Surah Al-Anaam Verse 119 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَمَا لَكُمۡ أَلَّا تَأۡكُلُواْ مِمَّا ذُكِرَ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَقَدۡ فَصَّلَ لَكُم مَّا حَرَّمَ عَلَيۡكُمۡ إِلَّا مَا ٱضۡطُرِرۡتُمۡ إِلَيۡهِۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا لَّيُضِلُّونَ بِأَهۡوَآئِهِم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُعۡتَدِينَ
Kí ni ó máa kọ̀ fun yín láti jẹ nínú ohun tí wọ́n fi orúkọ Allāhu pa! Ó kúkú ti ṣàlàyé fun yín ohun tí Ó ṣe ní èèwọ̀ fun yín àyàfi èyí tí ìnira (ebi) bá tì yín débẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni wọ́n ń fi ìfẹ́-inú wọn pẹ̀lú àìnímọ̀ (wọn) ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà