Surah An-Nisa Verse 90 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaإِلَّا ٱلَّذِينَ يَصِلُونَ إِلَىٰ قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٌ أَوۡ جَآءُوكُمۡ حَصِرَتۡ صُدُورُهُمۡ أَن يُقَٰتِلُوكُمۡ أَوۡ يُقَٰتِلُواْ قَوۡمَهُمۡۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَسَلَّطَهُمۡ عَلَيۡكُمۡ فَلَقَٰتَلُوكُمۡۚ فَإِنِ ٱعۡتَزَلُوكُمۡ فَلَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ وَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَمَ فَمَا جَعَلَ ٱللَّهُ لَكُمۡ عَلَيۡهِمۡ سَبِيلٗا
Àyàfi àwọn t’ó bá dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (akin-ọkàn) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fun yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, nígbà náà Allāhu kò fun yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun)