Surah Sad - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
صٓۚ وَٱلۡقُرۡءَانِ ذِي ٱلذِّكۡرِ
Sod. (Allahu bura pelu) al-Ƙur’an, tira iranti
Surah Sad, Verse 1
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي عِزَّةٖ وَشِقَاقٖ
Sibesibe awon t’o sai gbagbo wa ninu igberaga ati iyapa (ododo)
Surah Sad, Verse 2
كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّن قَرۡنٖ فَنَادَواْ وَّلَاتَ حِينَ مَنَاصٖ
Meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Nigba naa, won kigbe too nigba ti ko si ibusasi kan
Surah Sad, Verse 3
وَعَجِبُوٓاْ أَن جَآءَهُم مُّنذِرٞ مِّنۡهُمۡۖ وَقَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا سَٰحِرٞ كَذَّابٌ
Won seemo pe olukilo kan ninu won wa ba won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni opidan, opuro
Surah Sad, Verse 4
أَجَعَلَ ٱلۡأٓلِهَةَ إِلَٰهٗا وَٰحِدًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عُجَابٞ
Se o maa so awon orisa di Olohun Okan soso ti A oo maa josin fun ni? Dajudaju eyi ma ni nnkan iyanu
Surah Sad, Verse 5
وَٱنطَلَقَ ٱلۡمَلَأُ مِنۡهُمۡ أَنِ ٱمۡشُواْ وَٱصۡبِرُواْ عَلَىٰٓ ءَالِهَتِكُمۡۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٞ يُرَادُ
Awon asiwaju ninu won si lo (kaakiri lati wi fun awon omoleyin won) pe: "E maa ba (iborisa) lo, ki e si duro sinsin ti awon orisa yin. Dajudaju eyi (jije okan soso Allahu) ni nnkan ti won n gba lero (lati fi pa awon orisa yin run)
Surah Sad, Verse 6
مَا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِي ٱلۡمِلَّةِ ٱلۡأٓخِرَةِ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا ٱخۡتِلَٰقٌ
Awa ko gbo eyi ninu esin ikeyin (iyen, esin kristieniti) . Eyi ko je kini kan bi ko se adapa iro
Surah Sad, Verse 7
أَءُنزِلَ عَلَيۡهِ ٱلذِّكۡرُ مِنۢ بَيۡنِنَاۚ بَلۡ هُمۡ فِي شَكّٖ مِّن ذِكۡرِيۚ بَل لَّمَّا يَذُوقُواْ عَذَابِ
Se Won so Iranti kale fun un laaarin wa ni?" Rara, won wa ninu iyemeji nipa Iranti Mi (ti Mo sokale ni). Rara, won ko ti i to iya Mi wo ni
Surah Sad, Verse 8
أَمۡ عِندَهُمۡ خَزَآئِنُ رَحۡمَةِ رَبِّكَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡوَهَّابِ
Tabi (se) awon ni won ni awon apoti oro Oluwa re, Alagbara, Olore
Surah Sad, Verse 9
أَمۡ لَهُم مُّلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۖ فَلۡيَرۡتَقُواْ فِي ٱلۡأَسۡبَٰبِ
Tabi tiwon ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin mejeeji? Ti o ba ri bee, ki won wa awon ona lati fi gunke wa (ba Wa)
Surah Sad, Verse 10
جُندٞ مَّا هُنَالِكَ مَهۡزُومٞ مِّنَ ٱلۡأَحۡزَابِ
A maa segun omo ogun t’o wa nibe yen ninu omo ogun onijo
Surah Sad, Verse 11
كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَعَادٞ وَفِرۡعَوۡنُ ذُو ٱلۡأَوۡتَادِ
Awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati Fir‘aon, eleekan, won pe ododo niro siwaju won
Surah Sad, Verse 12
وَثَمُودُ وَقَوۡمُ لُوطٖ وَأَصۡحَٰبُ لۡـَٔيۡكَةِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلۡأَحۡزَابُ
Ijo Thamud, ijo Lut ati awon ara ’Aekah, awon wonyen (tun ni) awon ijo (t’o pe ododo niro)
Surah Sad, Verse 13
إِن كُلٌّ إِلَّا كَذَّبَ ٱلرُّسُلَ فَحَقَّ عِقَابِ
Ko si eni kan ninu won ti ko pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, iya Mi si ko le won lori
Surah Sad, Verse 14
وَمَا يَنظُرُ هَـٰٓؤُلَآءِ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ مَّا لَهَا مِن فَوَاقٖ
Awon wonyi ko reti kini kan tayo igbe eyo kan, ti ko nii si idapada (tabi idaduro) kan fun un (t’o ba de)
Surah Sad, Verse 15
وَقَالُواْ رَبَّنَا عَجِّل لَّنَا قِطَّنَا قَبۡلَ يَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ
Won wi pe: "Oluwa wa, yara fi iwe ise wa (ati esan wa) le wa lowo siwaju Ojo isiro-ise
Surah Sad, Verse 16
ٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَٱذۡكُرۡ عَبۡدَنَا دَاوُۥدَ ذَا ٱلۡأَيۡدِۖ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ
Se suuru lori nnkan ti won n so. Ki o si seranti itan erusin Wa, (Anabi) Dawud, alagbara. Dajudaju o je oluronupiwada
Surah Sad, Verse 17
إِنَّا سَخَّرۡنَا ٱلۡجِبَالَ مَعَهُۥ يُسَبِّحۡنَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِشۡرَاقِ
Dajudaju Awa te awon apata lori ba ti won n se afomo pelu re (fun Allahu) ni asale ati nigba ti oorun ba yo
Surah Sad, Verse 18
وَٱلطَّيۡرَ مَحۡشُورَةٗۖ كُلّٞ لَّهُۥٓ أَوَّابٞ
Ati awon eye naa, A ko won jo fun un. Ikookan (won) n tele ase re (lati safomo fun Allahu)
Surah Sad, Verse 19
وَشَدَدۡنَا مُلۡكَهُۥ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحِكۡمَةَ وَفَصۡلَ ٱلۡخِطَابِ
Ati pe A fun ijoba re ni agbara. A si fun un ni ipo Anabi ati eko oro ati idajo
Surah Sad, Verse 20
۞وَهَلۡ أَتَىٰكَ نَبَؤُاْ ٱلۡخَصۡمِ إِذۡ تَسَوَّرُواْ ٱلۡمِحۡرَابَ
Nje iro awon onija ti de odo re; nigba ti won pon ogiri ile ijosin
Surah Sad, Verse 21
إِذۡ دَخَلُواْ عَلَىٰ دَاوُۥدَ فَفَزِعَ مِنۡهُمۡۖ قَالُواْ لَا تَخَفۡۖ خَصۡمَانِ بَغَىٰ بَعۡضُنَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فَٱحۡكُم بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَلَا تُشۡطِطۡ وَٱهۡدِنَآ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلصِّرَٰطِ
Nigba ti won wole to (Anabi) Dawud, eru ba a lati ara won. Won so pe: "Ma se beru. Onija meji (ni wa). Apa kan wa tayo enu-ala si apa kan. Nitori naa, dajo laaarin wa pelu ododo. Ma sabosi. Ki o si to wa si ona taara
Surah Sad, Verse 22
إِنَّ هَٰذَآ أَخِي لَهُۥ تِسۡعٞ وَتِسۡعُونَ نَعۡجَةٗ وَلِيَ نَعۡجَةٞ وَٰحِدَةٞ فَقَالَ أَكۡفِلۡنِيهَا وَعَزَّنِي فِي ٱلۡخِطَابِ
Dajudaju eyi ni arakunrin mi. O ni abo ewure mokandin-logorun-un. Emi si ni abo ewure eyo kan. O si so pe: "Fa a le mi lowo. O si bori mi ninu oro
Surah Sad, Verse 23
قَالَ لَقَدۡ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعۡجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦۖ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٞ مَّا هُمۡۗ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّـٰهُ فَٱسۡتَغۡفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّۤ رَاكِعٗاۤ وَأَنَابَ۩
(Anabi Dawud) so pe: "O ti sabosi si o nipa bibeere abo ewure tire mo awon abo ewure tire. Dajudaju opolopo ninu awon olubada-nnkanpo, apa kan won maa n tayo enu-ala lori apa kan afi awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Die si ni won. (Anabi) Dawud si mo daju pe A kan fi (ibeere naa) sadanwo fun oun ni. Nitori naa, o toro aforijin lodo Oluwa re (nipa aiteti gbo oro lenu eni- afesunkan). O doju bole lati fori kanle. O si ronu piwada (sodo Allahu). onka iyawo won le po ni onka ki i se ni ti igbadun adun-ara bi ko se pe Allahu (subhanahu wa ta'ala) fe ko Anabi Dawud ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni eko igbejo nitori pe Allahu (subhanahu wa ta'ala) fe fi se adajo laaarin awon ijo re. Aiteti gbo oro lenu eni-afesunkan ni asise t’o sele si Anabi Dawud ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Eyi naa si ni ohun ti o toro aforijin Olohun fun
Surah Sad, Verse 24
فَغَفَرۡنَا لَهُۥ ذَٰلِكَۖ وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلۡفَىٰ وَحُسۡنَ مَـَٔابٖ
Nitori naa, A saforijin iyen fun un. Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un lodo Wa
Surah Sad, Verse 25
يَٰدَاوُۥدُ إِنَّا جَعَلۡنَٰكَ خَلِيفَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱحۡكُم بَيۡنَ ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّ وَلَا تَتَّبِعِ ٱلۡهَوَىٰ فَيُضِلَّكَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَضِلُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدُۢ بِمَا نَسُواْ يَوۡمَ ٱلۡحِسَابِ
(Anabi) Dawud, dajudaju Awa se o ni arole lori ile. Nitori naa, dajo laaarin awon eniyan pelu ododo. Ma se tele ife-inu nitori ki o ma baa sina kuro loju ona (esin) Allahu. Dajudaju awon t’o n sonu kuro ninu esin Allahu, iya lile wa fun won nitori pe won gbagbe Ojo isiro-ise
Surah Sad, Verse 26
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَآءَ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا بَٰطِلٗاۚ ذَٰلِكَ ظَنُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنَ ٱلنَّارِ
A ko seda sanmo, ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji pelu iro. (Iro), iyen ni ero awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ninu Ina
Surah Sad, Verse 27
أَمۡ نَجۡعَلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ كَٱلۡمُفۡسِدِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ نَجۡعَلُ ٱلۡمُتَّقِينَ كَٱلۡفُجَّارِ
Se ki A se awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere bi (A o ti se) awon obileje lori ile? Tabi se ki A se awon oluberu (Mi bi A o ti se) awon asebi
Surah Sad, Verse 28
كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ إِلَيۡكَ مُبَٰرَكٞ لِّيَدَّبَّرُوٓاْ ءَايَٰتِهِۦ وَلِيَتَذَكَّرَ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
(Eyi ni) Tira ibukun ti A so kale fun o nitori ki won le ronu jinle nipa awon ayah re ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti
Surah Sad, Verse 29
وَوَهَبۡنَا لِدَاوُۥدَ سُلَيۡمَٰنَۚ نِعۡمَ ٱلۡعَبۡدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٌ
A fi (Anabi) Sulaemon ta (Anabi) Dawud lore. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri sodo (Allahu) ni (nipa ironupiwada)
Surah Sad, Verse 30
إِذۡ عُرِضَ عَلَيۡهِ بِٱلۡعَشِيِّ ٱلصَّـٰفِنَٰتُ ٱلۡجِيَادُ
(Ranti) nigba ti won ko awon esin akawooja-leri asaretete wa ba a ni irole
Surah Sad, Verse 31
فَقَالَ إِنِّيٓ أَحۡبَبۡتُ حُبَّ ٱلۡخَيۡرِ عَن ذِكۡرِ رَبِّي حَتَّىٰ تَوَارَتۡ بِٱلۡحِجَابِ
o so pe: "Dajudaju emi feran ife ohun rere (iyen, awon esin naa) dipo iranti Oluwa Mi (iyen, irun ‘Asr) titi oorun fi wo
Surah Sad, Verse 32
رُدُّوهَا عَلَيَّۖ فَطَفِقَ مَسۡحَۢا بِٱلسُّوقِ وَٱلۡأَعۡنَاقِ
E da won pada sodo mi. "O si bere si i fi ida ge won ni ese ati ni orun
Surah Sad, Verse 33
وَلَقَدۡ فَتَنَّا سُلَيۡمَٰنَ وَأَلۡقَيۡنَا عَلَىٰ كُرۡسِيِّهِۦ جَسَدٗا ثُمَّ أَنَابَ
Dajudaju A dan (Anabi) Sulaemon wo. A ju abara kan sori aga re. Leyin naa, (Anabi Sulaemon) seri pada (pelu ironupiwada). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni iyawo t’o to ogorun-un labe ofin eto (iyen ni pe Allahu s.w.t. l’O se e ni eto fun un). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) si fi Allahu bura ni ojo kan pe ki i se ara oruka Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni awo Anabi Sulaemon wa. Bawo wa ni o se maa je pe nipase oruka Anabi Sulaemon ni awo re fi maa kuro lara re si ara esu alujannu nigba ti Anabi Sulaemon ki i se opidan? Anabi Sulaemon ko si fi oruka joba ambosibosi pe nigba ti ko ba si oruka re lowo re l’o maa fun elomiiran ni aye lati di oba! E tun wo itose-oro fun surah al-Baƙorah; 2:102. W-Allahu ’a‘lam
Surah Sad, Verse 34
قَالَ رَبِّ ٱغۡفِرۡ لِي وَهَبۡ لِي مُلۡكٗا لَّا يَنۢبَغِي لِأَحَدٖ مِّنۢ بَعۡدِيٓۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡوَهَّابُ
O so pe: "Oluwa mi, fori jin mi. Ki O si ta mi ni ore ijoba kan eyi ti ko nii to si eni kan kan mo leyin mi. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olore
Surah Sad, Verse 35
فَسَخَّرۡنَا لَهُ ٱلرِّيحَ تَجۡرِي بِأَمۡرِهِۦ رُخَآءً حَيۡثُ أَصَابَ
Nitori naa, A te ategun ba fun un. O n fe pelu ase re ni irorun sibi ti o ba fe
Surah Sad, Verse 36
وَٱلشَّيَٰطِينَ كُلَّ بَنَّآءٖ وَغَوَّاصٖ
Ati awon esu alujannu; gbogbo awon omole ati awon awakusa (ni A te ba fun un)
Surah Sad, Verse 37
وَءَاخَرِينَ مُقَرَّنِينَ فِي ٱلۡأَصۡفَادِ
Ati awon (alujannu) miiran ti won fi ewon de mole (A te won ba fun un)
Surah Sad, Verse 38
هَٰذَا عَطَآؤُنَا فَٱمۡنُنۡ أَوۡ أَمۡسِكۡ بِغَيۡرِ حِسَابٖ
Eyi ni ore Wa. Nitori naa, fi tore tabi ki o mu un dani lai la isiro lo (lorun)
Surah Sad, Verse 39
وَإِنَّ لَهُۥ عِندَنَا لَزُلۡفَىٰ وَحُسۡنَ مَـَٔابٖ
Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un ni odo Wa
Surah Sad, Verse 40
وَٱذۡكُرۡ عَبۡدَنَآ أَيُّوبَ إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَسَّنِيَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بِنُصۡبٖ وَعَذَابٍ
Seranti erusin Wa, (Anabi) ’Ayyub. Nigba ti o pe Oluwa re (pe): "Dajudaju Esu ti ko inira (aisan) ati iya ba mi
Surah Sad, Verse 41
ٱرۡكُضۡ بِرِجۡلِكَۖ هَٰذَا مُغۡتَسَلُۢ بَارِدٞ وَشَرَابٞ
(Molaika so fun un pe): "Fi ese re janle. Eyi ni omi iwe tutu ati omi mimu (fun iwosan re)
Surah Sad, Verse 42
وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ أَهۡلَهُۥ وَمِثۡلَهُم مَّعَهُمۡ رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
A si ta a lore awon ara ile re (pada) ati iru won pelu won. (O je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon onilaakaye
Surah Sad, Verse 43
وَخُذۡ بِيَدِكَ ضِغۡثٗا فَٱضۡرِب بِّهِۦ وَلَا تَحۡنَثۡۗ إِنَّا وَجَدۡنَٰهُ صَابِرٗاۚ نِّعۡمَ ٱلۡعَبۡدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٞ
Fi owo re mu idi igi koriko tutu ki o fi lu (iyawo) re. Ma se yapa ibura re. Dajudaju Awa ri (’Ayyub) ni onisuuru. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri si odo Allahu ni (nipa ironupiwada)
Surah Sad, Verse 44
وَٱذۡكُرۡ عِبَٰدَنَآ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ أُوْلِي ٱلۡأَيۡدِي وَٱلۡأَبۡصَٰرِ
Seranti awon erusin Wa, (Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub; awon alagbara, oluriran (nipa esin)
Surah Sad, Verse 45
إِنَّآ أَخۡلَصۡنَٰهُم بِخَالِصَةٖ ذِكۡرَى ٱلدَّارِ
Dajudaju Awa sa won lesa pelu esa kan; iranti Ile Ikeyin
Surah Sad, Verse 46
وَإِنَّهُمۡ عِندَنَا لَمِنَ ٱلۡمُصۡطَفَيۡنَ ٱلۡأَخۡيَارِ
Dajudaju won wa ninu awon eni esa, eni rere julo ni odo Wa
Surah Sad, Verse 47
وَٱذۡكُرۡ إِسۡمَٰعِيلَ وَٱلۡيَسَعَ وَذَا ٱلۡكِفۡلِۖ وَكُلّٞ مِّنَ ٱلۡأَخۡيَارِ
Seranti (awon Anabi) ’Ismo‘il, al-Yasa‘ ati Thul-Kifl. Ikookan won wa ninu awon eni rere julo
Surah Sad, Verse 48
هَٰذَا ذِكۡرٞۚ وَإِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ لَحُسۡنَ مَـَٔابٖ
Eyi ni iranti. Ati pe dajudaju abo rere wa fun awon oluberu (Allahu)
Surah Sad, Verse 49
جَنَّـٰتِ عَدۡنٖ مُّفَتَّحَةٗ لَّهُمُ ٱلۡأَبۡوَٰبُ
Awon Ogba Idera gbere (ni). Won si maa si awon ilekun re sile fun won
Surah Sad, Verse 50
مُتَّكِـِٔينَ فِيهَا يَدۡعُونَ فِيهَا بِفَٰكِهَةٖ كَثِيرَةٖ وَشَرَابٖ
Won yoo rogboku ninu re. Won yoo maa beere fun awon eso pupo ati ohun mimu ninu re
Surah Sad, Verse 51
۞وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ أَتۡرَابٌ
Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, ti ojo ori won ko jura won lo yo si wa ni odo won
Surah Sad, Verse 52
هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ
Eyi ni ohun ti Won n se ni adehun fun yin fun Ojo isiro-ise
Surah Sad, Verse 53
إِنَّ هَٰذَا لَرِزۡقُنَا مَا لَهُۥ مِن نَّفَادٍ
Dajudaju eyi ni arisiki Wa. Ko si nii tan
Surah Sad, Verse 54
هَٰذَاۚ وَإِنَّ لِلطَّـٰغِينَ لَشَرَّ مَـَٔابٖ
Eyi (ri bee). Ati pe dajudaju abo buruku ni ti awon alagbeere (si Allahu)
Surah Sad, Verse 55
جَهَنَّمَ يَصۡلَوۡنَهَا فَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ
Ina Jahanamo ni won yo wo. O si buru ni ibugbe
Surah Sad, Verse 56
هَٰذَا فَلۡيَذُوقُوهُ حَمِيمٞ وَغَسَّاقٞ
Eyi (ri bee). Nitori naa, ki won to o wo; omi gbigbona ati awoyunweje
Surah Sad, Verse 57
وَءَاخَرُ مِن شَكۡلِهِۦٓ أَزۡوَٰجٌ
Orisirisi (iya) miiran bi iru re (tun wa fun won)
Surah Sad, Verse 58
هَٰذَا فَوۡجٞ مُّقۡتَحِمٞ مَّعَكُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِهِمۡۚ إِنَّهُمۡ صَالُواْ ٱلنَّارِ
Eyi ni ijo kan t’o maa wo inu Ina pelu yin. (Awon asiwaju ninu Ina si maa wi pe:) "Ko si maawole-maarora fun won." Dajudaju won yoo wo inu Ina ni
Surah Sad, Verse 59
قَالُواْ بَلۡ أَنتُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِكُمۡۖ أَنتُمۡ قَدَّمۡتُمُوهُ لَنَاۖ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرَارُ
(Awon omoleyin ninu Ina) maa wi pe: "Rara, eyin naa ko si maawole-maarora fun yin. Eyin l’e pe wa sibi eyi (t’o bi Ina)." O si buru ni ibugbe
Surah Sad, Verse 60
قَالُواْ رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدۡهُ عَذَابٗا ضِعۡفٗا فِي ٱلنَّارِ
Won (tun) wi pe: "Oluwa wa, eni ti o pe wa (sibi iya) yii, se alekun adipele iya fun un ninu Ina
Surah Sad, Verse 61
وَقَالُواْ مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالٗا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ ٱلۡأَشۡرَارِ
Won tun wi pe: "Ki lo sele si wa ti a o ri awon okunrin kan, awon ti a n ka mo awon eni buruku
Surah Sad, Verse 62
أَتَّخَذۡنَٰهُمۡ سِخۡرِيًّا أَمۡ زَاغَتۡ عَنۡهُمُ ٱلۡأَبۡصَٰرُ
Sebi a fi won se yeye tabi awon oju ti fo won ni (l’a o fi ri won ninu Ina)
Surah Sad, Verse 63
إِنَّ ذَٰلِكَ لَحَقّٞ تَخَاصُمُ أَهۡلِ ٱلنَّارِ
Dajudaju iyen, ariyanjiyan awon ero inu Ina, ododo ma ni
Surah Sad, Verse 64
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ مُنذِرٞۖ وَمَا مِنۡ إِلَٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
So pe: "Emi ni olukilo. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si ayafi Allahu, Okan soso, Olubori
Surah Sad, Verse 65
رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّـٰرُ
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji, Alagbara, Alaforijin
Surah Sad, Verse 66
قُلۡ هُوَ نَبَؤٌاْ عَظِيمٌ
So pe: "(al-Ƙur’an) ni iro nla
Surah Sad, Verse 67
أَنتُمۡ عَنۡهُ مُعۡرِضُونَ
Eyin si n gbunri kuro nibe
Surah Sad, Verse 68
مَا كَانَ لِيَ مِنۡ عِلۡمِۭ بِٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰٓ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ
Emi ko si nimo nipa awon molaika ti o wa ni aye giga nigba ti won n saroye
Surah Sad, Verse 69
إِن يُوحَىٰٓ إِلَيَّ إِلَّآ أَنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٌ
Ki ni won fi ranse si mi bi ko se pe emi ni olukilo ponnbele
Surah Sad, Verse 70
إِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن طِينٖ
(Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: "Dajudaju Emi yoo da abara kan lati inu erupe
Surah Sad, Verse 71
فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ
Nigba ti Mo ba se e t’o dogba jale tan, ti Mo si fe ninu ategun emi ti Mo da sinu re, nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini
Surah Sad, Verse 72
فَسَجَدَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ
Gbogbo awon molaika patapata si fori kanle ki i
Surah Sad, Verse 73
إِلَّآ إِبۡلِيسَ ٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ayafi ’Iblis, ti o segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo
Surah Sad, Verse 74
قَالَ يَـٰٓإِبۡلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسۡجُدَ لِمَا خَلَقۡتُ بِيَدَيَّۖ أَسۡتَكۡبَرۡتَ أَمۡ كُنتَ مِنَ ٱلۡعَالِينَ
(Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o ko fun o lati fori kanle ki ohun ti Mo fi owo Mi mejeeji da? Se o segberaga ni tabi o wa ninu awon eni giga
Surah Sad, Verse 75
قَالَ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡهُ خَلَقۡتَنِي مِن نَّارٖ وَخَلَقۡتَهُۥ مِن طِينٖ
O wi pe: "Emi loore julo si oun; O da emi lati ara ina. O si da oun lati ara erupe amo
Surah Sad, Verse 76
قَالَ فَٱخۡرُجۡ مِنۡهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٞ
(Allahu) so pe: "Jade kuro ninu (Ogba Idera) nitori pe dajudaju iwo ni eni eko
Surah Sad, Verse 77
وَإِنَّ عَلَيۡكَ لَعۡنَتِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Ati pe dajudaju egun Mi yoo wa lori re titi di Ojo esan
Surah Sad, Verse 78
قَالَ رَبِّ فَأَنظِرۡنِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ
(Esu) wi pe: "Oluwa mi, lo mi lara titi di ojo ti Won yoo gbe eda dide
Surah Sad, Verse 79
قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلۡمُنظَرِينَ
(Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa ninu awon ti won maa lo lara
Surah Sad, Verse 80
إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡوَقۡتِ ٱلۡمَعۡلُومِ
titi di ojo akoko ti A ti mo
Surah Sad, Verse 81
قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغۡوِيَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ
(Esu) wi pe: "Mo fi agbara Re bura, dajudaju emi yoo ko gbogbo won sinu isina
Surah Sad, Verse 82
إِلَّا عِبَادَكَ مِنۡهُمُ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won
Surah Sad, Verse 83
قَالَ فَٱلۡحَقُّ وَٱلۡحَقَّ أَقُولُ
(Allahu) so pe: "Ododo (ni ibura Mi), ododo si ni Emi n so, (pe)
Surah Sad, Verse 84
لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ أَجۡمَعِينَ
dajudaju Mo maa fi iwo ati gbogbo awon t’o ba tele o ninu won kun inu ina Jahanamo
Surah Sad, Verse 85
قُلۡ مَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُتَكَلِّفِينَ
So pe: "Emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Emi ko si si ninu awon onitan-aroso
Surah Sad, Verse 86
إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ
Ki ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda
Surah Sad, Verse 87
وَلَتَعۡلَمُنَّ نَبَأَهُۥ بَعۡدَ حِينِۭ
Ati pe dajudaju e maa mo iro re (si ododo) laipe
Surah Sad, Verse 88