Surah An-Nisa Verse 24 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisa۞وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۖ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمۡ أَن تَبۡتَغُواْ بِأَمۡوَٰلِكُم مُّحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَۚ فَمَا ٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهِۦ مِنۡهُنَّ فَـَٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا تَرَٰضَيۡتُم بِهِۦ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡفَرِيضَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni t’ó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀tọ́ fun yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn fún ìgbà díẹ̀ (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn. Ọ̀ran-anyàn ni. Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ jọ yọ́nú sí (láti fojú fò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (t’ó jẹ́ ọ̀ran-anyàn). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n