Surah An-Nisa Verse 11 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِيٓ أَوۡلَٰدِكُمۡۖ لِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۚ فَإِن كُنَّ نِسَآءٗ فَوۡقَ ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَۖ وَإِن كَانَتۡ وَٰحِدَةٗ فَلَهَا ٱلنِّصۡفُۚ وَلِأَبَوَيۡهِ لِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٞۚ فَإِن لَّمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٞ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُۚ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخۡوَةٞ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِي بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍۗ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ لَا تَدۡرُونَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ لَكُمۡ نَفۡعٗاۚ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Allāhu ń pàṣẹ fun yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan) méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, (gbogbo rẹ̀) lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n