Surah Al-Anaam Verse 70 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Anaamوَذَرِ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ دِينَهُمۡ لَعِبٗا وَلَهۡوٗا وَغَرَّتۡهُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ وَذَكِّرۡ بِهِۦٓ أَن تُبۡسَلَ نَفۡسُۢ بِمَا كَسَبَتۡ لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ وَإِن تَعۡدِلۡ كُلَّ عَدۡلٖ لَّا يُؤۡخَذۡ مِنۡهَآۗ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أُبۡسِلُواْ بِمَا كَسَبُواْۖ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ
Pa awon t’o so esin won di ere sise ati iranu ti. Isemi aye si tan won je. Fi (al-Ƙur’an) se isiti nitori ki won ma baa fa emi kale sinu iparun nipase ohun ti o se nise (aburu). Ko si si alaabo tabi olusipe kan fun un leyin Allahu. Ti o ba si fi gbogbo aaro serapada, A o nii gba a lowo re. Awon wonyen ni awon ti won fa kale fun iparun nipase ohun ti won se nise. Ohun mimu gbigbona ati iya eleta elero n be fun won nitori pe won maa n sai gbagbo