Surah Al-Jathiya - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
حمٓ
Hā mīm
Surah Al-Jathiya, Verse 1
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Al-Jathiya, Verse 2
إِنَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àwọn àmì wà (nínú wọn) fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Al-Jathiya, Verse 3
وَفِي خَلۡقِكُمۡ وَمَا يَبُثُّ مِن دَآبَّةٍ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ
Àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá yín àti ohun tí Allāhu ń fọ́nká (sórí ilẹ̀) nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú
Surah Al-Jathiya, Verse 4
وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن رِّزۡقٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ ءَايَٰتٞ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
(Nínú) ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní arísìkí, tí Ó ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn t’ó ti kú àti ìyípadà atẹ́gùn, àwọn àmì tún wà (nínú wọn) fún ìjọ t’ó ní làákàyè
Surah Al-Jathiya, Verse 5
تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَ ٱللَّهِ وَءَايَٰتِهِۦ يُؤۡمِنُونَ
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu tí À ń ké (ní kéú) fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ wo lẹ́yìn (ọ̀rọ̀) Allāhu àti àwọn àmì Rẹ̀ ni wọn yóò tún gbàgbọ́
Surah Al-Jathiya, Verse 6
وَيۡلٞ لِّكُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٖ
Ègbé ni fún aládàápaarọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀
Surah Al-Jathiya, Verse 7
يَسۡمَعُ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ثُمَّ يُصِرُّ مُسۡتَكۡبِرٗا كَأَن لَّمۡ يَسۡمَعۡهَاۖ فَبَشِّرۡهُ بِعَذَابٍ أَلِيمٖ
t’ó ń gbọ́ àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń ké e fún un, lẹ́yìn náà, tí ó (tún) takú ní ti ìgbéraga bí ẹni pé kò gbọ́ ọ. Fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro
Surah Al-Jathiya, Verse 8
وَإِذَا عَلِمَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا شَيۡـًٔا ٱتَّخَذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Nígbà tí ó bá nímọ̀ nípa kiní kan nínú àwọn āyah Wa, ó máa mú un ní n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá ń bẹ fún
Surah Al-Jathiya, Verse 9
مِّن وَرَآئِهِمۡ جَهَنَّمُۖ وَلَا يُغۡنِي عَنۡهُم مَّا كَسَبُواْ شَيۡـٔٗا وَلَا مَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡلِيَآءَۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Iná Jahanamọ wà níwájú wọn. Ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n mú ní aláàbò lẹ́yìn Allāhu kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan níbi ìyà. Ìyà ńlá sì wà fún wọn
Surah Al-Jathiya, Verse 10
هَٰذَا هُدٗىۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَهُمۡ عَذَابٞ مِّن رِّجۡزٍ أَلِيمٌ
Èyí ni ìmọ̀nà. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn, ìyà ẹlẹ́gbin ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn
Surah Al-Jathiya, Verse 11
۞ٱللَّهُ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡبَحۡرَ لِتَجۡرِيَ ٱلۡفُلۡكُ فِيهِ بِأَمۡرِهِۦ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allāhu ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò fun yín nítorí kí àwọn ọkọ̀ ojú-omi lè rìn nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ tún lè wá nínú oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)
Surah Al-Jathiya, Verse 12
وَسَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مِّنۡهُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Ó tún rọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ pátápátá fun yín láti ọ̀dọ̀ ara Rẹ̀. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀
Surah Al-Jathiya, Verse 13
قُل لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَغۡفِرُواْ لِلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ أَيَّامَ ٱللَّهِ لِيَجۡزِيَ قَوۡمَۢا بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí wọ́n ṣàmójú kúrò fún àwọn tí kò retí àwọn ọjọ́ (tí) Allāhu (yóò ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo) nítorí kí Ó lè san ẹ̀san fún ìjọ kan nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Jathiya, Verse 14
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ
Ẹníkẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Al-Jathiya, Verse 15
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَفَضَّلۡنَٰهُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ
Dájúdájú A fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní Tírà àti ìdájọ́ ṣíṣe pẹ̀lú ipò Ànábì. A sì ṣe arísìkí fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. A sì ṣoore àjùlọ fún wọn lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn)
Surah Al-Jathiya, Verse 16
وَءَاتَيۡنَٰهُم بَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِۖ فَمَا ٱخۡتَلَفُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
A tún fún wọn ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú nípa ọ̀rọ̀ náà. Nítorí náà, wọn kò pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń yapa ẹnu sí
Surah Al-Jathiya, Verse 17
ثُمَّ جَعَلۡنَٰكَ عَلَىٰ شَرِيعَةٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ فَٱتَّبِعۡهَا وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ
Lẹ́yìn náà, A fi ọ́ sí ojú ọ̀nà kan nínú ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn ’Islām). Nítorí náà, tẹ̀lé e. Kí o sì má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tí kò nímọ̀
Surah Al-Jathiya, Verse 18
إِنَّهُمۡ لَن يُغۡنُواْ عَنكَ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۚ وَإِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۖ وَٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلۡمُتَّقِينَ
Dájúdájú wọn kò lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú àwọn alábòsí, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Allāhu sì ni Ọ̀rẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)
Surah Al-Jathiya, Verse 19
هَٰذَا بَصَـٰٓئِرُ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ
Èyí ni ìtọ́sọ́nà fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú
Surah Al-Jathiya, Verse 20
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ ٱجۡتَرَحُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن نَّجۡعَلَهُمۡ كَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ سَوَآءٗ مَّحۡيَاهُمۡ وَمَمَاتُهُمۡۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ
Tàbí àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé A máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí (A ti ṣe) àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí ìṣẹ́mí ayé wọn àti ikú wọn rí bákan náà? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú
Surah Al-Jathiya, Verse 21
وَخَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّ وَلِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo àti nítorí kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn
Surah Al-Jathiya, Verse 22
أَفَرَءَيۡتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَٰهَهُۥ هَوَىٰهُ وَأَضَلَّهُ ٱللَّهُ عَلَىٰ عِلۡمٖ وَخَتَمَ عَلَىٰ سَمۡعِهِۦ وَقَلۡبِهِۦ وَجَعَلَ عَلَىٰ بَصَرِهِۦ غِشَٰوَةٗ فَمَن يَهۡدِيهِ مِنۢ بَعۡدِ ٱللَّهِۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀, tí Allāhu sì ṣì í lọ́nà pẹ̀lú ìmọ̀ , tí Ó sì fi èdídí dí ìgbọ́rọ̀ rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀, tí Ó tún fi èbìbò bo ojú rẹ̀! Ta ni ó máa fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n lẹ́yìn Allāhu? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
Surah Al-Jathiya, Verse 23
وَقَالُواْ مَا هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا نَمُوتُ وَنَحۡيَا وَمَا يُهۡلِكُنَآ إِلَّا ٱلدَّهۡرُۚ وَمَا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَظُنُّونَ
Wọ́n wí pé: "Kò sí ìṣẹ̀mí kan mọ́ bí kò ṣe ìṣẹ̀mí ayé wa yìí; à ń kú, a sì ń ṣẹ̀mí. Àti pé kò sí n̄ǹkan t’ó ń pa wá bí kò ṣe ìgbà." Wọn kò sì ní ìmọ̀ kan nípa ìyẹn; wọn kò ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń ro èròkérò
Surah Al-Jathiya, Verse 24
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ مَّا كَانَ حُجَّتَهُمۡ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱئۡتُواْ بِـَٔابَآئِنَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwíjàre wọn kò jẹ́ kiní kan tayọ kí wọ́n wí pé: "Ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo
Surah Al-Jathiya, Verse 25
قُلِ ٱللَّهُ يُحۡيِيكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يَجۡمَعُكُمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا رَيۡبَ فِيهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Sọ pé: "Allāhu l’Ó ń sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀
Surah Al-Jathiya, Verse 26
وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوۡمَئِذٖ يَخۡسَرُ ٱلۡمُبۡطِلُونَ
Àti pé ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀; ọjọ́ yẹn ni àwọn t’ó ń tẹ̀lé irọ́ yóò ṣòfò
Surah Al-Jathiya, Verse 27
وَتَرَىٰ كُلَّ أُمَّةٖ جَاثِيَةٗۚ كُلُّ أُمَّةٖ تُدۡعَىٰٓ إِلَىٰ كِتَٰبِهَا ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
O sì máa rí gbogbo ìjọ lórí ìkúnlẹ̀. Wọn yó sì máa pe ìjọ kọ̀ọ̀kan síbi ìwé iṣẹ́ wọn. Ní òní ni A óò san yín ní ẹ̀san ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Jathiya, Verse 28
هَٰذَا كِتَٰبُنَا يَنطِقُ عَلَيۡكُم بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّا كُنَّا نَسۡتَنسِخُ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Èyí ni ìwé àkọ́sílẹ̀ Wa, tí ó ń sọ òdodo nípa yín. Dájúdájú Àwa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Jathiya, Verse 29
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَيُدۡخِلُهُمۡ رَبُّهُمۡ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡمُبِينُ
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé
Surah Al-Jathiya, Verse 30
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَفَلَمۡ تَكُنۡ ءَايَٰتِي تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ وَكُنتُمۡ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ
Ní ti àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, (A óò bi wọ́n léèrè pé:) "Ǹjẹ́ wọn kì í ké àwọn āyah Mi fun yín bí?" Ṣùgbọ́n ẹ ṣègbéraga. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀
Surah Al-Jathiya, Verse 31
وَإِذَا قِيلَ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱلسَّاعَةُ لَا رَيۡبَ فِيهَا قُلۡتُم مَّا نَدۡرِي مَا ٱلسَّاعَةُ إِن نَّظُنُّ إِلَّا ظَنّٗا وَمَا نَحۡنُ بِمُسۡتَيۡقِنِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: "Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé Àkókò náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀." Ẹ̀yin ń wí pé: "Àwa kò mọ ohun tí Àkókò náà jẹ́. Àwa kò sì rò ó sí kiní kan bí kò ṣe èròkérò; àwa kò sì ní àmọ̀dájú (nípa rẹ̀)
Surah Al-Jathiya, Verse 32
وَبَدَا لَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po
Surah Al-Jathiya, Verse 33
وَقِيلَ ٱلۡيَوۡمَ نَنسَىٰكُمۡ كَمَا نَسِيتُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَا وَمَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Wọ́n sì máa sọ pé: "Ní òní, Àwa yóò gbàgbé yín (sínú Iná) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Iná sì ni ibùgbé yín. Àti pé kò níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fun yín
Surah Al-Jathiya, Verse 34
ذَٰلِكُم بِأَنَّكُمُ ٱتَّخَذۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗا وَغَرَّتۡكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ فَٱلۡيَوۡمَ لَا يُخۡرَجُونَ مِنۡهَا وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ
Báyẹn ni nítorí pé, ẹ sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àti pé ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Nítorí náà, ní òní wọn kò níí mú wọn jáde kúrò nínú Iná. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu
Surah Al-Jathiya, Verse 35
فَلِلَّهِ ٱلۡحَمۡدُ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَرَبِّ ٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Nítorí náà, gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Surah Al-Jathiya, Verse 36
وَلَهُ ٱلۡكِبۡرِيَآءُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
TiRẹ̀ ni títóbi nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Al-Jathiya, Verse 37