Surah Sad Verse 34 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Sadوَلَقَدۡ فَتَنَّا سُلَيۡمَٰنَ وَأَلۡقَيۡنَا عَلَىٰ كُرۡسِيِّهِۦ جَسَدٗا ثُمَّ أَنَابَ
Dajudaju A dan (Anabi) Sulaemon wo. A ju abara kan sori aga re. Leyin naa, (Anabi Sulaemon) seri pada (pelu ironupiwada). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni iyawo t’o to ogorun-un labe ofin eto (iyen ni pe Allahu s.w.t. l’O se e ni eto fun un). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) si fi Allahu bura ni ojo kan pe ki i se ara oruka Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni awo Anabi Sulaemon wa. Bawo wa ni o se maa je pe nipase oruka Anabi Sulaemon ni awo re fi maa kuro lara re si ara esu alujannu nigba ti Anabi Sulaemon ki i se opidan? Anabi Sulaemon ko si fi oruka joba ambosibosi pe nigba ti ko ba si oruka re lowo re l’o maa fun elomiiran ni aye lati di oba! E tun wo itose-oro fun surah al-Baƙorah; 2:102. W-Allahu ’a‘lam