Surah Ad-Dukhan - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
حمٓ
Ha mim
Surah Ad-Dukhan, Verse 1
وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
(Allahu) bura pelu Tira t’o yanju oro eda
Surah Ad-Dukhan, Verse 2
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةٖ مُّبَٰرَكَةٍۚ إِنَّا كُنَّا مُنذِرِينَ
Dajudaju Awa so o kale ninu oru ibukun. Dajudaju Awa n je Olukilo
Surah Ad-Dukhan, Verse 3
فِيهَا يُفۡرَقُ كُلُّ أَمۡرٍ حَكِيمٍ
Ninu oru naa ni won ti maa yanju gbogbo oro ti ko nii tase (lori eda)
Surah Ad-Dukhan, Verse 4
أَمۡرٗا مِّنۡ عِندِنَآۚ إِنَّا كُنَّا مُرۡسِلِينَ
Ase kan ni lati odo Wa. Dajudaju Awa l’A n ran awon Ojise nise
Surah Ad-Dukhan, Verse 5
رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Ike kan ni lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo
Surah Ad-Dukhan, Verse 6
رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَآۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ
Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji ti eyin ba je alamodaju
Surah Ad-Dukhan, Verse 7
لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ رَبُّكُمۡ وَرَبُّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko
Surah Ad-Dukhan, Verse 8
بَلۡ هُمۡ فِي شَكّٖ يَلۡعَبُونَ
Sibe, won si wa ninu iyemeji, ti won n sere
Surah Ad-Dukhan, Verse 9
فَٱرۡتَقِبۡ يَوۡمَ تَأۡتِي ٱلسَّمَآءُ بِدُخَانٖ مُّبِينٖ
Nitori naa, maa reti ojo ti sanmo yoo mu eefin ponnbele wa
Surah Ad-Dukhan, Verse 10
يَغۡشَى ٱلنَّاسَۖ هَٰذَا عَذَابٌ أَلِيمٞ
O maa bo awon eniyan mole. Eyi ni iya eleta-elero
Surah Ad-Dukhan, Verse 11
رَّبَّنَا ٱكۡشِفۡ عَنَّا ٱلۡعَذَابَ إِنَّا مُؤۡمِنُونَ
(Awon eniyan yoo wi pe): Oluwa wa, gbe iya naa kuro fun wa, dajudaju awa yoo gbagbo ni ododo
Surah Ad-Dukhan, Verse 12
أَنَّىٰ لَهُمُ ٱلذِّكۡرَىٰ وَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مُّبِينٞ
Bawo ni iranti se le wulo fun won (lasiko iya)? Ojise ponnbele kuku ti de ba won
Surah Ad-Dukhan, Verse 13
ثُمَّ تَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ وَقَالُواْ مُعَلَّمٞ مَّجۡنُونٌ
Leyin naa, won gbunri kuro ni odo re. Won si wi pe: "Were ti eniyan kan n ko ni eko ni
Surah Ad-Dukhan, Verse 14
إِنَّا كَاشِفُواْ ٱلۡعَذَابِ قَلِيلًاۚ إِنَّكُمۡ عَآئِدُونَ
Dajudaju Awa maa gbe iya naa kuro fun igba die. Dajudaju eyin yoo tun pada (sinu aigbagbo)
Surah Ad-Dukhan, Verse 15
يَوۡمَ نَبۡطِشُ ٱلۡبَطۡشَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰٓ إِنَّا مُنتَقِمُونَ
Ojo ti A oo gba (won mu) ni igbamu t’o tobi julo; dajudaju Awa yoo gba esan iya (lara won)
Surah Ad-Dukhan, Verse 16
۞وَلَقَدۡ فَتَنَّا قَبۡلَهُمۡ قَوۡمَ فِرۡعَوۡنَ وَجَآءَهُمۡ رَسُولٞ كَرِيمٌ
Dajudaju A dan awon eniyan Fir‘aon wo siwaju won. Ojise alapon-onle si de wa ba won
Surah Ad-Dukhan, Verse 17
أَنۡ أَدُّوٓاْ إِلَيَّ عِبَادَ ٱللَّهِۖ إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ
(O so pe): “E ko awon erusin Allahu le mi lowo. Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
Surah Ad-Dukhan, Verse 18
وَأَن لَّا تَعۡلُواْ عَلَى ٱللَّهِۖ إِنِّيٓ ءَاتِيكُم بِسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٖ
E ma se segberaga si Allahu. Dajudaju emi ti mu eri ponnbele wa ba yin
Surah Ad-Dukhan, Verse 19
وَإِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُمۡ أَن تَرۡجُمُونِ
Dajudaju Emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin pe ki e ma se so mi loko pa
Surah Ad-Dukhan, Verse 20
وَإِن لَّمۡ تُؤۡمِنُواْ لِي فَٱعۡتَزِلُونِ
Ti e ko ba si gba mi gbo, e fi mi sile je
Surah Ad-Dukhan, Verse 21
فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٞ مُّجۡرِمُونَ
Nitori naa, o pe Oluwa re pe dajudaju awon wonyi ni ijo elese
Surah Ad-Dukhan, Verse 22
فَأَسۡرِ بِعِبَادِي لَيۡلًا إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ
(Allahu so pe): "Mu awon erusin Mi rin ni ale (nitori pe) won yoo to yin leyin
Surah Ad-Dukhan, Verse 23
وَٱتۡرُكِ ٱلۡبَحۡرَ رَهۡوًاۖ إِنَّهُمۡ جُندٞ مُّغۡرَقُونَ
Ki o si fi agbami odo sile ni yiyanu sile bee. Dajudaju awon ni omo ogun ti A maa teri sinu agbami
Surah Ad-Dukhan, Verse 24
كَمۡ تَرَكُواْ مِن جَنَّـٰتٖ وَعُيُونٖ
Meloo meloo ninu awon ogba oko ati odo iseleru ti won fi sile (leyin iparun won)
Surah Ad-Dukhan, Verse 25
وَزُرُوعٖ وَمَقَامٖ كَرِيمٖ
Ati awon irugbin pelu aye aponle (ti won fi sile)
Surah Ad-Dukhan, Verse 26
وَنَعۡمَةٖ كَانُواْ فِيهَا فَٰكِهِينَ
Ati idera ti won n gbadun ninu re (siwaju iparun won)
Surah Ad-Dukhan, Verse 27
كَذَٰلِكَۖ وَأَوۡرَثۡنَٰهَا قَوۡمًا ءَاخَرِينَ
Bayen (ni oro won se ri). A si jogun (ilu) won fun ijo eniyan miiran
Surah Ad-Dukhan, Verse 28
فَمَا بَكَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّمَآءُ وَٱلۡأَرۡضُ وَمَا كَانُواْ مُنظَرِينَ
Nigba naa, sanmo ati ile ko sunkun won. Won ko si fi iya won fale
Surah Ad-Dukhan, Verse 29
وَلَقَدۡ نَجَّيۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ مِنَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡمُهِينِ
Dajudaju A gba awon omo ’Isro’il la ninu iya yepere
Surah Ad-Dukhan, Verse 30
مِن فِرۡعَوۡنَۚ إِنَّهُۥ كَانَ عَالِيٗا مِّنَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ
(A la won) lowo Fir‘aon. Dajudaju o je onigbeeraga. O si wa ninu awon alakoyo
Surah Ad-Dukhan, Verse 31
وَلَقَدِ ٱخۡتَرۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ عِلۡمٍ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ
A kuku sa won lesa lori awon eda (asiko tiwon) pelu imo
Surah Ad-Dukhan, Verse 32
وَءَاتَيۡنَٰهُم مِّنَ ٱلۡأٓيَٰتِ مَا فِيهِ بَلَـٰٓؤٞاْ مُّبِينٌ
A si fun won ni awon ami ti adanwo ponnbele wa ninu re
Surah Ad-Dukhan, Verse 33
إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ لَيَقُولُونَ
Dajudaju awon wonyi n wi pe
Surah Ad-Dukhan, Verse 34
إِنۡ هِيَ إِلَّا مَوۡتَتُنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُنشَرِينَ
Ko si iku kan ayafi iku akoko (ti o pa wa nile aye). Won ko si nii gbe wa dide
Surah Ad-Dukhan, Verse 35
فَأۡتُواْ بِـَٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
(Bi bee ko), e mu awon baba wa wa ti e ba je olododo
Surah Ad-Dukhan, Verse 36
أَهُمۡ خَيۡرٌ أَمۡ قَوۡمُ تُبَّعٖ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ مُجۡرِمِينَ
Se awon ni won loore julo ni tabi awon eniyan Tubba‘u ati awon t’o siwaju won? A pa won re; dajudaju won je elese
Surah Ad-Dukhan, Verse 37
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا لَٰعِبِينَ
A ko seda awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji pelu ere sise
Surah Ad-Dukhan, Verse 38
مَا خَلَقۡنَٰهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
A ko da awon mejeeji bi ko se pelu ododo, sugbon opolopo won ni ko mo
Surah Ad-Dukhan, Verse 39
إِنَّ يَوۡمَ ٱلۡفَصۡلِ مِيقَٰتُهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Dajudaju ojo opinya (iyen, ojo ajinde) ni akoko adehun fun gbogbo won patapata
Surah Ad-Dukhan, Verse 40
يَوۡمَ لَا يُغۡنِي مَوۡلًى عَن مَّوۡلٗى شَيۡـٔٗا وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ
Ni ojo ti ore kan ko nii fi kini kan ro ore kan loro. A o si nii ran won lowo
Surah Ad-Dukhan, Verse 41
إِلَّا مَن رَّحِمَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ
Ayafi eni ti Allahu ba ke. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Asake-orun
Surah Ad-Dukhan, Verse 42
إِنَّ شَجَرَتَ ٱلزَّقُّومِ
Dajudaju igi zaƙum
Surah Ad-Dukhan, Verse 43
طَعَامُ ٱلۡأَثِيمِ
ni ounje elese
Surah Ad-Dukhan, Verse 44
كَٱلۡمُهۡلِ يَغۡلِي فِي ٱلۡبُطُونِ
O da bi epo gbigba ti n ho ninu ikun
Surah Ad-Dukhan, Verse 45
كَغَلۡيِ ٱلۡحَمِيمِ
(t’o) da bi hiho omi gbigbona
Surah Ad-Dukhan, Verse 46
خُذُوهُ فَٱعۡتِلُوهُ إِلَىٰ سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ
E mu un. Ki e wo o saarin gbungbun inu ina Jehim
Surah Ad-Dukhan, Verse 47
ثُمَّ صُبُّواْ فَوۡقَ رَأۡسِهِۦ مِنۡ عَذَابِ ٱلۡحَمِيمِ
Leyin naa, e ro iya olomi gbigbona le e lori
Surah Ad-Dukhan, Verse 48
ذُقۡ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡكَرِيمُ
To o wo (sebi) dajudaju iwo ni alagbara, alapon-onle (gege bi o se pe ara re)
Surah Ad-Dukhan, Verse 49
إِنَّ هَٰذَا مَا كُنتُم بِهِۦ تَمۡتَرُونَ
Dajudaju (iya) eyi ni nnkan ti e n seyemeji nipa re
Surah Ad-Dukhan, Verse 50
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي مَقَامٍ أَمِينٖ
Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa ni aye ifayabale
Surah Ad-Dukhan, Verse 51
فِي جَنَّـٰتٖ وَعُيُونٖ
(Won yoo wa) ninu awon Ogba Idera pelu awon omi iseleru (ni isale re)
Surah Ad-Dukhan, Verse 52
يَلۡبَسُونَ مِن سُندُسٖ وَإِسۡتَبۡرَقٖ مُّتَقَٰبِلِينَ
Won yoo maa wo aso aran felefele ati aran t’o nipon; won yo si maa koju sira won
Surah Ad-Dukhan, Verse 53
كَذَٰلِكَ وَزَوَّجۡنَٰهُم بِحُورٍ عِينٖ
Bayen (ni oro won yo se ri). A si maa fi awon obinrin eleyinju-ege se iyawo fun won
Surah Ad-Dukhan, Verse 54
يَدۡعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَٰكِهَةٍ ءَامِنِينَ
Won yoo maa beere fun gbogbo nnkan eleso ninu (Ogba Idera) pelu ifayabale
Surah Ad-Dukhan, Verse 55
لَا يَذُوقُونَ فِيهَا ٱلۡمَوۡتَ إِلَّا ٱلۡمَوۡتَةَ ٱلۡأُولَىٰۖ وَوَقَىٰهُمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ
Won ko nii to iku wo nibe ayafi iku akoko (ti won ti ku nile aye). (Allahu) si maa so won nibi iya ina Jehim
Surah Ad-Dukhan, Verse 56
فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكَۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
O je oore ajulo lati odo Oluwa re. Iyen ni erenje nla
Surah Ad-Dukhan, Verse 57
فَإِنَّمَا يَسَّرۡنَٰهُ بِلِسَانِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
Nitori naa, A se (al-Ƙur’an) ni irorun lori ahon re nitori ki won le lo iranti
Surah Ad-Dukhan, Verse 58
فَٱرۡتَقِبۡ إِنَّهُم مُّرۡتَقِبُونَ
Nitori naa, maa reti . Dajudaju awon naa n reti
Surah Ad-Dukhan, Verse 59