Surah An-Nisa Verse 127 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَيَسۡتَفۡتُونَكَ فِي ٱلنِّسَآءِۖ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِيهِنَّ وَمَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ فِي يَتَٰمَى ٱلنِّسَآءِ ٱلَّـٰتِي لَا تُؤۡتُونَهُنَّ مَا كُتِبَ لَهُنَّ وَتَرۡغَبُونَ أَن تَنكِحُوهُنَّ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلۡوِلۡدَٰنِ وَأَن تَقُومُواْ لِلۡيَتَٰمَىٰ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِهِۦ عَلِيمٗا
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fun yín. Ohun tí wọ́n ń ké fun yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fun yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò láti fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀