Surah Al-Maeda Verse 106 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaيَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ شَهَٰدَةُ بَيۡنِكُمۡ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ حِينَ ٱلۡوَصِيَّةِ ٱثۡنَانِ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ أَوۡ ءَاخَرَانِ مِنۡ غَيۡرِكُمۡ إِنۡ أَنتُمۡ ضَرَبۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةُ ٱلۡمَوۡتِۚ تَحۡبِسُونَهُمَا مِنۢ بَعۡدِ ٱلصَّلَوٰةِ فَيُقۡسِمَانِ بِٱللَّهِ إِنِ ٱرۡتَبۡتُمۡ لَا نَشۡتَرِي بِهِۦ ثَمَنٗا وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰ وَلَا نَكۡتُمُ شَهَٰدَةَ ٱللَّهِ إِنَّآ إِذٗا لَّمِنَ ٱلۡأٓثِمِينَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín. Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) "A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀