡمُصۡطَفَيۡنَ ٱلۡأَخۡيَارِ

Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa
Surah Sad, Verse 47


وَٱذۡكُرۡ إِسۡمَٰعِيلَ وَٱلۡيَسَعَ وَذَا ٱلۡكِفۡلِۖ وَكُلّٞ مِّنَ ٱلۡأَخۡيَارِ

Ṣèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ
Surah Sad, Verse 48


هَٰذَا ذِكۡرٞۚ وَإِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ لَحُسۡنَ مَـَٔابٖ

Èyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Sad, Verse 49


جَنَّـٰتِ عَدۡنٖ مُّفَتَّحَةٗ لَّهُمُ ٱلۡأَبۡوَٰبُ

Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn
Surah Sad, Verse 50


مُتَّكِـِٔينَ فِيهَا يَدۡعُونَ فِيهَا بِفَٰكِهَةٖ كَثِيرَةٖ وَشَرَابٖ

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀
Surah Sad, Verse 51


۞وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ أَتۡرَابٌ

Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn
Surah Sad, Verse 52


هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ

Èyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́
Surah Sad, Verse 53


إِنَّ هَٰذَا لَرِزۡقُنَا مَا لَهُۥ مِن نَّفَادٍ

Dájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán
Surah Sad, Verse 54


هَٰذَاۚ وَإِنَّ لِلطَّـٰغِينَ لَشَرَّ مَـَٔابٖ

Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu)
Surah Sad, Verse 55


جَهَنَّمَ يَصۡلَوۡنَهَا فَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ

Iná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé
Surah Sad, Verse 56


هَٰذَا فَلۡيَذُوقُوهُ حَمِيمٞ وَغَسَّاقٞ

Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀
Surah Sad, Verse 57


وَءَاخَرُ مِن شَكۡلِهِۦٓ أَزۡوَٰجٌ

Oríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn)
Surah Sad, Verse 58


هَٰذَا فَوۡجٞ مُّقۡتَحِمٞ مَّعَكُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِهِمۡۚ إِنَّهُمۡ صَالُواْ ٱلنَّارِ

Èyí ni ìjọ kan t’ó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) "Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn." Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni
Surah Sad, Verse 59


قَالُواْ بَلۡ أَنتُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِكُمۡۖ أَنتُمۡ قَدَّمۡتُمُوهُ لَنَاۖ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرَارُ

(Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: "Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fun yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (t’ó bí Iná)." Ó sì burú ní ibùgbé
Surah Sad, Verse 60


قَالُواْ رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدۡهُ عَذَابٗا ضِعۡفٗا فِي ٱلنَّارِ

Wọ́n (tún) wí pé: "Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná
Surah Sad, Verse 61


وَقَالُواْ مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالٗا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ ٱلۡأَشۡرَارِ

Wọ́n tún wí pé: "Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a ò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú
Surah Sad, Verse 62


أَتَّخَذۡنَٰهُمۡ سِخۡرِيًّا أَمۡ زَاغَتۡ عَنۡهُمُ ٱلۡأَبۡصَٰرُ

Ṣèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)
Surah Sad, Verse 63


إِنَّ ذَٰلِكَ لَحَقّٞ تَخَاصُمُ أَهۡلِ ٱلنَّارِ

Dájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni
Surah Sad, Verse 64


قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ مُنذِرٞۖ وَمَا مِنۡ إِلَٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ

Sọ pé: "Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí
Surah Sad, Verse 65


رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّـٰرُ

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn
Surah Sad, Verse 66


قُلۡ هُوَ نَبَؤٌاْ عَظِيمٌ

Sọ pé: "(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá
Surah Sad, Verse 67


أَنتُمۡ عَنۡهُ مُعۡرِضُونَ

Ẹ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀
Surah Sad, Verse 68


مَا كَانَ لِيَ مِنۡ عِلۡمِۭ بِٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰٓ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ

Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé
Surah Sad, Verse 69


إِن يُوحَىٰٓ إِلَيَّ إِلَّآ أَنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٌ

Kí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé
Surah Sad, Verse 70


إِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن طِينٖ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: "Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrùpẹ̀
Surah Sad, Verse 71


فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ

Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni
Surah Sad, Verse 72


فَسَجَدَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ

Gbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i
Surah Sad, Verse 73


إِلَّآ إِبۡلِيسَ ٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Àyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Sad, Verse 74


قَالَ يَـٰٓإِبۡلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسۡجُدَ لِمَا خَلَقۡتُ بِيَدَيَّۖ أَسۡتَكۡبَرۡتَ أَمۡ كُنتَ مِنَ ٱلۡعَالِينَ

(Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga
Surah Sad, Verse 75


قَالَ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡهُ خَلَقۡتَنِي مِن نَّارٖ وَخَلَقۡتَهُۥ مِن طِينٖ

Ó wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀
Surah Sad, Verse 76


قَالَ فَٱخۡرُجۡ مِنۡهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٞ

(Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀
Surah Sad, Verse 77


وَإِنَّ عَلَيۡكَ لَعۡنَتِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلدِّينِ

Àti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san
Surah Sad, Verse 78


قَالَ رَبِّ فَأَنظِرۡنِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ

(Èṣù) wí pé: "Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde
Surah Sad, Verse 79


قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلۡمُنظَرِينَ

(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára
Surah Sad, Verse 80


إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡوَقۡتِ ٱلۡمَعۡلُومِ

títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ
Surah Sad, Verse 81


قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغۡوِيَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ

(Èṣù) wí pé: "Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà
Surah Sad, Verse 82


إِلَّا عِبَادَكَ مِنۡهُمُ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn
Surah Sad, Verse 83


قَالَ فَٱلۡحَقُّ وَٱلۡحَقَّ أَقُولُ

(Allāhu) sọ pé: "Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)
Surah Sad, Verse 84


لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ أَجۡمَعِينَ

dájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ
Surah Sad, Verse 85


قُلۡ مَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُتَكَلِّفِينَ

Sọ pé: "Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ
Surah Sad, Verse 86


إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ

Kí ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá
Surah Sad, Verse 87


وَلَتَعۡلَمُنَّ نَبَأَهُۥ بَعۡدَ حِينِۭ

Àti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́
Surah Sad, Verse 88


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 37
>> Surah 39

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai