Surah An-Nisa Verse 128 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَإِنِ ٱمۡرَأَةٌ خَافَتۡ مِنۢ بَعۡلِهَا نُشُوزًا أَوۡ إِعۡرَاضٗا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يُصۡلِحَا بَيۡنَهُمَا صُلۡحٗاۚ وَٱلصُّلۡحُ خَيۡرٞۗ وَأُحۡضِرَتِ ٱلۡأَنفُسُ ٱلشُّحَّۚ وَإِن تُحۡسِنُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا
Tí obìnrin kan bá páyà ìṣe oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára jú lọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́