Surah Al-Maeda Verse 41 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maeda۞يَـٰٓأَيُّهَا ٱلرَّسُولُ لَا يَحۡزُنكَ ٱلَّذِينَ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡكُفۡرِ مِنَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَلَمۡ تُؤۡمِن قُلُوبُهُمۡۛ وَمِنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْۛ سَمَّـٰعُونَ لِلۡكَذِبِ سَمَّـٰعُونَ لِقَوۡمٍ ءَاخَرِينَ لَمۡ يَأۡتُوكَۖ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ مِنۢ بَعۡدِ مَوَاضِعِهِۦۖ يَقُولُونَ إِنۡ أُوتِيتُمۡ هَٰذَا فَخُذُوهُ وَإِن لَّمۡ تُؤۡتَوۡهُ فَٱحۡذَرُواْۚ وَمَن يُرِدِ ٱللَّهُ فِتۡنَتَهُۥ فَلَن تَمۡلِكَ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُرِدِ ٱللَّهُ أَن يُطَهِّرَ قُلُوبَهُمۡۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Iwo Ojise, ma se je ki o ba o ninu je awon t’o n yara lo sinu aigbagbo ninu awon t’o fi enu ara won wi pe: “A gbagbo.” – ti okan won ko si gbagbo ni ododo - ati awon t’o di yehudi, ti won n teti si iro, ti won si n teti si oro fun awon eniyan miiran ti ko wa si odo re, ti won n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “Ti won ba fun yin ni eyi e gba a. Ti won ko ba si fun yin e sora.” Enikeni ti Allahu ba fe fooro re, o o ni ikapa kini kan lodo Allahu fun un. Awon wonyen ni awon ti Allahu ko fe fo okan won mo. Idojuti n be fun won ni aye. Iya nla si n be fun won ni orun