Surah Al-Maeda Verse 89 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaلَا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا عَقَّدتُّمُ ٱلۡأَيۡمَٰنَۖ فَكَفَّـٰرَتُهُۥٓ إِطۡعَامُ عَشَرَةِ مَسَٰكِينَ مِنۡ أَوۡسَطِ مَا تُطۡعِمُونَ أَهۡلِيكُمۡ أَوۡ كِسۡوَتُهُمۡ أَوۡ تَحۡرِيرُ رَقَبَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖۚ ذَٰلِكَ كَفَّـٰرَةُ أَيۡمَٰنِكُمۡ إِذَا حَلَفۡتُمۡۚ وَٱحۡفَظُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹnikẹ́ni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́