Surah Al-Jathiya - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
حمٓ
Ha mim
Surah Al-Jathiya, Verse 1
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
Surah Al-Jathiya, Verse 2
إِنَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ
Dajudaju ninu awon sanmo ati ile awon ami wa (ninu won) fun awon onigbagbo ododo
Surah Al-Jathiya, Verse 3
وَفِي خَلۡقِكُمۡ وَمَا يَبُثُّ مِن دَآبَّةٍ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ
Awon ami wa ninu iseda yin ati ohun ti Allahu n fonka (sori ile) ninu awon nnkan abemi; (ami wa ninu won) fun ijo t’o ni amodaju
Surah Al-Jathiya, Verse 4
وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن رِّزۡقٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
(Ninu) itelentele ati iyato oru ati osan, ati ohun ti Allahu n sokale ni arisiki, ti O n fi so ile di aye leyin t’o ti ku ati iyipada ategun, awon ami tun wa (ninu won) fun ijo t’o ni laakaye
Surah Al-Jathiya, Verse 5
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَ ٱللَّهِ وَءَايَٰتِهِۦ يُؤۡمِنُونَ
Iwonyi ni awon ayah Allahu ti A n ke (ni keu) fun o pelu ododo. Nitori naa, oro wo leyin (oro) Allahu ati awon ami Re ni won yoo tun gbagbo
Surah Al-Jathiya, Verse 6
وَيۡلٞ لِّكُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٖ
Egbe ni fun aladaapaaro, elese
Surah Al-Jathiya, Verse 7
يَسۡمَعُ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ثُمَّ يُصِرُّ مُسۡتَكۡبِرٗا كَأَن لَّمۡ يَسۡمَعۡهَاۖ فَبَشِّرۡهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٖ
t’o n gbo awon ayah Allahu, ti won n ke e fun un, leyin naa, ti o (tun) taku ni ti igberaga bi eni pe ko gbo o. Fun un ni iro iya eleta-elero
Surah Al-Jathiya, Verse 8
وَإِذَا عَلِمَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا شَيۡـًٔا ٱتَّخَذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Nigba ti o ba nimo nipa kini kan ninu awon ayah Wa, o maa mu un ni nnkan yeye. Awon wonyen ni iya ti i yepere eda n be fun
Surah Al-Jathiya, Verse 9
مِّن وَرَآئِهِمۡ جَهَنَّمُۖ وَلَا يُغۡنِي عَنۡهُم مَّا كَسَبُواْ شَيۡـٔٗا وَلَا مَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡلِيَآءَۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ina Jahanamo wa niwaju won. Ohun ti won se nise ati ohun ti won mu ni alaabo leyin Allahu ko si nii ro won loro kan nibi iya. Iya nla si wa fun won
Surah Al-Jathiya, Verse 10
هَٰذَا هُدٗىۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَهُمۡ عَذَابٞ مِّن رِّجۡزٍ أَلِيمٌ
Eyi ni imona. Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won, iya elegbin eleta-elero wa fun won
Surah Al-Jathiya, Verse 11
۞ٱللَّهُ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡبَحۡرَ لِتَجۡرِيَ ٱلۡفُلۡكُ فِيهِ بِأَمۡرِهِۦ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allahu ni Eni ti O ro agbami odo fun yin nitori ki awon oko oju-omi le rin ninu re pelu ase Re ati nitori ki e tun le wa ninu oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Un)
Surah Al-Jathiya, Verse 12
وَسَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مِّنۡهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
O tun ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile patapata fun yin lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
Surah Al-Jathiya, Verse 13
قُل لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَغۡفِرُواْ لِلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ أَيَّامَ ٱللَّهِ لِيَجۡزِيَ قَوۡمَۢا بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
So fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki won samoju kuro fun awon ti ko reti awon ojo (ti) Allahu (yoo se aranse fun awon onigbagbo ododo) nitori ki O le san esan fun ijo kan nipa ohun ti won n se nise
Surah Al-Jathiya, Verse 14
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ
Enikeni ti o ba se ise rere, fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si se ise aburu, fun emi ara re ni. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won yoo da yin pada si
Surah Al-Jathiya, Verse 15
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَفَضَّلۡنَٰهُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ
Dajudaju A fun awon omo ’Isro’il ni Tira ati idajo sise pelu ipo Anabi. A si se arisiki fun won ninu awon nnkan daadaa. A si soore ajulo fun won lori awon eda (asiko won)
Surah Al-Jathiya, Verse 16
وَءَاتَيۡنَٰهُم بَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِۖ فَمَا ٱخۡتَلَفُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
A tun fun won ni awon eri t’o yanju nipa oro naa. Nitori naa, won ko pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Dajudaju Oluwa re l’O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa nnkan ti won n yapa enu si
Surah Al-Jathiya, Verse 17
ثُمَّ جَعَلۡنَٰكَ عَلَىٰ شَرِيعَةٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ فَٱتَّبِعۡهَا وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ
Leyin naa, A fi o si oju ona kan ninu oro (esin ’Islam). Nitori naa, tele e. Ki o si ma se tele ife-inu awon ti ko nimo
Surah Al-Jathiya, Verse 18
إِنَّهُمۡ لَن يُغۡنُواْ عَنكَ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۚ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۖ وَٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلۡمُتَّقِينَ
Dajudaju won ko le ro o loro kini kan nibi iya ni odo Allahu. Ati pe dajudaju awon alabosi, apa kan won lore apa kan. Allahu si ni Ore awon oluberu (Re)
Surah Al-Jathiya, Verse 19
هَٰذَا بَصَـٰٓئِرُ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ
Eyi ni itosona fun awon eniyan. Imona ati ike ni fun ijo t’o ni amodaju
Surah Al-Jathiya, Verse 20
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ ٱجۡتَرَحُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن نَّجۡعَلَهُمۡ كَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ سَوَآءٗ مَّحۡيَاهُمۡ وَمَمَاتُهُمۡۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ
Tabi awon t’o n se ise aburu lero pe A maa se won gege bi (A ti se) awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ki isemi aye won ati iku won ri bakan naa? Ohun ti won n da lejo buru
Surah Al-Jathiya, Verse 21
وَخَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّ وَلِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo ati nitori ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise. A o si nii se abosi si won
Surah Al-Jathiya, Verse 22
أَفَرَءَيۡتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَٰهَهُۥ هَوَىٰهُ وَأَضَلَّهُ ٱللَّهُ عَلَىٰ عِلۡمٖ وَخَتَمَ عَلَىٰ سَمۡعِهِۦ وَقَلۡبِهِۦ وَجَعَلَ عَلَىٰ بَصَرِهِۦ غِشَٰوَةٗ فَمَن يَهۡدِيهِ مِنۢ بَعۡدِ ٱللَّهِۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re, ti Allahu si si i lona pelu imo , ti O si fi edidi di igboro re ati okan re, ti O tun fi ebibo bo oju re! Ta ni o maa fi ona mo on leyin Allahu? Se e o nii lo iranti ni
Surah Al-Jathiya, Verse 23
وَقَالُواْ مَا هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا نَمُوتُ وَنَحۡيَا وَمَا يُهۡلِكُنَآ إِلَّا ٱلدَّهۡرُۚ وَمَا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَظُنُّونَ
Won wi pe: "Ko si isemi kan mo bi ko se isemi aye wa yii; a n ku, a si n semi. Ati pe ko si nnkan t’o n pa wa bi ko se igba." Won ko si ni imo kan nipa iyen; won ko se kini kan bi ko se pe won n ro erokero
Surah Al-Jathiya, Verse 24
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ مَّا كَانَ حُجَّتَهُمۡ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱئۡتُواْ بِـَٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awijare won ko je kini kan tayo ki won wi pe: "E mu awon baba wa wa ti e ba je olododo
Surah Al-Jathiya, Verse 25
قُلِ ٱللَّهُ يُحۡيِيكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يَجۡمَعُكُمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا رَيۡبَ فِيهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
So pe: "Allahu l’O n so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo
Surah Al-Jathiya, Verse 26
وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوۡمَئِذٖ يَخۡسَرُ ٱلۡمُبۡطِلُونَ
Ati pe ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. (Ranti) ojo ti Akoko naa maa sele; ojo yen ni awon t’o n tele iro yoo sofo
Surah Al-Jathiya, Verse 27
وَتَرَىٰ كُلَّ أُمَّةٖ جَاثِيَةٗۚ كُلُّ أُمَّةٖ تُدۡعَىٰٓ إِلَىٰ كِتَٰبِهَا ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
O si maa ri gbogbo ijo lori ikunle. Won yo si maa pe ijo kookan sibi iwe ise won. Ni oni ni A oo san yin ni esan ohun ti e n se nise
Surah Al-Jathiya, Verse 28
هَٰذَا كِتَٰبُنَا يَنطِقُ عَلَيۡكُم بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّا كُنَّا نَسۡتَنسِخُ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Eyi ni iwe akosile Wa, ti o n so ododo nipa yin. Dajudaju Awa n se akosile ohun ti e n se nise
Surah Al-Jathiya, Verse 29
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَيُدۡخِلُهُمۡ رَبُّهُمۡ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡمُبِينُ
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi won sinu ike Re. Iyen ni erenje ponnbele
Surah Al-Jathiya, Verse 30
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَفَلَمۡ تَكُنۡ ءَايَٰتِي تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ وَكُنتُمۡ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ
Ni ti awon t’o si sai gbagbo, (A oo bi won leere pe:) "Nje won ki i ke awon ayah Mi fun yin bi?" Sugbon e segberaga. E si je ijo elese
Surah Al-Jathiya, Verse 31
وَإِذَا قِيلَ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱلسَّاعَةُ لَا رَيۡبَ فِيهَا قُلۡتُم مَّا نَدۡرِي مَا ٱلسَّاعَةُ إِن نَّظُنُّ إِلَّا ظَنّٗا وَمَا نَحۡنُ بِمُسۡتَيۡقِنِينَ
Nigba ti won ba so pe: "Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe Akoko naa, ko si iyemeji ninu re." Eyin n wi pe: "Awa ko mo ohun ti Akoko naa je. Awa ko si ro o si kini kan bi ko se erokero; awa ko si ni amodaju (nipa re)
Surah Al-Jathiya, Verse 32
وَبَدَا لَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Awon aburu ohun ti won se nise si han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po
Surah Al-Jathiya, Verse 33
وَقِيلَ ٱلۡيَوۡمَ نَنسَىٰكُمۡ كَمَا نَسِيتُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَا وَمَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Won si maa so pe: "Ni oni, Awa yoo gbagbe yin (sinu Ina) gege bi eyin naa se gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Ina si ni ibugbe yin. Ati pe ko nii si awon oluranlowo fun yin
Surah Al-Jathiya, Verse 34
ذَٰلِكُم بِأَنَّكُمُ ٱتَّخَذۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗا وَغَرَّتۡكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ فَٱلۡيَوۡمَ لَا يُخۡرَجُونَ مِنۡهَا وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ
Bayen ni nitori pe, e so awon ayah Allahu di nnkan yeye. Ati pe isemi aye tan yin je. Nitori naa, ni oni won ko nii mu won jade kuro ninu Ina. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu
Surah Al-Jathiya, Verse 35
فَلِلَّهِ ٱلۡحَمۡدُ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَرَبِّ ٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Nitori naa, gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa gbogbo eda
Surah Al-Jathiya, Verse 36
وَلَهُ ٱلۡكِبۡرِيَآءُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
TiRe ni titobi ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon
Surah Al-Jathiya, Verse 37