Surah Al-Maeda Verse 17 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaلَّقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَۚ قُلۡ فَمَن يَمۡلِكُ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔا إِنۡ أَرَادَ أَن يُهۡلِكَ ٱلۡمَسِيحَ ٱبۡنَ مَرۡيَمَ وَأُمَّهُۥ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗاۗ وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta sì l’ó ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam, àti ìyá rẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan