Surah Az-Zumar - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Isokale Tira naa (sele) lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
Surah Az-Zumar, Verse 1
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ فَٱعۡبُدِ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ
Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. Nitori naa, josin fun Allahu ni olusafomo-esin fun Un
Surah Az-Zumar, Verse 2
أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ
Gbo! Ti Allahu ni esin mimo. Awon ti won si mu awon alafeyinti kan yato si Allahu, (won wi pe): "A o josin fun won bi ko se pe nitori ki won le mu wa sunmo Allahu pekipeki ni." Dajudaju Allahu l’O maa dajo laaarin won nipa ohun ti won n yapa enu nipa re (iyen, esin ’Islam). Dajudaju Allahu ki i fi ona mo eni ti o je opuro, alaigbagbo
Surah Az-Zumar, Verse 3
لَّوۡ أَرَادَ ٱللَّهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدٗا لَّٱصۡطَفَىٰ مِمَّا يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
Ti o ba je pe Allahu ba fe fi eni kan se omo ni, iba sesa ohun ti O ba fe (fi somo) ninu nnkan ti O da. Mimo ni fun Un (nibi eyi). Oun ni Allahu, Okan soso, Olubori
Surah Az-Zumar, Verse 4
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ يُكَوِّرُ ٱلَّيۡلَ عَلَى ٱلنَّهَارِ وَيُكَوِّرُ ٱلنَّهَارَ عَلَى ٱلَّيۡلِۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمًّىۗ أَلَا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّـٰرُ
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O n ti oru bonu osan. O si n ti osan bonu oru. O si ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Gbo! Oun ni Alagbara, Alaforijin
Surah Az-Zumar, Verse 5
خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۚ يَخۡلُقُكُمۡ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ خَلۡقٗا مِّنۢ بَعۡدِ خَلۡقٖ فِي ظُلُمَٰتٖ ثَلَٰثٖۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ
O seda yin lati ara emi eyo kan. Leyin naa, O da iyawo re lati ara re. O si so mejo kale fun yin ninu eran-osin ni tako-tabo. O n seda yin sinu iya yin, eda kan leyin eda kan ninu awon okunkun meta. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
Surah Az-Zumar, Verse 6
إِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنكُمۡۖ وَلَا يَرۡضَىٰ لِعِبَادِهِ ٱلۡكُفۡرَۖ وَإِن تَشۡكُرُواْ يَرۡضَهُ لَكُمۡۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرۡجِعُكُمۡ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Ti e ba sai moore, dajudaju Allahu roro lai si eyin (ko si ni bukata si yin). Ko si yonu si aimoore fun awon erusin Re. Ti e ba dupe, O maa yonu si i fun yin. Eleru-ese kan ko si nii ru eru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda
Surah Az-Zumar, Verse 7
۞وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَا رَبَّهُۥ مُنِيبًا إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُۥ نِعۡمَةٗ مِّنۡهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدۡعُوٓاْ إِلَيۡهِ مِن قَبۡلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِۦۚ قُلۡ تَمَتَّعۡ بِكُفۡرِكَ قَلِيلًا إِنَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلنَّارِ
Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Oluwa re ni oluseri si odo Re. Leyin naa, nigba ti O ba se idera fun un lati odo Re, o maa gbagbe ohun t’o se ni adua si (Oluwa re) siwaju. O si maa so (awon eda kan) di akegbe fun Allahu nitori ki o le ko isina ba (elomiiran) ni oju ona esin Re (’Islam). So pe: "Fi aigbagbo re jegbadun aye fun igba die. Dajudaju iwo wa ninu awon ero inu Ina
Surah Az-Zumar, Verse 8
أَمَّنۡ هُوَ قَٰنِتٌ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ سَاجِدٗا وَقَآئِمٗا يَحۡذَرُ ٱلۡأٓخِرَةَ وَيَرۡجُواْ رَحۡمَةَ رَبِّهِۦۗ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلَّذِينَ يَعۡلَمُونَ وَٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Nje eni ti o je olutele ti Allahu (t’o je) oluforikanle ati oludideduro (lori irun kiki) ni awon akoko ale, t’o n sora fun orun, t’o si n ni agbekele ninu aanu Oluwa re (da bi elese bi?) So pe: "Nje awon ti won nimo ati awon ti ko nimo dogba bi? Awon onilaakaye nikan l’o n lo iranti
Surah Az-Zumar, Verse 9
قُلۡ يَٰعِبَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۗ وَأَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٌۗ إِنَّمَا يُوَفَّى ٱلصَّـٰبِرُونَ أَجۡرَهُم بِغَيۡرِ حِسَابٖ
So pe: "Eyin erusin Mi ti e gbagbo ni ododo, e beru Oluwa yin. Esan rere wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Ile Allahu si gbooro. Awon onisuuru ni Won si maa fun ni esan (rere ise) won lai la isiro lo
Surah Az-Zumar, Verse 10
قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ
So pe: "Dajudaju Won pa mi ni ase pe ki ng josin fun Allahu ni ti oluse-afomo-esin fun Un
Surah Az-Zumar, Verse 11
وَأُمِرۡتُ لِأَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
Won tun pa mi ni ase pe ki emi je eni akoko (ninu) awon musulumi (ni asiko temi)
Surah Az-Zumar, Verse 12
قُلۡ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ
So pe: "Dajudaju emi n paya iya ojo nla, ti mo ba fi le yapa ase Oluwa mi
Surah Az-Zumar, Verse 13
قُلِ ٱللَّهَ أَعۡبُدُ مُخۡلِصٗا لَّهُۥ دِينِي
So pe: "Allahu ni emi yoo maa josin fun (mo maa je) oluse-afomo-esin mi fun Un
Surah Az-Zumar, Verse 14
فَٱعۡبُدُواْ مَا شِئۡتُم مِّن دُونِهِۦۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ
Nitori naa, ki e josin fun ohun ti e ba fe leyin Re." So pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won lofo ni Ojo Ajinde. Gbo! Iyen, ohun ni ofo ponnbele
Surah Az-Zumar, Verse 15
لَهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ ظُلَلٞ مِّنَ ٱلنَّارِ وَمِن تَحۡتِهِمۡ ظُلَلٞۚ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ ٱللَّهُ بِهِۦ عِبَادَهُۥۚ يَٰعِبَادِ فَٱتَّقُونِ
Awon aja Ina maa wa ni oke won. Awon aja yo si wa ni isale won. Iyen ni Allahu fi n deru ba awon erusin Re (bayii pe:) "Eyin erusin Mi, e beru Mi
Surah Az-Zumar, Verse 16
وَٱلَّذِينَ ٱجۡتَنَبُواْ ٱلطَّـٰغُوتَ أَن يَعۡبُدُوهَا وَأَنَابُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰۚ فَبَشِّرۡ عِبَادِ
Awon ti won yago fun awon orisa lati josin fun un, won si seri pada si (jijosin fun) Allahu, iro idunnu n be fun won. Nitori naa, fun awon erusin Mi ni iro idunnu
Surah Az-Zumar, Verse 17
ٱلَّذِينَ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقَوۡلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحۡسَنَهُۥٓۚ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَىٰهُمُ ٱللَّهُۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمۡ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Awon t’o n teti gbo oro, ti won si n tele eyi t’o dara julo ninu re, awon wonyen ni awon ti Allahu fi mona. Awon wonyen, awon ni onilaakaye
Surah Az-Zumar, Verse 18
أَفَمَنۡ حَقَّ عَلَيۡهِ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِي ٱلنَّارِ
Se eni ti oro iya Ina ti kole lori (nipa aigbagbo re, se ko nii wona ni?) Se iwo l’o maa la eni t’o wa ninu Ina (nipase aigbagbo re) ni
Surah Az-Zumar, Verse 19
لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ لَهُمۡ غُرَفٞ مِّن فَوۡقِهَا غُرَفٞ مَّبۡنِيَّةٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ ٱلۡمِيعَادَ
Sugbon awon t’o beru Oluwa won, tiwon ni awon ile giga, ti awon ile giga tun wa loke re, awon odo yo si maa san ni isale re. Adehun Allahu ni (eyi). Allahu ko si nii ye adehun naa
Surah Az-Zumar, Verse 20
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَسَلَكَهُۥ يَنَٰبِيعَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعٗا مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصۡفَرّٗا ثُمَّ يَجۡعَلُهُۥ حُطَٰمًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo, O si mu omi naa bo sinu awon opopona odo ninu ile, leyin naa, O n fi mu irugbin ti awo won yato sira won jade, leyin naa, (irugbin naa) yoo gbe, o si maa ri i ni pipon, leyin naa, O maa so o di rirun? Dajudaju iranti wa ninu iyen fun awon onilaakaye
Surah Az-Zumar, Verse 21
أَفَمَن شَرَحَ ٱللَّهُ صَدۡرَهُۥ لِلۡإِسۡلَٰمِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٖ مِّن رَّبِّهِۦۚ فَوَيۡلٞ لِّلۡقَٰسِيَةِ قُلُوبُهُم مِّن ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
Nje eni ti Allahu gba okan re laaye fun esin ’Islam, ti o si wa ninu imole lati odo Oluwa re (da bi alaigbagbo bi)? Egbe ni fun awon ti okan won le si iranti Allahu. Awon wonyen wa ninu isina ponnbele
Surah Az-Zumar, Verse 22
ٱللَّهُ نَزَّلَ أَحۡسَنَ ٱلۡحَدِيثِ كِتَٰبٗا مُّتَشَٰبِهٗا مَّثَانِيَ تَقۡشَعِرُّ مِنۡهُ جُلُودُ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُمۡ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمۡ وَقُلُوبُهُمۡ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُدَى ٱللَّهِ يَهۡدِي بِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٍ
Allahu l’O so oro t’o dara julo kale, (o je) Tira, ti (awon oro inu re) jora won ni oro asotunso, ti awo ara awon t’o n paya Oluwa won yo si maa wariri nitori re. Leyin naa, awo ara won ati okan won yoo maa ro nibi iranti Allahu. Iyen ni imona Allahu. O si n fi se imona fun eni ti O ba fe. Eni ti Allahu ba si lona, ko si nii si afinimona kan fun un
Surah Az-Zumar, Verse 23
أَفَمَن يَتَّقِي بِوَجۡهِهِۦ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَقِيلَ لِلظَّـٰلِمِينَ ذُوقُواْ مَا كُنتُمۡ تَكۡسِبُونَ
Nje eni ti o maa foju ara re ko aburu iya Ina ni Ojo Ajinde (da bi eni ti o maa wo inu Ogba Idera woorowo)? Won yo si so fun awon alabosi pe: "E to iya ohun ti e n se nise wo
Surah Az-Zumar, Verse 24
كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Awon t’o siwaju won pe ododo niro. Nitori naa, iya de ba won ni aye ti won ko ti fura
Surah Az-Zumar, Verse 25
فَأَذَاقَهُمُ ٱللَّهُ ٱلۡخِزۡيَ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Allahu fun won ni abuku iya to wo ninu isemi aye yii. Iya orun si tobi julo ti o ba je pe won mo
Surah Az-Zumar, Verse 26
وَلَقَدۡ ضَرَبۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖ لَّعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
A si ti se gbogbo akawe fun awon eniyan ninu al-Ƙur’an yii nitori ki won le lo iranti
Surah Az-Zumar, Verse 27
قُرۡءَانًا عَرَبِيًّا غَيۡرَ ذِي عِوَجٖ لَّعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ
Al-Ƙur’an ni ede Larubawa, eyi ti oro inu re ko doju ru (l’A sokale) nitori ki won le beru (Allahu)
Surah Az-Zumar, Verse 28
ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلٗا فِيهِ شُرَكَآءُ مُتَشَٰكِسُونَ وَرَجُلٗا سَلَمٗا لِّرَجُلٍ هَلۡ يَسۡتَوِيَانِ مَثَلًاۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Allahu fi akawe kan lele; erukunrin kan t’o wa labe ase oga pupo ti won n fa a kiri (ko si mo ta ni o maa da lohun ninu awon oga re) ati (akawe) erukunrin kan t’o da wa gedegbe labe ogakunrin kan. Nje awon (eru) mejeeji dogba ni akawe bi? Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko mo
Surah Az-Zumar, Verse 29
إِنَّكَ مَيِّتٞ وَإِنَّهُم مَّيِّتُونَ
Dajudaju iwo maa ku. Dajudaju awon naa maa ku
Surah Az-Zumar, Verse 30
ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عِندَ رَبِّكُمۡ تَخۡتَصِمُونَ
Leyin naa, ni Ojo Ajinde dajudaju eyin yoo maa ba ara yin se ariyanjiyan ni odo Oluwa yin
Surah Az-Zumar, Verse 31
۞فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَذَبَ عَلَى ٱللَّهِ وَكَذَّبَ بِٱلصِّدۡقِ إِذۡ جَآءَهُۥٓۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡكَٰفِرِينَ
Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o paro mo Allahu, t’o tun pe ododo niro nigba ti o de ba a? Se ki i se Ina ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni
Surah Az-Zumar, Verse 32
وَٱلَّذِي جَآءَ بِٱلصِّدۡقِ وَصَدَّقَ بِهِۦٓ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُتَّقُونَ
Eni ti o si mu ododo wa (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) ati (awon) eni t’o gba a gbo ni ododo; awon wonyen, awon ni oluberu (Allahu)
Surah Az-Zumar, Verse 33
لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمۡۚ ذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen si ni esan awon eni rere
Surah Az-Zumar, Verse 34
لِيُكَفِّرَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ أَسۡوَأَ ٱلَّذِي عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
nitori ki Allahu le ba won pa aburu ti won se re ati (nitori) ki O le fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won
Surah Az-Zumar, Verse 35
أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِكَافٍ عَبۡدَهُۥۖ وَيُخَوِّفُونَكَ بِٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٖ
Se Allahu ko to fun erusin Re ni? Won si n fi awon elomiiran leyin Re deru ba o! Enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un
Surah Az-Zumar, Verse 36
وَمَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّضِلٍّۗ أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِعَزِيزٖ ذِي ٱنتِقَامٖ
Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), ko le si asinilona fun un. Se Allahu ko ni Alagbara, Olugba-esan
Surah Az-Zumar, Verse 37
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۚ قُلۡ أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَنِيَ ٱللَّهُ بِضُرٍّ هَلۡ هُنَّ كَٰشِفَٰتُ ضُرِّهِۦٓ أَوۡ أَرَادَنِي بِرَحۡمَةٍ هَلۡ هُنَّ مُمۡسِكَٰتُ رَحۡمَتِهِۦۚ قُلۡ حَسۡبِيَ ٱللَّهُۖ عَلَيۡهِ يَتَوَكَّلُ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ
Dajudaju ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." So pe: "E so fun mi nipa awon nnkan ti e n pe leyin Allahu, ti Allahu ba gbero inira kan ro mi, nje won le mu inira Re kuro fun mi? Tabi ti O ba gbero ike kan si mi, nje won le da ike Re duro bi?" So pe: "Allahu to fun mi. Oun si ni awon olugbarale n gbarale
Surah Az-Zumar, Verse 38
قُلۡ يَٰقَوۡمِ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنِّي عَٰمِلٞۖ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
So pe: "Eyin eniyan mi, e se tiyin ni aye yin. Emi naa n se temi. Nitori naa, laipe e maa mo
Surah Az-Zumar, Verse 39
مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيۡهِ عَذَابٞ مُّقِيمٌ
eni ti iya ti o maa yepere re maa de ba, ti iya gbere si maa ko le lori
Surah Az-Zumar, Verse 40
إِنَّآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ لِلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٍ
Dajudaju Awa so Tira kale fun o pelu ododo (ki o le fi se iranti) fun awon eniyan. Nitori naa, eni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Eni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Iwo si ko ni oluso lori won
Surah Az-Zumar, Verse 41
ٱللَّهُ يَتَوَفَّى ٱلۡأَنفُسَ حِينَ مَوۡتِهَا وَٱلَّتِي لَمۡ تَمُتۡ فِي مَنَامِهَاۖ فَيُمۡسِكُ ٱلَّتِي قَضَىٰ عَلَيۡهَا ٱلۡمَوۡتَ وَيُرۡسِلُ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّىۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Allahu l’O n gba awon emi ni akoko iku won ati (awon emi) ti ko ku soju oorun won. O n mu (awon emi) ti O ti pebubu iku le lori mole. O si n fi awon yooku sile titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
Surah Az-Zumar, Verse 42
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُفَعَآءَۚ قُلۡ أَوَلَوۡ كَانُواْ لَا يَمۡلِكُونَ شَيۡـٔٗا وَلَا يَعۡقِلُونَ
Tabi won mu awon olusipe miiran leyin Allahu ni? So pe: "(Won mu won ni olusipe) t’o si je pe won ko ni agbara kan kan, won ko si nii laakaye
Surah Az-Zumar, Verse 43
قُل لِّلَّهِ ٱلشَّفَٰعَةُ جَمِيعٗاۖ لَّهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
So pe: "Ti Allahu ni gbogbo isipe patapata. TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si
Surah Az-Zumar, Verse 44
وَإِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُ ٱشۡمَأَزَّتۡ قُلُوبُ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِۖ وَإِذَا ذُكِرَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦٓ إِذَا هُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ
Nigba ti won ba daruko Allahu nikan soso, okan awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo maa sa kuro (nibi mimu Allahu ni okan soso). Nigba ti won ba si daruko awon miiran (ti won n josin fun) leyin Re, nigba naa ni won yoo maa dunnu
Surah Az-Zumar, Verse 45
قُلِ ٱللَّهُمَّ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ عَٰلِمَ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ أَنتَ تَحۡكُمُ بَيۡنَ عِبَادِكَ فِي مَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
So pe: "Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, Onimo-ikoko ati gbangba, Iwo l’O maa dajo laaarin awon erusin Re nipa ohun ti won n yapa enu si
Surah Az-Zumar, Verse 46
وَلَوۡ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا وَمِثۡلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفۡتَدَوۡاْ بِهِۦ مِن سُوٓءِ ٱلۡعَذَابِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَبَدَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مَا لَمۡ يَكُونُواْ يَحۡتَسِبُونَ
Ti o ba je pe dajudaju gbogbo nnkan ti o wa lori ile je ti awon alabosi ati iru re miiran pelu re (tun je tiwon ni), won iba fi serapada (fun emi ara won) nibi aburu iya ni Ojo Ajinde. (Nigba yen) ohun ti won ko lero maa han si won ni odo Allahu
Surah Az-Zumar, Verse 47
وَبَدَا لَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Awon aburu ohun ti won se nise maa han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po
Surah Az-Zumar, Verse 48
فَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلۡنَٰهُ نِعۡمَةٗ مِّنَّا قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمِۭۚ بَلۡ هِيَ فِتۡنَةٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Wa. Leyin naa, nigba ti A ba fun un ni idera kan lati odo Wa, o maa wi pe: "Won fun mi pelu imo ni." Ko si ri bee, adanwo ni, sugbon opolopo won ni ko mo
Surah Az-Zumar, Verse 49
قَدۡ قَالَهَا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Awon t’o siwaju won kuku wi (iru) re, sugbon ohun ti won n se nise ko ro won loro
Surah Az-Zumar, Verse 50
فَأَصَابَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْۚ وَٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ هَـٰٓؤُلَآءِ سَيُصِيبُهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْ وَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ
Aburu ohun ti won se nise si ba won. Awon alabosi ninu awon wonyi naa, aburu ohun ti won se nise yoo ba won. Won ko si nii mori bo
Surah Az-Zumar, Verse 51
أَوَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Se won ko mo pe dajudaju Allahu l’O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo
Surah Az-Zumar, Verse 52
۞قُلۡ يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ أَسۡرَفُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ لَا تَقۡنَطُواْ مِن رَّحۡمَةِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَغۡفِرُ ٱلذُّنُوبَ جَمِيعًاۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
So pe: "Eyin erusin Mi, ti e ti dese pupo si emi ara yin lorun, e ma se soreti nu nipa ike Allahu. Dajudaju Allahu l’O n saforijin gbogbo ese patapata. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun
Surah Az-Zumar, Verse 53
وَأَنِيبُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَأَسۡلِمُواْ لَهُۥ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
E seri pada (ni ti ironupiwada) si odo Oluwa yin. Ki e si juwo-juse sile fun Un siwaju ki iya naa t’o wa ba yin. (Bi bee ko) leyin naa, A o nii ran yin lowo
Surah Az-Zumar, Verse 54
وَٱتَّبِعُوٓاْ أَحۡسَنَ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ بَغۡتَةٗ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ
Ki e si tele ohun ti o dara julo ti won sokale fun yin lati odo Oluwa yin siwaju ki iya naa to wa ba yin ni ojiji, nigba ti eyin ko nii fura
Surah Az-Zumar, Verse 55
أَن تَقُولَ نَفۡسٞ يَٰحَسۡرَتَىٰ عَلَىٰ مَا فَرَّطتُ فِي جَنۢبِ ٱللَّهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ ٱلسَّـٰخِرِينَ
Nitori ki emi kan ma baa wi pe: "Mo ka abamo lori bi mo se jafara lori aitele ase Allahu. Ati pe emi wa ninu awon t’o n fi (oro Re) se yeye
Surah Az-Zumar, Verse 56
أَوۡ تَقُولَ لَوۡ أَنَّ ٱللَّهَ هَدَىٰنِي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُتَّقِينَ
Tabi ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe Allahu fi ona mo mi ni, dajudaju emi iba wa ninu awon oluberu (Allahu)
Surah Az-Zumar, Verse 57
أَوۡ تَقُولَ حِينَ تَرَى ٱلۡعَذَابَ لَوۡ أَنَّ لِي كَرَّةٗ فَأَكُونَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Tabi nigba ti o ba ri Ina ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe ipadasaye wa fun mi ni, emi iba si wa ninu awon oluse-rere
Surah Az-Zumar, Verse 58
بَلَىٰ قَدۡ جَآءَتۡكَ ءَايَٰتِي فَكَذَّبۡتَ بِهَا وَٱسۡتَكۡبَرۡتَ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Rara o! Awon ayah Mi kuku ti de ba o. O pe e niro. O tun segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo
Surah Az-Zumar, Verse 59
وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تَرَى ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَى ٱللَّهِ وُجُوهُهُم مُّسۡوَدَّةٌۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡمُتَكَبِّرِينَ
Ati pe ni Ojo Ajinde, o maa ri awon t’o paro mo Allahu ti oju won maa dudu. Se inu ina Jahnamo ko ni ibugbe fun awon onigbeeraga ni
Surah Az-Zumar, Verse 60
وَيُنَجِّي ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ بِمَفَازَتِهِمۡ لَا يَمَسُّهُمُ ٱلسُّوٓءُ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Allahu yoo gba awon t’o beru (Re) la sinu ile igbala won (iyen, Ogba Idera). Aburu ko nii fowo ba won. Won ko si nii banuje
Surah Az-Zumar, Verse 61
ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ
Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan
Surah Az-Zumar, Verse 62
لَّهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, awon wonyen, awon ni eni ofo
Surah Az-Zumar, Verse 63
قُلۡ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَأۡمُرُوٓنِّيٓ أَعۡبُدُ أَيُّهَا ٱلۡجَٰهِلُونَ
So pe: "Se nnkan miiran yato si Allahu l’e n pa mi lase pe ki ng maa josin fun, eyin alaimokan
Surah Az-Zumar, Verse 64
وَلَقَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ لَئِنۡ أَشۡرَكۡتَ لَيَحۡبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ
Dajudaju A ti fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re (pe) "Dajudaju ti o ba sebo, ise re maa baje. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni ofo
Surah Az-Zumar, Verse 65
بَلِ ٱللَّهَ فَٱعۡبُدۡ وَكُن مِّنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ
Rara (ma sebo). Allahu nikan ni ki o josin fun. Ki o si wa ninu awon oludupe (fun Un)
Surah Az-Zumar, Verse 66
وَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦ وَٱلۡأَرۡضُ جَمِيعٗا قَبۡضَتُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُ مَطۡوِيَّـٰتُۢ بِيَمِينِهِۦۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Won ko bu iyi fun Allahu bi o se to lati bu iyi fun Un. Gbogbo ile patapata si ni (Allahu) maa fowo ara Re gbamu ni Ojo Ajinde. O si maa fi owo otun Re ka sanmo korobojo. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
Surah Az-Zumar, Verse 67
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخۡرَىٰ فَإِذَا هُمۡ قِيَامٞ يَنظُرُونَ
Won a fon fere oniwo fun iku. Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile si maa ku afi eni ti Allahu ba fe. Leyin naa, won maa fon on ni ee keji, nigba naa won maa wa ni idide. Won yo si maa wo sun
Surah Az-Zumar, Verse 68
وَأَشۡرَقَتِ ٱلۡأَرۡضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ وَجِاْيٓءَ بِٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Ati pe ile naa yoo maa tan yanranyanran pelu imole Oluwa re. Won maa gbe iwe ise eda lele. Won si maa mu awon Anabi ati awon elerii wa. A o si sedajo laaarin won pelu ododo. A o si nii sabosi si won
Surah Az-Zumar, Verse 69
وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَا يَفۡعَلُونَ
Ati pe Won maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n se nise
Surah Az-Zumar, Verse 70
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا فُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَآ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَتۡلُونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِ رَبِّكُمۡ وَيُنذِرُونَكُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَاۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنۡ حَقَّتۡ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Won yo si da awon t’o sai gbagbo lo sinu ina Jahnamo nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Nje awon Ojise kan ko wa ba yin lati aarin ara yin, ti won n ke awon ayah Oluwa yin fun yin, ti won si n kilo ipade ojo yin oni yii fun yin?" Won wi pe: "Rara (won wa ba wa)." Sugbon oro iya ko le awon alaigbagbo lori ni
Surah Az-Zumar, Verse 71
قِيلَ ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
A oo so pe: "E wo enu ona ina Jahnamo. Olusegbere (ni yin) ninu re. Ibugbe awon olusegberaga si buru
Surah Az-Zumar, Verse 72
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا وَفُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَا سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ طِبۡتُمۡ فَٱدۡخُلُوهَا خَٰلِدِينَ
Ati pe A oo ko awon t’o beru Oluwa won lo sinu Ogba Idera nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Ki alaafia maa ba yin. Eyin se ise t’o dara. Nitori naa, e wo inu Ogba Idera, (ki e di) olusegbere (ninu re)
Surah Az-Zumar, Verse 73
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي صَدَقَنَا وَعۡدَهُۥ وَأَوۡرَثَنَا ٱلۡأَرۡضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ ٱلۡجَنَّةِ حَيۡثُ نَشَآءُۖ فَنِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ
Won a so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu adehun Re se fun wa. O tun jogun ile naa fun wa, ti a n gbe nibikibi ti a ba fe ninu Ogba Idera." Esan awon oluse-rere ma si dara
Surah Az-Zumar, Verse 74
وَتَرَى ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ حَآفِّينَ مِنۡ حَوۡلِ ٱلۡعَرۡشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡۚ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّۚ وَقِيلَ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
O maa si ri awon Molaika ti won n rokirika ni egbe Ite-ola. Won n se afomo ati idupe fun Oluwa won. A maa fi ododo sedajo laaarin awon eda. Won si maa so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda
Surah Az-Zumar, Verse 75