Surah Al-Maeda Verse 110 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaإِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱذۡكُرۡ نِعۡمَتِي عَلَيۡكَ وَعَلَىٰ وَٰلِدَتِكَ إِذۡ أَيَّدتُّكَ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِ تُكَلِّمُ ٱلنَّاسَ فِي ٱلۡمَهۡدِ وَكَهۡلٗاۖ وَإِذۡ عَلَّمۡتُكَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَۖ وَإِذۡ تَخۡلُقُ مِنَ ٱلطِّينِ كَهَيۡـَٔةِ ٱلطَّيۡرِ بِإِذۡنِي فَتَنفُخُ فِيهَا فَتَكُونُ طَيۡرَۢا بِإِذۡنِيۖ وَتُبۡرِئُ ٱلۡأَكۡمَهَ وَٱلۡأَبۡرَصَ بِإِذۡنِيۖ وَإِذۡ تُخۡرِجُ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِيۖ وَإِذۡ كَفَفۡتُ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ عَنكَ إِذۡ جِئۡتَهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡهُمۡ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ
(Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, ranti idera Mi lori re ati lori iya re, nigba ti Mo fi emi Mimo (molaika Jibril) ran o lowo, ti o si n ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba ti o dagba. (Ranti) nigba ti Mo fun o ni imo Tira, ijinle oye, at-Taorah ati al-’Injil. (Ranti) nigba ti o n mo nnkan lati inu amo bi irisi eye, ti o n fe ategun sinu re, ti o n di eye pelu iyonda Mi. O n wo afoju ati adete san pelu iyonda. (Ranti) nigba ti o n mu awon oku jade (ni alaaye lati inu saree) pelu iyonda Mi. (Ranti) nigba ti Mo ko awon omo ’Isro’il lowo ro, nigba ti o mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon t’o sai gbagbo ninu won si wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”