Surah Al-Maeda Verse 45 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaوَكَتَبۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيهَآ أَنَّ ٱلنَّفۡسَ بِٱلنَّفۡسِ وَٱلۡعَيۡنَ بِٱلۡعَيۡنِ وَٱلۡأَنفَ بِٱلۡأَنفِ وَٱلۡأُذُنَ بِٱلۡأُذُنِ وَٱلسِّنَّ بِٱلسِّنِّ وَٱلۡجُرُوحَ قِصَاصٞۚ فَمَن تَصَدَّقَ بِهِۦ فَهُوَ كَفَّارَةٞ لَّهُۥۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
A sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí