Surah Al-Anaam Verse 70 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَذَرِ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ دِينَهُمۡ لَعِبٗا وَلَهۡوٗا وَغَرَّتۡهُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ وَذَكِّرۡ بِهِۦٓ أَن تُبۡسَلَ نَفۡسُۢ بِمَا كَسَبَتۡ لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ وَإِن تَعۡدِلۡ كُلَّ عَدۡلٖ لَّا يُؤۡخَذۡ مِنۡهَآۗ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أُبۡسِلُواْ بِمَا كَسَبُواْۖ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ
Pa àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́