Surah An-Nisa Verse 102 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَإِذَا كُنتَ فِيهِمۡ فَأَقَمۡتَ لَهُمُ ٱلصَّلَوٰةَ فَلۡتَقُمۡ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُم مَّعَكَ وَلۡيَأۡخُذُوٓاْ أَسۡلِحَتَهُمۡۖ فَإِذَا سَجَدُواْ فَلۡيَكُونُواْ مِن وَرَآئِكُمۡ وَلۡتَأۡتِ طَآئِفَةٌ أُخۡرَىٰ لَمۡ يُصَلُّواْ فَلۡيُصَلُّواْ مَعَكَ وَلۡيَأۡخُذُواْ حِذۡرَهُمۡ وَأَسۡلِحَتَهُمۡۗ وَدَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡ تَغۡفُلُونَ عَنۡ أَسۡلِحَتِكُمۡ وَأَمۡتِعَتِكُمۡ فَيَمِيلُونَ عَلَيۡكُم مَّيۡلَةٗ وَٰحِدَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِن كَانَ بِكُمۡ أَذٗى مِّن مَّطَرٍ أَوۡ كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَن تَضَعُوٓاْ أَسۡلِحَتَكُمۡۖ وَخُذُواْ حِذۡرَكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٗا مُّهِينٗا
Nigba ti o ba wa laaarin won, gbe irun duro fun won. Ki igun kan ninu won kirun pelu re, ki won mu nnkan ijagun won lowo. Nigba ti won ba si fori kanle (ti won pari irun), ki won bo seyin yin, ki igun miiran ti ko ti i kirun wa kirun pelu re. Ki won mu isora won ati nnkan ijagun won lowo. Awon t’o sai gbagbo fe ki e gbagbe awon nnkan ijagun yin ati nnkan igbadun yin, ki won le kolu yin ni ee kan naa. Ko si ese fun yin ti o ba je pe ipalara kan n be fun yin latara ojo tabi (pe) e je alaisan, pe ki e fi nnkan ijagun yin sile (lori irun). E mu nnkan isora yin lowo. Dajudaju Allahu ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo