Surah An-Nisa Verse 104 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَلَا تَهِنُواْ فِي ٱبۡتِغَآءِ ٱلۡقَوۡمِۖ إِن تَكُونُواْ تَأۡلَمُونَ فَإِنَّهُمۡ يَأۡلَمُونَ كَمَا تَأۡلَمُونَۖ وَتَرۡجُونَ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا يَرۡجُونَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
E ma se kaaare nipa wiwa awon eniyan naa (lati ja won logun). Ti eyin ba n je irora (ogbe), dajudaju awon naa n je irora (ogbe) gege bi eyin naa se n je irora. Eyin si n reti ohun ti awon ko reti lodo Allahu. Allahu si n je Onimo, Ologbon