Surah An-Nisa Verse 6 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا
Ẹ máa ṣàgbéyẹ̀wò (òye) àwọn ọmọ òrukàn títí wọn yóò fi tó ìgbéyàwó ṣe. Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò