Surah An-Nisa Verse 24 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisa۞وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۖ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمۡ أَن تَبۡتَغُواْ بِأَمۡوَٰلِكُم مُّحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَۚ فَمَا ٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهِۦ مِنۡهُنَّ فَـَٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا تَرَٰضَيۡتُم بِهِۦ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡفَرِيضَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا
(O tun je eewo lati fe) awon abileko ninu awon obinrin ayafi awon erubinrin yin. Ofin Allahu niyi lori yin. Won si se eni t’o n be leyin awon wonyen ni eto fun yin pe ki e wa won fe pelu dukia yin; e fe won ni fife iyawo, lai nii ba won se sina (siwaju yigi siso). Eni ti e ba si fe ni fife iyawo, ti e si ti je igbadun oorun ife lara won fun igba die (amo ti e fe ko won sile), e fun won ni sodaaki won. Oran-anyan ni. Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e jo yonu si (lati foju fo laaarin ara yin) leyin sodaaki (t’o je oran-anyan). Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon