Surah An-Nisa Verse 11 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيُوصِيكُمُ ٱللَّهُ فِيٓ أَوۡلَٰدِكُمۡۖ لِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۚ فَإِن كُنَّ نِسَآءٗ فَوۡقَ ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُنَّ ثُلُثَا مَا تَرَكَۖ وَإِن كَانَتۡ وَٰحِدَةٗ فَلَهَا ٱلنِّصۡفُۚ وَلِأَبَوَيۡهِ لِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُ مِمَّا تَرَكَ إِن كَانَ لَهُۥ وَلَدٞۚ فَإِن لَّمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلَدٞ وَوَرِثَهُۥٓ أَبَوَاهُ فَلِأُمِّهِ ٱلثُّلُثُۚ فَإِن كَانَ لَهُۥٓ إِخۡوَةٞ فَلِأُمِّهِ ٱلسُّدُسُۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِي بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍۗ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ لَا تَدۡرُونَ أَيُّهُمۡ أَقۡرَبُ لَكُمۡ نَفۡعٗاۚ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Allahu n pase fun yin nipa (ogun ti e maa pin fun) awon omo yin; ti okunrin ni iru ipin ti obinrin meji. Ti won ba si je obinrin (nikan) meji soke, tiwon ni ida meji ninu ida meta ohun ti (oku) fi sile. Ti o ba je obinrin kan soso, idaji ni tire. Ti obi re mejeeji, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji ninu ohun ti oku fi sile, ti o ba ni omo laye. Ti ko ba si ni omo laye, ti o si je pe awon obi re mejeeji l’o maa jogun re, ida kan ninu ida meta ni ti iya re. Ti o ba ni arakunrin (tabi arabinrin), ida kan ninu ida mefa ni ti iya re, (gbogbo re) leyin asoole ti o so tabi gbese. Awon baba yin ati awon omokunrin yin; eyin ko mo ewo ninu won lo maa mu anfaani ba yin julo. (Ipin) oran-anyan ni lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon