Surah An-Nisa Verse 89 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ كَمَا كَفَرُواْ فَتَكُونُونَ سَوَآءٗۖ فَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ أَوۡلِيَآءَ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَخُذُوهُمۡ وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ وَجَدتُّمُوهُمۡۖ وَلَا تَتَّخِذُواْ مِنۡهُمۡ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرًا
Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa ṣí kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ṣíṣe hijrah náà), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti rí wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn