Surah An-Nisa Verse 92 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٍ أَن يَقۡتُلَ مُؤۡمِنًا إِلَّا خَطَـٔٗاۚ وَمَن قَتَلَ مُؤۡمِنًا خَطَـٔٗا فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖ وَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُواْۚ فَإِن كَانَ مِن قَوۡمٍ عَدُوّٖ لَّكُمۡ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ وَإِن كَانَ مِن قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞ فَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ وَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ تَوۡبَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا
Ko letoo fun onigbagbo ododo kan lati pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba seesi. Eni ti o ba si seesi pa onigbagbo ododo kan, o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. O si maa san owo emi fun awon eniyan oku afi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba si wa ninu awon eniyan kan ti o je ota fun yin, onigbagbo ododo si ni (eni ti won seesi pa), o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Ti o ba je ijo ti adehun n be laaarin eyin ati awon, o maa san owo emi fun won. O si maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Eni ti ko ba ri eru onigbagbo ododo, o maa gba aawe osu meji ni telentele. (Ona) ironupiwada kan lati odo Allahu (niyi). Allahu n je Onimo, Ologbon