Surah Al-Maeda Verse 42 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaسَمَّـٰعُونَ لِلۡكَذِبِ أَكَّـٰلُونَ لِلسُّحۡتِۚ فَإِن جَآءُوكَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُمۡ أَوۡ أَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡۖ وَإِن تُعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ فَلَن يَضُرُّوكَ شَيۡـٔٗاۖ وَإِنۡ حَكَمۡتَ فَٱحۡكُم بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ
Wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé