Surah An-Nisa Verse 92 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٍ أَن يَقۡتُلَ مُؤۡمِنًا إِلَّا خَطَـٔٗاۚ وَمَن قَتَلَ مُؤۡمِنًا خَطَـٔٗا فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖ وَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُواْۚ فَإِن كَانَ مِن قَوۡمٍ عَدُوّٖ لَّكُمۡ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ وَإِن كَانَ مِن قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞ فَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ وَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ تَوۡبَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó sì máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fun yín, onígbàgbọ́ òdodo sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn, ó máa san owó ẹ̀mí fún wọn. Ó sì máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí ẹrú onígbàgbọ́ òdodo, ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n