Surah An-Nisa Verse 91 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaسَتَجِدُونَ ءَاخَرِينَ يُرِيدُونَ أَن يَأۡمَنُوكُمۡ وَيَأۡمَنُواْ قَوۡمَهُمۡ كُلَّ مَا رُدُّوٓاْ إِلَى ٱلۡفِتۡنَةِ أُرۡكِسُواْ فِيهَاۚ فَإِن لَّمۡ يَعۡتَزِلُوكُمۡ وَيُلۡقُوٓاْ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَمَ وَيَكُفُّوٓاْ أَيۡدِيَهُمۡ فَخُذُوهُمۡ وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ ثَقِفۡتُمُوهُمۡۚ وَأُوْلَـٰٓئِكُمۡ جَعَلۡنَا لَكُمۡ عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينٗا
Ẹ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n fẹ́ fi yín lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì fẹ́ fi àwọn ènìyàn wọn lọ́kàn balẹ̀ (pé) nígbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) ni wọ́n ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fun yín, tí wọn kò juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fun yín ní agbára t’ó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun)