Surah Al-Araf Verse 143 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَلَمَّا جَآءَ مُوسَىٰ لِمِيقَٰتِنَا وَكَلَّمَهُۥ رَبُّهُۥ قَالَ رَبِّ أَرِنِيٓ أَنظُرۡ إِلَيۡكَۚ قَالَ لَن تَرَىٰنِي وَلَٰكِنِ ٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡجَبَلِ فَإِنِ ٱسۡتَقَرَّ مَكَانَهُۥ فَسَوۡفَ تَرَىٰنِيۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُۥ لِلۡجَبَلِ جَعَلَهُۥ دَكّٗا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقٗاۚ فَلَمَّآ أَفَاقَ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un, Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó tají, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi)