Surah Al-Araf Verse 143 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Arafوَلَمَّا جَآءَ مُوسَىٰ لِمِيقَٰتِنَا وَكَلَّمَهُۥ رَبُّهُۥ قَالَ رَبِّ أَرِنِيٓ أَنظُرۡ إِلَيۡكَۚ قَالَ لَن تَرَىٰنِي وَلَٰكِنِ ٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡجَبَلِ فَإِنِ ٱسۡتَقَرَّ مَكَانَهُۥ فَسَوۡفَ تَرَىٰنِيۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُۥ لِلۡجَبَلِ جَعَلَهُۥ دَكّٗا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقٗاۚ فَلَمَّآ أَفَاقَ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Nigba ti (Anabi) Musa de ni akoko ti A fun un, Oluwa re si ba a soro. (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, fi ara Re han mi, ki emi le ri O.” (Allahu) so pe: “Iwo ko le ri Mi. Sugbon wo apata (yii), ti o ba duro sinsin si aye re, laipe o maa ri Mi.” Nigba ti Oluwa re si (rora) fi ara Re han apata, O so o di petele. (Anabi) Musa si subu lule, o daku. Nigba ti o taji, o so pe: “Mimo ni fun O, emi ronu piwada si odo Re. Emi si ni akoko awon onigbagbo ododo (ni asiko temi)