Surah An-Nisa Verse 6 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا
E maa sagbeyewo (oye) awon omo orukan titi won yoo fi to igbeyawo se. Ti e ba si ti ri oye lara won, ki e da dukia won pada fun won. E o gbodo je dukia won ni ije apa ati ijekuje ki won to dagba. Eni ti o ba je oloro, ki o moju kuro (nibe). Eni ti o ba je alaini, ki o je ninu re ni ona t’o dara. Nitori naa, ti e ba fe da dukia won pada fun won, e pe awon elerii si won. Allahu si to ni Olusiro