Surah Al-Maeda Verse 41 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maeda۞يَـٰٓأَيُّهَا ٱلرَّسُولُ لَا يَحۡزُنكَ ٱلَّذِينَ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡكُفۡرِ مِنَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَلَمۡ تُؤۡمِن قُلُوبُهُمۡۛ وَمِنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْۛ سَمَّـٰعُونَ لِلۡكَذِبِ سَمَّـٰعُونَ لِقَوۡمٍ ءَاخَرِينَ لَمۡ يَأۡتُوكَۖ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ مِنۢ بَعۡدِ مَوَاضِعِهِۦۖ يَقُولُونَ إِنۡ أُوتِيتُمۡ هَٰذَا فَخُذُوهُ وَإِن لَّمۡ تُؤۡتَوۡهُ فَٱحۡذَرُواْۚ وَمَن يُرِدِ ٱللَّهُ فِتۡنَتَهُۥ فَلَن تَمۡلِكَ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُرِدِ ٱللَّهُ أَن يُطَهِّرَ قُلُوبَهُمۡۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn t’ó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn t’ó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” – tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn t’ó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fun yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fun yín ẹ ṣọ́ra.” Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run