Surah Al-Maeda Verse 44 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaإِنَّآ أَنزَلۡنَا ٱلتَّوۡرَىٰةَ فِيهَا هُدٗى وَنُورٞۚ يَحۡكُمُ بِهَا ٱلنَّبِيُّونَ ٱلَّذِينَ أَسۡلَمُواْ لِلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلرَّبَّـٰنِيُّونَ وَٱلۡأَحۡبَارُ بِمَا ٱسۡتُحۡفِظُواْ مِن كِتَٰبِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ عَلَيۡهِ شُهَدَآءَۚ فَلَا تَخۡشَوُاْ ٱلنَّاسَ وَٱخۡشَوۡنِ وَلَا تَشۡتَرُواْ بِـَٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗاۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Dájúdájú Àwa sọ Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn t’ó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A ní kí wọ́n ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́