UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Fussilat - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


حمٓ

Hā mīm
Surah Fussilat, Verse 1


تَنزِيلٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

Ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí kan (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Fussilat, Verse 2


كِتَٰبٞ فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ

(Èyí ni) Tírà kan tí Wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀; al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá ni fún ìjọ t’ó nímọ̀
Surah Fussilat, Verse 3


بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا فَأَعۡرَضَ أَكۡثَرُهُمۡ فَهُمۡ لَا يَسۡمَعُونَ

(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i
Surah Fussilat, Verse 4


وَقَالُواْ قُلُوبُنَا فِيٓ أَكِنَّةٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ وَفِيٓ ءَاذَانِنَا وَقۡرٞ وَمِنۢ بَيۡنِنَا وَبَيۡنِكَ حِجَابٞ فَٱعۡمَلۡ إِنَّنَا عَٰمِلُونَ

Wọ́n sì wí pé: "Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa
Surah Fussilat, Verse 5


قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَٱسۡتَقِيمُوٓاْ إِلَيۡهِ وَٱسۡتَغۡفِرُوهُۗ وَوَيۡلٞ لِّلۡمُشۡرِكِينَ

Sọ pé: "Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í, kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Fussilat, Verse 6


ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ

àwọn tí kò yọ Zakāh. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
Surah Fussilat, Verse 7


إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونٖ

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín ń bẹ fún wọn
Surah Fussilat, Verse 8


۞قُلۡ أَئِنَّكُمۡ لَتَكۡفُرُونَ بِٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ فِي يَوۡمَيۡنِ وَتَجۡعَلُونَ لَهُۥٓ أَندَادٗاۚ ذَٰلِكَ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Sọ pé: "Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ fún Un?" Ìyẹn sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Surah Fussilat, Verse 9


وَجَعَلَ فِيهَا رَوَٰسِيَ مِن فَوۡقِهَا وَبَٰرَكَ فِيهَا وَقَدَّرَ فِيهَآ أَقۡوَٰتَهَا فِيٓ أَرۡبَعَةِ أَيَّامٖ سَوَآءٗ لِّلسَّآئِلِينَ

Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀). ó jẹyọ nínú wọn pé “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54 n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”
Surah Fussilat, Verse 10


ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ وَهِيَ دُخَانٞ فَقَالَ لَهَا وَلِلۡأَرۡضِ ٱئۡتِيَا طَوۡعًا أَوۡ كَرۡهٗا قَالَتَآ أَتَيۡنَا طَآئِعِينَ

Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: "Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀." Àwọn méjèèjì sọ pé: "A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀
Surah Fussilat, Verse 11


فَقَضَىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَاتٖ فِي يَوۡمَيۡنِ وَأَوۡحَىٰ فِي كُلِّ سَمَآءٍ أَمۡرَهَاۚ وَزَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِمَصَٰبِيحَ وَحِفۡظٗاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ

Ó sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀
Surah Fussilat, Verse 12


فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَقُلۡ أَنذَرۡتُكُمۡ صَٰعِقَةٗ مِّثۡلَ صَٰعِقَةِ عَادٖ وَثَمُودَ

Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: "Èmi ń ṣèkìlọ̀ ìparun irú ìparun ìjọ ‘Ād àti Thamūd fun yín ni
Surah Fussilat, Verse 13


إِذۡ جَآءَتۡهُمُ ٱلرُّسُلُ مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ قَالُواْ لَوۡ شَآءَ رَبُّنَا لَأَنزَلَ مَلَـٰٓئِكَةٗ فَإِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn, (wọ́n sọ) pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu." Wọ́n wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́
Surah Fussilat, Verse 14


فَأَمَّا عَادٞ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَقَالُواْ مَنۡ أَشَدُّ مِنَّا قُوَّةًۖ أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَهُمۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۖ وَكَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: "Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?" Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni. Wọ́n sì ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa
Surah Fussilat, Verse 15


فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِيٓ أَيَّامٖ نَّحِسَاتٖ لِّنُذِيقَهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَخۡزَىٰۖ وَهُمۡ لَا يُنصَرُونَ

Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́. “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú aláìmọ̀kan
Surah Fussilat, Verse 16


وَأَمَّا ثَمُودُ فَهَدَيۡنَٰهُمۡ فَٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡعَمَىٰ عَلَى ٱلۡهُدَىٰ فَأَخَذَتۡهُمۡ صَٰعِقَةُ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡهُونِ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ

Ní ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, igbe ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Fussilat, Verse 17


وَنَجَّيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ

A sì gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là
Surah Fussilat, Verse 18


وَيَوۡمَ يُحۡشَرُ أَعۡدَآءُ ٱللَّهِ إِلَى ٱلنَّارِ فَهُمۡ يُوزَعُونَ

Ní ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn
Surah Fussilat, Verse 19


حَتَّىٰٓ إِذَا مَا جَآءُوهَا شَهِدَ عَلَيۡهِمۡ سَمۡعُهُمۡ وَأَبۡصَٰرُهُمۡ وَجُلُودُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Fussilat, Verse 20


وَقَالُواْ لِجُلُودِهِمۡ لِمَ شَهِدتُّمۡ عَلَيۡنَاۖ قَالُوٓاْ أَنطَقَنَا ٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَنطَقَ كُلَّ شَيۡءٖۚ وَهُوَ خَلَقَكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ

Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: "Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?" Wọ́n yóò sọ pé: "Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Fussilat, Verse 21


وَمَا كُنتُمۡ تَسۡتَتِرُونَ أَن يَشۡهَدَ عَلَيۡكُمۡ سَمۡعُكُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُكُمۡ وَلَا جُلُودُكُمۡ وَلَٰكِن ظَنَنتُمۡ أَنَّ ٱللَّهَ لَا يَعۡلَمُ كَثِيرٗا مِّمَّا تَعۡمَلُونَ

Ẹ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Fussilat, Verse 22


وَذَٰلِكُمۡ ظَنُّكُمُ ٱلَّذِي ظَنَنتُم بِرَبِّكُمۡ أَرۡدَىٰكُمۡ فَأَصۡبَحۡتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ

Ìyẹn, èrò yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò
Surah Fussilat, Verse 23


فَإِن يَصۡبِرُواْ فَٱلنَّارُ مَثۡوٗى لَّهُمۡۖ وَإِن يَسۡتَعۡتِبُواْ فَمَا هُم مِّنَ ٱلۡمُعۡتَبِينَ

Tí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣẹ́rí padà sí ṣíṣe ohun tí Allāhu yọ́nú sí (ní àsìkò yìí), A ò níí gbà wọ́n láyè láti ṣẹ́rí padà
Surah Fussilat, Verse 24


۞وَقَيَّضۡنَا لَهُمۡ قُرَنَآءَ فَزَيَّنُواْ لَهُم مَّا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ

Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn, tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ t’ó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò
Surah Fussilat, Verse 25


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَسۡمَعُواْ لِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَٱلۡغَوۡاْ فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَغۡلِبُونَ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí
Surah Fussilat, Verse 26


فَلَنُذِيقَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَذَابٗا شَدِيدٗا وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَسۡوَأَ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí t’ó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san
Surah Fussilat, Verse 27


ذَٰلِكَ جَزَآءُ أَعۡدَآءِ ٱللَّهِ ٱلنَّارُۖ لَهُمۡ فِيهَا دَارُ ٱلۡخُلۡدِ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ

Iná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa
Surah Fussilat, Verse 28


وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ رَبَّنَآ أَرِنَا ٱلَّذَيۡنِ أَضَلَّانَا مِنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِ نَجۡعَلۡهُمَا تَحۡتَ أَقۡدَامِنَا لِيَكُونَا مِنَ ٱلۡأَسۡفَلِينَ

Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá nítorí kí á lè fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ gìgísẹ̀ wa, nítorí kí wọ́n lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá
Surah Fussilat, Verse 29


إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ تَتَنَزَّلُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ أَلَّا تَخَافُواْ وَلَا تَحۡزَنُواْ وَأَبۡشِرُواْ بِٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ

Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín)
Surah Fussilat, Verse 30


نَحۡنُ أَوۡلِيَآؤُكُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَشۡتَهِيٓ أَنفُسُكُمۡ وَلَكُمۡ فِيهَا مَا تَدَّعُونَ

Àwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fun yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀
Surah Fussilat, Verse 31


نُزُلٗا مِّنۡ غَفُورٖ رَّحِيمٖ

N̄ǹkan ìgbàlejò ni láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Surah Fussilat, Verse 32


وَمَنۡ أَحۡسَنُ قَوۡلٗا مِّمَّن دَعَآ إِلَى ٱللَّهِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا وَقَالَ إِنَّنِي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ

Ta ni ó dára jùlọ ní ọ̀rọ̀ sísọ t’ó tayọ ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí
Surah Fussilat, Verse 33


وَلَا تَسۡتَوِي ٱلۡحَسَنَةُ وَلَا ٱلسَّيِّئَةُۚ ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ فَإِذَا ٱلَّذِي بَيۡنَكَ وَبَيۡنَهُۥ عَدَٰوَةٞ كَأَنَّهُۥ وَلِيٌّ حَمِيمٞ

Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú). Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí
Surah Fussilat, Verse 34


وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَمَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ذُو حَظٍّ عَظِيمٖ

A ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn t’ó ṣe sùúrù. A ò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá
Surah Fussilat, Verse 35


وَإِمَّا يَنزَغَنَّكَ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ نَزۡغٞ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ

Àti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ Èṣù bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀
Surah Fussilat, Verse 36


وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلَّيۡلُ وَٱلنَّهَارُ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُۚ لَا تَسۡجُدُواْ لِلشَّمۡسِ وَلَا لِلۡقَمَرِ وَٱسۡجُدُواْۤ لِلَّهِۤ ٱلَّذِي خَلَقَهُنَّ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ ò gbọdọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni t’ó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo
Surah Fussilat, Verse 37


فَإِنِ ٱسۡتَكۡبَرُواْ فَٱلَّذِينَ عِندَ رَبِّكَ يُسَبِّحُونَ لَهُۥ بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَهُمۡ لَا يَسۡـَٔمُونَ۩

Tí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn t’ó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara
Surah Fussilat, Verse 38


وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنَّكَ تَرَى ٱلۡأَرۡضَ خَٰشِعَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡۚ إِنَّ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاهَا لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ

Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Fussilat, Verse 39


إِنَّ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا لَا يَخۡفَوۡنَ عَلَيۡنَآۗ أَفَمَن يُلۡقَىٰ فِي ٱلنَّارِ خَيۡرٌ أَم مَّن يَأۡتِيٓ ءَامِنٗا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ٱعۡمَلُواْ مَا شِئۡتُمۡ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ

Dájúdájú àwọn t’ó ń yẹ àwọn āyah Wa (síbi òmíràn), wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Fussilat, Verse 40


إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلذِّكۡرِ لَمَّا جَآءَهُمۡۖ وَإِنَّهُۥ لَكِتَٰبٌ عَزِيزٞ

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà t’ó lágbára
Surah Fussilat, Verse 41


لَّا يَأۡتِيهِ ٱلۡبَٰطِلُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَلَا مِنۡ خَلۡفِهِۦۖ تَنزِيلٞ مِّنۡ حَكِيمٍ حَمِيدٖ

Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀. Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn
Surah Fussilat, Verse 42


مَّا يُقَالُ لَكَ إِلَّا مَا قَدۡ قِيلَ لِلرُّسُلِ مِن قَبۡلِكَۚ إِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغۡفِرَةٖ وَذُو عِقَابٍ أَلِيمٖ

Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀)
Surah Fussilat, Verse 43


وَلَوۡ جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا أَعۡجَمِيّٗا لَّقَالُواْ لَوۡلَا فُصِّلَتۡ ءَايَٰتُهُۥٓۖ ءَا۬عۡجَمِيّٞ وَعَرَبِيّٞۗ قُلۡ هُوَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ هُدٗى وَشِفَآءٞۚ وَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ فِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٞ وَهُوَ عَلَيۡهِمۡ عَمًىۚ أُوْلَـٰٓئِكَ يُنَادَوۡنَ مِن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ

Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?" Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad s.a.w.) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: "Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn. Fọ́júǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè t’ó jìnnà
Surah Fussilat, Verse 44


وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ

A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān
Surah Fussilat, Verse 45


مَّنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۗ وَمَا رَبُّكَ بِظَلَّـٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn
Surah Fussilat, Verse 46


۞إِلَيۡهِ يُرَدُّ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِۚ وَمَا تَخۡرُجُ مِن ثَمَرَٰتٖ مِّنۡ أَكۡمَامِهَا وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ أَيۡنَ شُرَكَآءِي قَالُوٓاْ ءَاذَنَّـٰكَ مَامِنَّا مِن شَهِيدٖ

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: "Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?" Wọ́n á wí pé: "Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé O ní akẹgbẹ́)
Surah Fussilat, Verse 47


وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَدۡعُونَ مِن قَبۡلُۖ وَظَنُّواْ مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ

Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé kò sí ibùsásí kan fún àwọn
Surah Fussilat, Verse 48


لَّا يَسۡـَٔمُ ٱلۡإِنسَٰنُ مِن دُعَآءِ ٱلۡخَيۡرِ وَإِن مَّسَّهُ ٱلشَّرُّ فَيَـُٔوسٞ قَنُوطٞ

Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná
Surah Fussilat, Verse 49


وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ رَحۡمَةٗ مِّنَّا مِنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّجِعۡتُ إِلَىٰ رَبِّيٓ إِنَّ لِي عِندَهُۥ لَلۡحُسۡنَىٰۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِمَا عَمِلُواْ وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ

Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: "Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀." Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà t’ó nípọn tọ́ wò
Surah Fussilat, Verse 50


وَإِذَآ أَنۡعَمۡنَا عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ أَعۡرَضَ وَنَـَٔا بِجَانِبِهِۦ وَإِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ فَذُو دُعَآءٍ عَرِيضٖ

Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ
Surah Fussilat, Verse 51


قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ثُمَّ كَفَرۡتُم بِهِۦ مَنۡ أَضَلُّ مِمَّنۡ هُوَ فِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)" Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa t’ó jìnnà (sí òdodo)
Surah Fussilat, Verse 52


سَنُرِيهِمۡ ءَايَٰتِنَا فِي ٱلۡأٓفَاقِ وَفِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمۡ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّۗ أَوَلَمۡ يَكۡفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ

A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Fussilat, Verse 53


أَلَآ إِنَّهُمۡ فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآءِ رَبِّهِمۡۗ أَلَآ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطُۢ

Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká
Surah Fussilat, Verse 54


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 40
>> Surah 42

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai