Surah Al-Maeda Verse 18 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaوَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ وَٱلنَّصَٰرَىٰ نَحۡنُ أَبۡنَـٰٓؤُاْ ٱللَّهِ وَأَحِبَّـٰٓؤُهُۥۚ قُلۡ فَلِمَ يُعَذِّبُكُم بِذُنُوبِكُمۖ بَلۡ أَنتُم بَشَرٞ مِّمَّنۡ خَلَقَۚ يَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۚ وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Àwọn yẹhudi àti nasara wí pé: "Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀." Sọ pé: “Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?” Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá