Surah Ash-Shura - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
حمٓ
Hā mīm
Surah Ash-Shura, Verse 1
عٓسٓقٓ
‘Aēn sīn ƙọ̄f
Surah Ash-Shura, Verse 2
كَذَٰلِكَ يُوحِيٓ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ
Surah Ash-Shura, Verse 3
لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ
TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ó ga, Ó tóbi
Surah Ash-Shura, Verse 4
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِن فَوۡقِهِنَّۚ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Sánmọ̀ fẹ́ẹ̀ fàya láti òkè wọn (nípa títóbi Allāhu). Àwọn mọlāika sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó wà lórí ilẹ̀. Gbọ́ Mi, dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Ash-Shura, Verse 5
وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهُ حَفِيظٌ عَلَيۡهِمۡ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٖ
Àwọn t’ó mú àwọn alátìlẹ́yìn kan lẹ́yìn Rẹ̀, Allāhu sì ni Aláàbò lórí wọn. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn
Surah Ash-Shura, Verse 6
وَكَذَٰلِكَ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّتُنذِرَ أُمَّ ٱلۡقُرَىٰ وَمَنۡ حَوۡلَهَا وَتُنذِرَ يَوۡمَ ٱلۡجَمۡعِ لَا رَيۡبَ فِيهِۚ فَرِيقٞ فِي ٱلۡجَنَّةِ وَفَرِيقٞ فِي ٱلسَّعِيرِ
Báyẹn ni A ṣe fi al-Ƙur’ān ránṣẹ́ sí ọ ní èdè Lárúbáwá nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù), àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ nípa Ọjọ́ Àkójọ, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìjọ kan yóò wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìjọ kan yó sì wà nínú Iná t’ó ń jò
Surah Ash-Shura, Verse 7
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَهُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُدۡخِلُ مَن يَشَآءُ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ وَٱلظَّـٰلِمُونَ مَا لَهُم مِّن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe wọ́n ní ìjọ ẹlẹ́sìn ẹyọ kan. Ṣùgbọ́n Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Àwọn alábòsí, kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 8
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَۖ فَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡوَلِيُّ وَهُوَ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Ash-Shura, Verse 9
وَمَا ٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِيهِ مِن شَيۡءٖ فَحُكۡمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّي عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ
Ohunkóhun tí ẹ bá yapa ẹnu nípa rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah t’ó ń pa wá láṣẹ láti fi al-Ƙur’an àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yanjú àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu
Surah Ash-Shura, Verse 10
فَاطِرُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ أَزۡوَٰجٗا يَذۡرَؤُكُمۡ فِيهِۚ لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ
(Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fun yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran
Surah Ash-Shura, Verse 11
لَهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ àpótí-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan
Surah Ash-Shura, Verse 12
۞شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ
(Allāhu) ṣe ní òfin fun yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà)
Surah Ash-Shura, Verse 13
وَمَا تَفَرَّقُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى لَّقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُورِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ
(Àwọn ọ̀ṣẹbọ) kò sì pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tí ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (pé Òun yóò lọ́ wọn lára) títí di gbèdéke àkókò kan ni, Wọn ìbá ti dájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú àwọn tí A jogún Tírà fún lẹ́yìn wọn sì tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ’Islām
Surah Ash-Shura, Verse 14
فَلِذَٰلِكَ فَٱدۡعُۖ وَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡۖ وَقُلۡ ءَامَنتُ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِن كِتَٰبٖۖ وَأُمِرۡتُ لِأَعۡدِلَ بَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡۖ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡۖ لَا حُجَّةَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Nítorí ìyẹn, pèpè (sínú ’Islām), kí o sì dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Wọ́n ṣe pa ọ́ lásẹ. Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Kí o sì sọ pé: "Mo gbàgbọ́ nínú èyíkéyìí Tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Wọ́n sì pa mí láṣẹ pé kí n̄g ṣe déédé láààrin yín. Allāhu ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kò sí ìjà láààrin àwa àti ẹ̀yin. Allāhu l’Ó sì máa kó wa jọ papọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ní àbọ̀ ẹ̀dá.”
Surah Ash-Shura, Verse 15
وَٱلَّذِينَ يُحَآجُّونَ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ٱسۡتُجِيبَ لَهُۥ حُجَّتُهُمۡ دَاحِضَةٌ عِندَ رَبِّهِمۡ وَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ وَلَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٌ
Àwọn t’ó ń bá (Ànábì s.a.w.) jà nípa (ẹ̀sìn) Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ènìyàn ti gbà fún un, ẹ̀rí wọn máa wó lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbínú ń bẹ lórí wọn. Ìyà líle sì wà fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 16
ٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ وَٱلۡمِيزَانَۗ وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّ ٱلسَّاعَةَ قَرِيبٞ
Allāhu ni Ẹni tí Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) àti (òfin) òṣùwọ̀n (déédé) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́
Surah Ash-Shura, Verse 17
يَسۡتَعۡجِلُ بِهَا ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِهَاۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مُشۡفِقُونَ مِنۡهَا وَيَعۡلَمُونَ أَنَّهَا ٱلۡحَقُّۗ أَلَآ إِنَّ ٱلَّذِينَ يُمَارُونَ فِي ٱلسَّاعَةِ لَفِي ضَلَٰلِۭ بَعِيدٍ
Àwọn tí kò gbà á gbọ́ ń wá a pẹ̀lú ìkánjú. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo ń páyà rẹ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni. Kíyè sí i, dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa Àkókò náà ti wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà
Surah Ash-Shura, Verse 18
ٱللَّهُ لَطِيفُۢ بِعِبَادِهِۦ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُۖ وَهُوَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡعَزِيزُ
Allāhu ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Abiyì
Surah Ash-Shura, Verse 19
مَن كَانَ يُرِيدُ حَرۡثَ ٱلۡأٓخِرَةِ نَزِدۡ لَهُۥ فِي حَرۡثِهِۦۖ وَمَن كَانَ يُرِيدُ حَرۡثَ ٱلدُّنۡيَا نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَا وَمَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِن نَّصِيبٍ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ọ̀run, A máa ṣe àlékún sí èso rẹ̀ fún un. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀. Kò sì níí sí ìpín kan kan fún un mọ́ ní ọ̀run
Surah Ash-Shura, Verse 20
أَمۡ لَهُمۡ شُرَكَـٰٓؤُاْ شَرَعُواْ لَهُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا لَمۡ يَأۡذَنۢ بِهِ ٱللَّهُۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةُ ٱلۡفَصۡلِ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۗ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan t’ó ṣòfin (ìbọ̀rìṣà) fún wọn nínú ẹ̀sìn, èyí tí Allāhu kò yọ̀ǹda rẹ̀? Tí kò bá jẹ́ ti ọ̀rọ̀ àsọyán (pé A ò níí kánjú jẹ wọ́n níyà), Àwa ìbá ti mú ìdájọ́ wá láààrin wọn. Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 21
تَرَى ٱلظَّـٰلِمِينَ مُشۡفِقِينَ مِمَّا كَسَبُواْ وَهُوَ وَاقِعُۢ بِهِمۡۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فِي رَوۡضَاتِ ٱلۡجَنَّاتِۖ لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمۡۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَضۡلُ ٱلۡكَبِيرُ
O máa rí àwọn alábòsí tí wọn yóò máa páyà nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, tí ó sì máa kò lé wọn lórí. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere máa wà ní àwọn àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn, òhun ni oore àjùlọ t’ó tóbi
Surah Ash-Shura, Verse 22
ذَٰلِكَ ٱلَّذِي يُبَشِّرُ ٱللَّهُ عِبَادَهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِۗ قُل لَّآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًا إِلَّا ٱلۡمَوَدَّةَ فِي ٱلۡقُرۡبَىٰۗ وَمَن يَقۡتَرِفۡ حَسَنَةٗ نَّزِدۡ لَهُۥ فِيهَا حُسۡنًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ شَكُورٌ
Ìyẹn ni èyí tí Allāhu fi ń ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Sọ pé: "Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ bí kò ṣe ìfẹ́ ẹbí.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe rere kan, A máa ṣe àlékún rere fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́
Surah Ash-Shura, Verse 23
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗاۖ فَإِن يَشَإِ ٱللَّهُ يَخۡتِمۡ عَلَىٰ قَلۡبِكَۗ وَيَمۡحُ ٱللَّهُ ٱلۡبَٰطِلَ وَيُحِقُّ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni?" Nítorí náà, tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa fi èdídí dí ọkàn rẹ pa. Àti pé Allāhu yóò pa irọ́ rẹ́. Ó sì máa fi òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá
Surah Ash-Shura, Verse 24
وَهُوَ ٱلَّذِي يَقۡبَلُ ٱلتَّوۡبَةَ عَنۡ عِبَادِهِۦ وَيَعۡفُواْ عَنِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ وَيَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ
Òun ni Ẹni t’Ó ń gba ìronúpìwàdà àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe àmójúkúrò níbi àwọn àṣìṣe. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Ash-Shura, Verse 25
وَيَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضۡلِهِۦۚ وَٱلۡكَٰفِرُونَ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞ
Ó ń gba àdúà àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ó sì ń ṣe àlékún fún wọn nínú ọlá Rẹ̀. Àwọn aláìgbàgbọ́, ìyà líle sì wà fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 26
۞وَلَوۡ بَسَطَ ٱللَّهُ ٱلرِّزۡقَ لِعِبَادِهِۦ لَبَغَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِن يُنَزِّلُ بِقَدَرٖ مَّا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرُۢ بَصِيرٞ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni, wọn ìbá tayọ ẹnu-àlà lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń sọ (arísìkí) tí Ó bá fẹ́ kalẹ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀
Surah Ash-Shura, Verse 27
وَهُوَ ٱلَّذِي يُنَزِّلُ ٱلۡغَيۡثَ مِنۢ بَعۡدِ مَا قَنَطُواْ وَيَنشُرُ رَحۡمَتَهُۥۚ وَهُوَ ٱلۡوَلِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
Òun sì ni Ẹni t’Ó ń sọ omi òjò kalẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti sọ̀rètí nù. Ó sì ń fọ́n ìkẹ́ Rẹ̀ ká. Òun sì ni Aláàbò, Ẹlẹ́yìn
Surah Ash-Shura, Verse 28
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَثَّ فِيهِمَا مِن دَآبَّةٖۚ وَهُوَ عَلَىٰ جَمۡعِهِمۡ إِذَا يَشَآءُ قَدِيرٞ
Àti pé nínú àmì Rẹ̀ ni ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tí Ó fọ́nká sáààrin méjèèjì nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí. Òun sì ni Alágbára lórí ìkójọ wọn nígbà tí Ó bá fẹ́
Surah Ash-Shura, Verse 29
وَمَآ أَصَٰبَكُم مِّن مُّصِيبَةٖ فَبِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَيَعۡفُواْ عَن كَثِيرٖ
Ohunkóhun tí ó bá kàn yín nínú àdánwò, ohun tí ẹ fi ọwọ́ ara yín fà ni. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀
Surah Ash-Shura, Verse 30
وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ
Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́ (mọ́ Allāhu lọ́wọ́) lórí ilẹ̀. Kò sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu
Surah Ash-Shura, Verse 31
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلۡجَوَارِ فِي ٱلۡبَحۡرِ كَٱلۡأَعۡلَٰمِ
Ó tún wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn lójú omi (t’ó dà) bí àwọn òkè àpáta gíga
Surah Ash-Shura, Verse 32
إِن يَشَأۡ يُسۡكِنِ ٱلرِّيحَ فَيَظۡلَلۡنَ رَوَاكِدَ عَلَىٰ ظَهۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٍ
Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa mú atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa di ohun tí kò níí lọ mọ́ lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́
Surah Ash-Shura, Verse 33
أَوۡ يُوبِقۡهُنَّ بِمَا كَسَبُواْ وَيَعۡفُ عَن كَثِيرٖ
Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa mú atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa di ohun tí kò níí lọ mọ́ lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́
Surah Ash-Shura, Verse 34
وَيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ
Àwọn t’ó ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa sì máa mọ̀ pé kò sí ibùsásí kan fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 35
فَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
Nítorí náà, ohunkóhun tí A bá fun yín, ìgbádùn ayé nìkan ni. Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa ṣẹ́kù títí láéláé fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn
Surah Ash-Shura, Verse 36
وَٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَـٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُواْ هُمۡ يَغۡفِرُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn t’ó ń jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá àti àwọn ìwà ìbàjẹ́, àti (àwọn t’ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá bínú, wọ́n yóò ṣàforíjìn
Surah Ash-Shura, Verse 37
وَٱلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِرَبِّهِمۡ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَمۡرُهُمۡ شُورَىٰ بَيۡنَهُمۡ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn t’ó jẹ́pè ti Olúwa wọn, tí wọ́n ń kírun, ọ̀rọ̀ ara wọn sì jẹ́ ìjíròrò láààrin ara wọn, wọ́n tún ń ná nínú arísìkí tí A pèsè fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 38
وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَابَهُمُ ٱلۡبَغۡيُ هُمۡ يَنتَصِرُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí wọn, wọn yóò gbẹ̀san wọn padà
Surah Ash-Shura, Verse 39
وَجَزَـٰٓؤُاْ سَيِّئَةٖ سَيِّئَةٞ مِّثۡلُهَاۖ فَمَنۡ عَفَا وَأَصۡلَحَ فَأَجۡرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàmójúkúrò, tí ó tún ṣàtúnṣe, ẹ̀san rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí
Surah Ash-Shura, Verse 40
وَلَمَنِ ٱنتَصَرَ بَعۡدَ ظُلۡمِهِۦ فَأُوْلَـٰٓئِكَ مَا عَلَيۡهِم مِّن سَبِيلٍ
Dájúdájú ẹni tí ó bá sì gbẹ̀san lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àbòsí sí i, àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ṣàbòsí sí), kò sí ìbáwí kan kan fún wọn
Surah Ash-Shura, Verse 41
إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَظۡلِمُونَ ٱلنَّاسَ وَيَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn t’ó ń ṣàbòsí sí àwọn ènìyàn, tí wọ́n tún ń tayọ ẹnu-àlà lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún
Surah Ash-Shura, Verse 42
وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe sùúrù, tí ó tún ṣàforíjìn, dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan
Surah Ash-Shura, Verse 43
وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن وَلِيّٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَتَرَى ٱلظَّـٰلِمِينَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَ يَقُولُونَ هَلۡ إِلَىٰ مَرَدّٖ مِّن سَبِيلٖ
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò tún sí aláàbò kan fún un mọ́ lẹ́yìn Rẹ̀. O sì máa rí àwọn alábòsí nígbà tí wọ́n bá rí Iná, wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ ọ̀nà kan kan wà tí a lè fi padà sí ilé ayé
Surah Ash-Shura, Verse 44
وَتَرَىٰهُمۡ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا خَٰشِعِينَ مِنَ ٱلذُّلِّ يَنظُرُونَ مِن طَرۡفٍ خَفِيّٖۗ وَقَالَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ فِي عَذَابٖ مُّقِيمٖ
O sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde." Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére
Surah Ash-Shura, Verse 45
وَمَا كَانَ لَهُم مِّنۡ أَوۡلِيَآءَ يَنصُرُونَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن سَبِيلٍ
Kò sì níí sí aláàbò kan fún wọn tí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Àti pé ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí ọ̀nà kan kan fún un
Surah Ash-Shura, Verse 46
ٱسۡتَجِيبُواْ لِرَبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۚ مَا لَكُم مِّن مَّلۡجَإٖ يَوۡمَئِذٖ وَمَا لَكُم مِّن نَّكِيرٖ
Ẹ jẹ́pè Olúwa yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó de, tí kò sí ìdápadà kan fún un ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Kò sí ibùsásí kan fun yín ní ọjọ́ yẹn. Kò sì níí sí olùkọ̀yà kan fun yín
Surah Ash-Shura, Verse 47
فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظًاۖ إِنۡ عَلَيۡكَ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُۗ وَإِنَّآ إِذَآ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ فَرِحَ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ فَإِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ كَفُورٞ
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, A ò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ fún wọn. Kò sí kiní kan t’ó di dandan fún ọ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́. Àti pé dájúdájú nígbà tí A bá fún ènìyàn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn án nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọn tì ṣíwájú (ní iṣẹ́ aburú), dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore
Surah Ash-Shura, Verse 48
لِّلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ يَهَبُ لِمَن يَشَآءُ إِنَٰثٗا وَيَهَبُ لِمَن يَشَآءُ ٱلذُّكُورَ
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọbìnrin. Ó sì ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ ní lọ́rẹ ọmọkùnrin
Surah Ash-Shura, Verse 49
أَوۡ يُزَوِّجُهُمۡ ذُكۡرَانٗا وَإِنَٰثٗاۖ وَيَجۡعَلُ مَن يَشَآءُ عَقِيمًاۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٞ قَدِيرٞ
Tàbí kí Ó ṣe wọ́n ní oríṣi méjì; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó sì ń ṣe ẹni tí Ó bá fẹ́ ní àgàn. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀, Alágbára
Surah Ash-Shura, Verse 50
۞وَمَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُكَلِّمَهُ ٱللَّهُ إِلَّا وَحۡيًا أَوۡ مِن وَرَآيِٕ حِجَابٍ أَوۡ يُرۡسِلَ رَسُولٗا فَيُوحِيَ بِإِذۡنِهِۦ مَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ عَلِيٌّ حَكِيمٞ
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan pé kí Allāhu bá a sọ̀rọ̀ àfi kí (ọ̀rọ̀ náà) jẹ́ ìmísí (ìṣípayá mímọ́), tàbí kí ó jẹ́ lẹ́yìn gàgá, tàbí kí Ó rán Òjíṣẹ́ kan (tí)
Surah Ash-Shura, Verse 51
وَكَذَٰلِكَ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ رُوحٗا مِّنۡ أَمۡرِنَاۚ مَا كُنتَ تَدۡرِي مَا ٱلۡكِتَٰبُ وَلَا ٱلۡإِيمَٰنُ وَلَٰكِن جَعَلۡنَٰهُ نُورٗا نَّهۡدِي بِهِۦ مَن نَّشَآءُ مِنۡ عِبَادِنَاۚ وَإِنَّكَ لَتَهۡدِيٓ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),1 ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām). 2 iṣẹ́ wiridi ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń ṣe nínú ọ̀gbun Hirā ṣíwájú kí ó tó di Ànábì Ọlọ́hun irọ́ l’ó fi pa. Ìdí ni pé
Surah Ash-Shura, Verse 52
صِرَٰطِ ٱللَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِلَى ٱللَّهِ تَصِيرُ ٱلۡأُمُورُ
Ọ̀nà Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Gbọ́! Ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá yóò padà sí
Surah Ash-Shura, Verse 53