Surah Al-Maeda Verse 89 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Maedaلَا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا عَقَّدتُّمُ ٱلۡأَيۡمَٰنَۖ فَكَفَّـٰرَتُهُۥٓ إِطۡعَامُ عَشَرَةِ مَسَٰكِينَ مِنۡ أَوۡسَطِ مَا تُطۡعِمُونَ أَهۡلِيكُمۡ أَوۡ كِسۡوَتُهُمۡ أَوۡ تَحۡرِيرُ رَقَبَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖۚ ذَٰلِكَ كَفَّـٰرَةُ أَيۡمَٰنِكُمۡ إِذَا حَلَفۡتُمۡۚ وَٱحۡفَظُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Allahu ko nii fi ibura ti o bo lenu yin bi yin, sugbon O maa fi awon ibura ti e finnufindo mu wa bi yin. Nitori naa, itanran re ni bibo talika mewaa pelu ounje ti o wa ni iwontun-wonsi ti e n fi bo ara ile yin, tabi ki e raso fun won, tabi ki e tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Enikeni ti ko ba ri (eyi se), o maa gba aawe ojo meta. Iyen ni itanran ibura yin nigba ti e ba bura. E so ibura yin. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le dupe